Herbal Doctor: Iléẹṣẹ́ ọlọ́pàá Eko tú àṣírí agbẹ̀bí alágbo tó ṣekú pa obìnrin kan

Agbo ibilẹ

Oríṣun àwòrán, Alagbo

Iwadii ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fihan bi elewe ọmọ kan ṣe tan Mercy Henry jẹ, ti o si tun ṣekúpa a niluu Eko.

Mecry, iya ọlọmọ meji naa, ni a gbọ pe o lọ ba agbẹbi alagbo yii, Mayowa Timothy Bamidele fun iranwọ lori nkan ti o n ṣe e.

Lẹyin naa ni a gbọ pe Bamidele tan Mercy lọ sí ile rẹ nibi ti o ti kun un bi ẹran, ti o si sin in sẹyin ile rẹ to wa ni Ijegun.

Iwadii fihan pe oṣu kejila ọdun 2021 ni Mercy kan si Bamidele.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọjọ kerindinlogun oṣu Kejìlá ọdun 2021 ni Mercy kuro nile lọ sile Bamidele.

Awọn ẹbi rẹ figbe ta lẹyin ti wọn ko ri, ti ko si dari wale.

Àkọlé fídíò, Zazzu Portable: Èmi ni mo ni Zazzu Zeh, orúkọ mi ló wà níbẹ̀ àmọ́ wọ́n fẹ́ gbá mi

Bawo ni asiri isẹlẹ ipaniyan yii se tu?

Aburo Mercy to jẹ ọkunrin ni ẹbi bẹrẹ si ni wa Mercy lati ọjọ kẹtadinlogun oṣu kejila.

Ọrẹ Mercy to n gbe niluu Portharcourt, Ayo ni Mercy fẹ ya ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira lọwọ oun lọjọ kẹẹdogun oṣu kejila kan náà.

Ayo ni Mercy sọ fun oun pe ara oun ko ya ati pe oun fẹ fí ṣe itọju ara oun.

Ayọ sọ fun ẹbi Mercy pe ago meji ku iṣẹju kan ni oun fi owo naa ranṣẹ, ago meji kọja isẹju mẹta si ni nọmba Mercy ko lọ mọ lati igba naa.

Baba Mercy salaye aayan ti wọn se lati se awari Mercy:

Baba Mercy, Pa Henry Ekienabor ni ṣadeedee ni awọn ko kan ri Mercy mọ.

"Inu mi bajẹ gan an, iru eleyii ko ṣẹlẹ si mi ri.

O ti pe oṣu kan bayii ti a ko ri Mercy. A wa a kaakiri, a pe awọn ọrẹ rẹ, a si fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.

Awọn ọlọpaa n sọ fun wa pe iwadii si n lọ lọwọ. A tun lọ si ile adahunṣe, wọn sọ fun wa pe Mercy wa ninu ọfin nibi kan.

Ṣugbọn ko si ẹni to mọ ibi to wa," Baba Mercy ṣalaye.

Àkọlé fídíò, Wo ọmọ tó kọ̀ láti sin òkú ìyá rẹ̀ fún ọdún mẹ́wàá àti ìdí tó fi kọ̀ bẹ́ẹ̀

Ohun to mu ki iya alagbo jẹwọ fun ọlọpaa ree:

Iwadii fihan pe Bamidele lo gbẹbi fun Mercy nigba ti o bi ọkan lara awọn ọmọ rẹ.

Ayẹwo foonu Bamidele fihan pe oun ati Mercy sọrọ lọjọ kẹẹdogun oṣu kejila ni ago mẹsan an alẹ.

A gbọ pe Bamidele jẹwọ wí pe oun ni oun pa Mercy lẹyin ti ọkan lara awọn afurasi ti ileeṣẹ ọlọpaa mu jẹwọ pe awọn lo pa Mercy.

Afurasi naa pada mu awọn ọlọpaa lọ sẹyin ile rẹ nibi to sin Mercy si lẹyin to kọkọ ge ara rẹ wẹlẹ wẹlẹ sinu apo ki o to o sin in.

Awọn wo ni a n pe ni elewe ọmọ tabi alagbo nilẹ Yoruba?

Awọn eeyan ti Yoruba n pe ni alagbo ni awọn eeyan to maa n ta eroja ibilẹ ti wọn fi n se egboogi tabi oogun ibilẹ fun iwosan oniruuru aidape ara.

Awọn alagbo naa, ti ọpọ wọn maa n jẹ obinrin ni kii saba kawe tabi lọ sile ẹkọ fun ẹkọ iwe igbalode.

Awọn alagbo yii lo maa n lo ewe ati egbo fun iwosan, ti wọn si maa n gbẹbi ọmọ tuntun nigba miran nilana ti ibilẹ.