Wife kills husband with hot water: Bí ọwọ́ ṣe tẹ ìyàwó tó pa ọkọ ní Ogun rẹ̀ nìyí

Oríṣun àwòrán, Ogun Police
Iyawo ile kan ni Ìpínlẹ̀ Ogun, Arabinrin Ramota lọwọ ikọ Ọlọpaa ti tẹ lori ẹ̀sùn pe o pa ọkọ rẹ, Ọgbẹni Bello Saliu.
Ohun taa gbọ́ ni wipe omi gbigbona ni afurasi ohun da lu ọkọ rẹ lara.
Ninu atejade ti agbenuso Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi fọwọ́ si, alaye tí ẹni to jẹ aburo oloogbe wa ṣe ni agọ wọn tó wà ní agbègbè Lafenwa, Abeokuta ni pé iṣẹlẹ náà sẹlẹ ni ọjọ Kejila Oṣù Kejì ọdun 2022 nígbà tí afurasi naa ni aawọ ranpẹ pẹlu ọkọ rẹ .
Ó ṣàlàyé pe Arabinrin Ramota se omi gbigbona lori ina to si da a le ọkọ rẹ to n sun lọwọ lasiko naa lára èyí to fa ọpọlọpọ ipalara sii lara.
Wọn sare gbe Ọgbẹni Saliu digba-digba lọ ilé ìwòsàn fún itọju sugbọn ìròyìn ni ọjọ kejì lo dagbere faye lásìkò to n gba itoju lọwọ.
Nigba ti afurasi náà woye bí nkan tó ṣeé ṣe to ti fi ẹsẹ fẹ́ ẹ.
Ko sẹni to fi ẹjọ́ ohun to sẹlẹ yìí sun lagọ olopaa láti ọjọ naa títí di ọjọ́ Kọkànlá lógún oṣù Kejì nigba ti wọn ri afurasi naa nibi to sa pamọ si.
Kete ti iroyin naa tẹ àwọn Ọlọpaa létí ni wọn ṣe iṣẹ́ wọn bi isẹ ti wọn si fi panpẹ òfin mú Ramota.
Láti ọjọ naa ni wọn ti dárí ẹjọ́ rẹ sì ẹ̀ka to n rí si ipaniyan laarin awọn otelemuye.















