Sex Toy: Obìnrin ológun kan lo ohun ìṣeré ìbálòpọ̀, ó dákú rangbọndan

Asamọ kan lo ni erekere a mọ ko ba ni, ohun ti eeyan ba si mọọ jẹ, le seku pa a.
Diẹ lo ku ki obinrin ologun kan jade laye lasiko ti ohun isere ibalopọ, ta mọ si Sex Toy ha si oju ara rẹ.
Obinrin naa to ni isẹ ti gbe oun kuro nile lati ọdun kan sẹyin salaye pe oun fẹ dọgbọn si nipa nini adun ibalopọ.
- Genevieve ṣàlàyé ànfààní tó wà nínú ìbásùn òwúrọ̀ kùtù fáwọn lọ́kọ láya
- Ṣé irúfẹ́ oúnjẹ tí ò ń jẹ́ lè jẹ́ kí o gbádùn ìbálòpọ̀ rẹ síi?
- Wo ohun mẹ́rin tó lè mú ikú wá lásìkò ìbálòpọ̀
- Wo àwọn ohun mẹ́jọ́ tí àwọn olólùfẹ́ gbọ̀dọ̀ ṣe lẹ́yìn ìbálòpọ̀
- Arákùnrin òníbálòpọ̀ akọsákọ yarí mọ́ ìjọba lọ́wọ́ lórí àwọn Ìbejì rẹ̀ tí wọ́n bẹ́gi dínà ìrìnàjò wọn
- Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ìbálọ̀pọ̀ pẹ̀lú aya tàbí ọkọ rẹ lè jẹ́ kí o dàbí ọmọdé?
- Kí làwọn nǹkan tó lè rán ọkùnrin sí ọ̀run alákeji lásìkò ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin?
- Ẹ̀mi arákùnrin yìí kò gbé e, ó bá aláṣẹ́wò lò dórí ìgbà ìkéje ló bá ré sálákeji
- Bó o bá ń gba ẹnu ní ìbálòpọ̀, wo àìsàn tó o lè kó lójú ara rẹ
Amọ ere lo fẹ se, ni ọrọ ba yiwọ mọ lọwọ, ti adunmadẹẹkẹ si fẹ gba ẹmi rẹ.
Bawo ni ohun isere ibalopọ se fẹ sokunfa iku ojiji:
Obinrin ologun naa, to ya aworan ara rẹ lasiko to wa lori ibusun nile iwosan, lo salaye ohun to sọ dero ile iwosan naa.
Alaisan naa, ninu fidio kan to se, to gbe sori ayelujara ni ohun isere ibalopọ ti oun fi n ba oju ara oun sere, lo yiwọ.
" O to ọna mẹwa ti maa fi seto lilo ohun isere ibalopọ naa, mo si maa n lo lọpọ igba.
Amọ ni ọjọ kan, mo pinnu pe ki n sare lo lọna ti yoo fi sare ju bo se yẹ lọ, lati ba oju ara mi sere.
Ko yẹ ki n se bẹẹ nitori ipele kini, ikeji ni yoofun mi ni igbadun, gbe mi de 'ọrun' nigba kuugba ti mo ba n lo wọn.
Amọ lọna ati jẹ igbadun ara ọtọ pẹlu ohun isere ibalopọ naa, mo ba gbe kuro ni ipele kinni ati ikeji, mo si gbe lọ si ipele kẹfa.
Bo se n gbọn ni oju ara mi yatọ pupọ, to si ni ohun eelo kan to fi n fa mi."
Mo daku nigba ti ohun isere ibalopọ kọ, ti ko jade loju ara mi:
Obinrin naa salaye pe ohun isere ibalopọ naa sare kiakia fun oun ni adun ibalopọ, to si gbe oun de 'ọrun', gbe oun pada laarin aabọ isẹju.
Amọ ko pẹ ni wahala de, to si nira fun oun lati fa ohun ibalopọ naa yọ ni oju ara oun, lẹyin to ti fun oun ni adun ibalopọ tan.
"Mo tiraka lati fa a jade, amọ o kọ, ko jade, ti ohun to n fa oju ara mi ko si sisẹ bo se yẹ.
Bakan naa ni n ko le dide, nitori o ti rẹ mi, ti mo si wa ni ilẹ lẹ lasan, nigba to ya ni mo daku rangbọndan."
Lẹyin naa lo ni wọn gbe oun lọ sile iwosan nibi ti wọn ti ba fa ohun isere ibalopọ naa yọ.
Bo si se de ile pada, lo yara sọ ohun isere ibalopọ naa nu.



















