Billionaire kidnapper Evans: Ilé ẹjọ́ ju Evans ajínigbé sẹ́wọ̀n gbére

Evans

Oríṣun àwòrán, Punch

Àkọlé àwòrán, Evans

Bí irọ́ bá lọ fún ogún ọdún, ọjọ́ kan ṣoṣo báyìí ni òtítọ́ yóò àti pé àṣegbé kan kò sí láyé àṣepamọ́ ló wà.

Ilé ẹjọ́ gíga ìlú Ikeja, ìpínlẹ̀ Eko ti sọ ògbóǹtarìgì ajínigbé olówó tabua, Chukwudimeme Onwuamadike tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Evans sí ẹ̀wọ̀n gbére.

Ilé ẹjọ́ ní Evans jẹ̀bi ẹ̀sùn jíjí Donatius Dunu tó jẹ́ ẹni tó ni iléeṣẹ́ ìpoògùn Maydon Pharmaceuticals Limited gbé lọ́dún 2017.

Yàtọ̀ sí Evans, ilé ẹjọ́ tún sọ àwọn méjì mìíràn tó jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Evans, Uche Amadi àti Okwuchukwu Nwachukwu sí ẹ̀wọ̀n gbére bákan náà.

Nínú ìdájọ́ tó gbá wákàtí mẹ́ta, Onídajọ́ Hakeem Oshodi ní àwọn afẹ̀sùnkàn mẹ́tẹ́ẹ̀ta jẹ̀bi ìjínigbé àti lílẹ̀dí àpòpọ̀ láti hu ìwà láabi.

Bákan náà ni Adájọ́ dá Ogechi Uchechukwu, Chilaka Ifeanyi àti Victor Aduba sílẹ̀ láti máa lọ ilé wọn láyọ̀ àti àláfíà wí pé kò sí ẹ̀rí tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ìjínigbé náà.

Chilaka Ifeanyi àti Victor Aduba ní wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ àjọ ọmọ ogun tẹ́lẹ̀.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ní ọdún 2017 ní àwọn ọlọ́pàá yabo ilé ìgbé Chukwudimeme Onwuamadike láti nawọ́ gan fún ẹ̀sùn ìjínigbé.

Onírúurú ẹ̀sùn ni wọ́n fi kan Evans tó fi mọ́ ìjínigbé àti olè jíjà.

Ìwádìí fi hàn pé Oyo, Eko, Port Harcourt, Onitsha àti Aba ní ọwọ́jà olè jíjà àti ìjínigbé rẹ̀ dé.