Afcon 2021: Ṣé lóòótọ́ ní ọ̀rọ̀ tàwọn èèyàn n sọ pé ẹmí òkùnkùn ààrẹ Buhari ló kó bá Super Eagles?

Aworan aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presdiency

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ ololufẹ ere bọọlu ọmọ Naijiria ni yoo ji lowurọ ọjọ Aje pẹlu ibanujẹ ọkan nitori ijakulẹ Super Egales ninu idije Afcon to n lọ lọwọ.

Lalẹ ọjọ Aiku ni wọn fidi rẹmi lọwọ akẹgbẹ wọn lati Tunisia ninu abala komẹsẹoyọ.

Goolu kan sodo lawọn Carthage Eagles lati Tunisia fi fagba han Super Eagles.

Ọrọ yii fọwọ kan ọpọ ọmọ Naijiria lẹmi paapa nitori iru ireti ati agbẹkẹle ti wọn ni ninu ikọ Super Eagles.

Itara yii foju han ninu ariwiisi awọn eeyan paapa loju opo Twitter nibi ti wọn ti nda awọn eeyan kan lẹbi ijakulẹ Super Eagles.

Nigeria ati Tunisia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bawọn kan ṣe n da ẹbi ru aṣọle Super Eagles Maduka Okoye, ti ko le da bọọlu to wọ awọn Eagles durọ, bẹẹ lawọn mii n sọ pe adari ere naa lẹbi tiẹ naa.

Eleyi to wa jẹ babanbari ninu ẹni tawọn eeyan da lẹbi ni aarẹ Buhari.

Ṣé ẹmi buruku Buhari lo mu ki awọn Super Eagles fidirẹmi?

Loju opo Twitter awọn eeyan n sọ pe ipe ti aarẹ Buhari pe Super Eagles lo ko ba wọn.

Ṣaaju ki ikọ naa to koju Tunisia, ni aarẹ Buhari pe awọn agbabọọlu naa, to si sọ ọrọ iwuri gẹgẹ bi baba orileede si wọn.

Amọ ọrọ yii ti wa fẹ di ohun tawọn kan n sọ pe aarẹ lo ko ba Super Eagles.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Ninu wọn la ti ri gbajugbaja alatako aarẹ nni, Reno Omokri.

Loju opo rẹ ni Twiter Omokri ti gbe fidio kan sita nibi to ti sọ pe aarẹ lo jẹ ki awọn Super Eagles pade ijakulẹ yii.

Gẹgẹ bo ti ṣe wi, o ni ko yẹ ki awọn ajọ ere bọọlu NFF gba ki aarẹ pe Super Eagles.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

''Ki lo n ṣe awọn NFF yii gaan? Ṣe wọn ti gbagbe ohun to ṣẹlẹ lẹyin ti aarẹ pe Anthony Joshua ni?Tabi awọn ikọ Super Eagles ninu idije Afcon to kọja?''

O tẹ siwaju pe lati igba ti ikọ yii ti bẹrẹ idije Afcon, wọn ko gba kaadi kankan bi kii ṣe igba ti aarẹ wa pe wọn ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ wọn.

''Iwobi gba kaadi pupa, wọn fun Iheanacho naa ni Yello. Lati igba ti wọn ti n gba bọọlu ninu idije yii, eleyi ko ṣẹlẹ ri. Ki lo wa de to ṣe pe ọjọ ti aarẹ Buhari pe wọn ni ajalu wọnyi n ṣẹlẹ?''

Ki lawọn eeyan sọ lori fidio Omokri yi?

Iriwisi ọtọọtọ lo ti n ba ọrọ ti Omokri sọ wa.

Awọn miran ati ohun ti wọn sọ nipa ipe aarẹ Buhari si Super Eagles ree:

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3

Yatọ si Super Eagles ti Omokri sọ pe ẹmi okunkun aarẹ lo ko ba a, o tun sọ pe aarẹ lo ko ba Anthony Joshua to fi fidi rẹmi ninu ija rẹ pẹlu Oleksandr Usyk.

Aworan aarẹ Buhari ati Anthony Joshua

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina

Oṣu Kini ọdun 2020 ni aarẹ ati Anthony Joshua pade lasiko ipade okoowo laarin Afrika ati ilẹ Gẹẹsi ni London.

Bawọn kan ṣe n fi awada sọ pe lootọ lọrọ to wi lawọn miran n sọ pe ko tọ bo ṣe da ẹbi yi ru aarẹ ati pe ko si ootọ ninu ọrọ rẹ.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Wale Gates fesi pada fun Omokri pe Anthony Joshua ko fidirẹmi ninu ija rẹ lẹyin to pade aarẹ ni oṣu kini ọdun 2020.

O ni a le fi ọrọ aarẹ se awada ṣugbọn iwa aigbọn ni ki eeyan wa ṣe fidio lori rẹ.

Ero rẹ ati awọn miran naa si papọ.

Arakunrin @Toyosky4real loju opo Twitter ni iru orire ati mi daada aarẹ lo y ki awọn eeyan maa tọrọ.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Bakan naa lọrọ ri lọdọ @whelegbo to ni awọn adari ikọ naa lẹbi ti wọn ninu ọrọ to wa nilẹ yi

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6