Fuel Subsidy Removal: Wo ìdí tí ìjọba àpapọ̀ ṣe pẹ̀yìndà lórí ìrànwọ́ owó orí epo

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina
Minisita eto iṣuna, Zainab Ahmed ti sọ pe ijọba apapọ ti dawọ duro lori ipinnu rẹ lati yọ owo iranwọ ori epo bẹntiro.
Minsita naa lo fi ọrọ ọhun lede lẹyin ipade kan ti wọn ṣe niluu Abuja.
O ni awọn ti wọgile igbese awọn lati yọ owo iranwọ ori epo naa, awọn ko si tii le sọ igba ti awọn yoo yi ipinnu ọhun pada.
- Ìjọba Kano gbẹ́sẹ̀lé ìwé àṣẹ gbogbo ilé ẹ̀kọ́ aládàni lẹ́yìn ikú ọmọdébìnrin Hanifa Abubakar
- Ṣé ìdìtẹ̀ gbàjọba ló ń wáyé ní Burkina Faso àbí kí ló gbé ológun jáde?
- Ìwádìí rèé lórí fídíò tó ṣàfihàn bí agbébọn ṣe tú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sí ìhòhò
- Mo fẹ́ fojú rí Sunday Igboho ní àhámọ́ tó wà, kò sì ní bọ́ níbẹ̀ - Seriki Fulani
- Wo bí agbẹ̀bí alágbo ṣe tan ìyá ọlọ́mọ méjì pa l'Eko, tó gé ẹ̀yà ara rẹ̀
- Tunisia já ìrètí Super Eagles kulẹ̀, wo àwọn tí ọmọ Nàìjíría dá lẹ́bi
- Ọlọ́run lè yan ààrẹ Nàìjíríà nínú ìjọ Winners, ó lè jẹ́ obìnrin gan ni - Oyedepo
- Ṣé lóòtọ́ ni Mercy Aigbe ti sẹ ìgbéyàwó pẹ̀lú Adekaz, àbọ̀ ìwádìí wa rèé
Zainab ṣalaye pe Aarẹ Muhammadu Buhari pinnu lati máṣe yọ owo iranwọ ori epo naa lasiko yii niroti bi oju ọjọ ṣe ri Naijiria, paapaa ni ẹka eto iṣuna Naijiria.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ti wọn ba yọ owo iranwọ naa, iya yoo yoo jẹ ọpọ ọmọ Naijiria, eyii ko si kii ṣe ohun ti yoo dun mọ Aarẹ Buhari ninu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O fi kun pe awọn ti ṣeto fun owo iranwọ naa ninu eto iṣuna ọdun 2022 lati oṣu Kinni titi di oṣu Kẹfa.
Minisita ọhun sọ pe awọn yoo tẹsiwaju lati maa jiroro pẹlu gbogbo awọn ti ọrọ kan lọna ati ṣe atunṣe si awọn ileeṣe ijọba to n fọ epo ni Naijiria lọna ati mu adinku ba iye owo ti wọn n ta epo ni Naijiria.
O ni awọn yoo ni lati ṣe atunṣẹ si eto iṣuna ọdun yii ki awọn le ri aye fun afikun owo iranwọ naa bẹrẹ lati oṣu Keje lọ.
Lori ọrọ eto iṣuna ọdun yii, minisita fun ọrọ epo bẹntiro, Timipriye Sylva ni wọn gbọdo fi owo iranwọ ori epo naa kun eto iṣuna to ti wa nilẹ, ile igbimọ aṣofin si gbọdọ ri pe eyii ṣeeṣe.
Ohun to yẹ ki o mọ nipa owo iranwọ ori epo
Eredi ti ijọba ṣe n san owo naa ni lati mu adinku ba ipa ti iye owo epo yoo ni lara awọn araalu.
Lati nnkan bii ọdun 1970 ni ijọba Naijiria ti n san owo yii.
Laarin ọdu 2006 si 2018, ko din ni tiriliọnu mẹwaa naira ti ijọba aapọ san gẹgẹ bii owo iranwọ ori epo bẹntiro.














