AFCON 2021: Asamoah Gyan ní Super Eagles Nàìjíríà ló dáńtọ́ láti gba ife ẹ̀yẹ AFCON 2021 ní Cameroon

Samuel Chukwueze ati Kelechi Iheanacho

Oríṣun àwòrán, Twitter/Super Eagles

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ẹlẹsẹ ayo ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Ghana tẹlẹ ri, Asamoah Gyan ti sọ pe ikọ Super Eagles Naijiria lo dantọ julọ lati gba ife ẹyẹ idije AFCON to n lọ lọwọ ni Cameroon.

Gyan fọrọ yii lede lori ẹrọ amohunmaworan Supersports nigba to jẹ ọna lara awọn alejo lori eto.

Ẹlẹsẹ ayo orilẹede Ghana tẹlẹ ni awọn agbabọọlu Naijiria fi ara wọn han nigba ti wọn gbo ewuro soju Egypt pẹlu ami ayo kan sodo pe awọn lawọn to lati gbade idije AFCON ni Cameroon.

''Lai ṣe ani ani, ikọ agbabọọlu Naijiria lo gbounjẹ fẹgbẹ to si gbawo bọ ninu gbogbo ẹgbẹ agbabọọlu to n kopa ninu idije AFCON lọwọ yii.

Ko si ikọ agbabọọlu ti Super Eagles ko le ṣẹgun pẹlu ohun ti wọn gba ninu ifẹṣẹwọnsẹ wọn pẹlu Egypt.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Gbogbo awọn ikọ agbabọọlu mii to tun le gba ife ẹyẹ AFCON ko fi tara tara si idije to n lọ lọwọ.

Amọ ti a ba wo ikọ Super Eagle Naijiria, wọn n gba bọọlu bi ikọ to le bori gba ife ẹyẹ naa.

O yẹ ki Naijiria gba ju goolu kan lọ sawọn Egypt ṣugbọn nkan naa n ṣe taṣe taṣe mọ wọn lọwọ ni.

Ti ikọ Super Eagles ba le tẹsiwaju lati maa gbabọọlu bi wọn ṣe n gba a lọwọ yii, awọn ni yoo gba ife ẹyẹ AFCON to n lọwọ yii,'' Gyan lo sọ bẹẹ.

Lọjọ Abamẹta ni Naijiria tun jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ keji ti wọn gba pẹlu Sudan.

Ami ayo mẹta si ẹyọkan ni wọn jawe olubori eleyii to mu wọn pegede fun ipele ẹlẹni mẹrindinlogun ninu idije AFCON to n lọ lọwọ.