Bamise Ayanwole missing lady in Lagos BRT: Awakọ̀ BRT jẹ́wọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ tí Bamise fi di òkú lẹ́yìn tó wọ ọkọ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Awakọ to wa ọkọ bọọsi BRT ti arabinrin ẹni ọdun 22, Bamise Ayanwole to dawati wọ ti wi tẹnu rẹ lasiko ti awọn ọlọpaa fi panpẹ ofin ti wọn si fi oju rẹ han fun awọn oniroyin.
O ṣalaye pe oun o tilẹ le ṣalaye bi nkan ṣi ri lara oun lasiko ti gbogbo iṣẹ aburu naa n ṣẹlẹ.
"Mi o ni nkankan ṣe pẹlu awọn to fa ibọn yọ lẹgbẹ mi rara, Chevron ni mo ti gbe arabinrin naa mo si gbe awọn ọkunrin ọhun ni ibudokọ mii".
Awakọ naa ṣalaye pe nigba ti awọn yẹn fa ibọn yọ ti wn fi han oun, oun ko jẹ ara oun mọ. "Ibẹru ti bo mi jinijini, torinaa, gbogbo nkan ti ẹni to gbe ibọn lọwọ ba sọ fun mi ni mo kan n tẹle".
Nice Andrew Omininikoron ṣalaye bi wọn ṣe ni kida ọkọ duro nigba ti awọn de ori afara Carter ti wọn si n wọ ọmọbinrin naa bọlẹ, "nigba ti mo ri i to n sunkun, ko sohun ti mo le ṣe".
O ni idi ti oun fi sa lọ ni pe nigba ti iṣẹlẹ naa ṣlẹ ẹru ba oun.

Oríṣun àwòrán, others
Ileese ọlọ́páà ipinlẹ̀ Eko ti mu afurasi awakọ to wa ọkọ̀ BRT ti Bamise ti dawati.
Ikọ̀ ọlọ̀pàá ti Kọmisonna Abiodun Alabi saaju fun lo mu okunrin naa.
Okọ̀ BRT yii lo gbe arabinrin Ayanwole Oluwabamise to je eni odun mejilelogun to n sise aranso to dawati.
Bayii wọ́n ti ri oku Bamise leyin to di oku.
Awako yii lo ti sa lọ lati igba ti wọ́n ti n wa ọ̀dọ̀mọbinrin naa ni eyi ti o dẹ́ ti di afurasi bayii.
Wọ́n ni pe nibi ipamọ́ rẹ̀ ni ọwọ́ ti tẹ̀ẹ́ ni agbegbe Odogbolu nipinle Ogun bayii.
Tani afurasi awakọ naa?
Orukọ rẹ̀ ni Nice Andrew Ominikoron.
Won si ti n fọ̀rọ̀ waa lẹ́nu wo bayii ni agọ́ ọlọ́paa.
Omininikoron ni won ti furasi bayii ti wọ́n si ti fi si gbaga olopaa.
- Bí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ṣe ń wáyé lọ́wọ́ ní Abuja, Femi Falana ń bèèrè pé kí ọ̀gá ọlọ́pàá dá ẹjọ́ padà sí Osun
- Àwọn ẹbí Rahmon Adedoyin àti Timothy Adegoke ju òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn nílé ẹjọ́
- Odindi ọdún mẹ́ta ni ọkọ mi ti ń fipá bá ìbátan mi ọmọ òrukàn ọdún mọ́kànlá lò pọ̀
- Wọ́n ti rí òkú obìnrin ẹni ọdún 22 tó dàwátì nínú ọkọ̀ BRT l'Eko
- Ọkọ̀ tó rìn gba "one way" gbá ọmọ ìyá mẹ́rin lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo l'Eko, ọ̀kan kú
- Odindi ọdún mẹ́ta ni ọkọ mi ti ń fipá bá ìbátan mi ọmọ òrukàn ọdún mọ́kànlá lò pọ̀

Oríṣun àwòrán, BRT
Wọ́n ti rí òkú obìnrin ẹni ọdún 22 tó dàwátì nínú ọkọ̀ BRT l'Eko
Iroyin to n jade ni yajoyajo bayii n fidi rẹ mulẹ pe omidan Oluwabamise Ayanwọle ti okiki kan pe o sọnu lẹyin to wọ ọkọ bọọsi BRT l'Eko ti di riri.
Amọṣa oku rẹ ni wọn ri lagbegbe Lagos Island.
Arakunrin kan ti wọn ni o ri oku omidan naa lo pe awọn ọlọpaa ni Ebute Ero nibi ti wọn ti gbe oku rẹ l si ile igbokupamọ si Mainland Hospital.
Ohun ti a n gbọ ni pe awọn mọlẹbi rẹ ṣalaye fawọn akọroyin kan pe wọn fẹ ṣe ayẹwo oku rẹ lati mọ boya wọn ge ẹya ara rẹ kankan lọ.
Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe bẹrẹ?
Ohun ti a gbọ ni pe agbegbe Chevron Estate ni Ajah ni oloogbe naa ti n ṣiṣẹ gẹgẹbi aranṣọ, ti o si maa n lọ si Ọta nipinlẹ Ogun lọdọ ẹgbọn rẹ obinrin lati lọ ṣe isinmi opin ọsẹ lọsọọsẹ.
Omidan Ayanwọle n lọ si Ọta lọjọ Satide lẹyin to pari iṣẹ tan ni Ajah lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu keji lo fi gun bọọsi BRT naa ti nọmba rẹ jẹ 240257.
Osodi ni bọọsi BRT naa n lọ ṣugbọn omidan naa ko de osodi, oku rẹ ni wọn ri bayii.
#JusticeforBamise
Ariwo #JusticeforBamisaye lawọn eeyan ti n pa lori ayelujara latigba ti iroyin pe o dawati ninu ọkọ BRT ti jade.
Ki ni ọlọpaa n ṣe?
Ileeṣẹ ọlọpaa ti kọkọ fi atẹjade kan sita tẹlẹ pe iwadii ti bẹrẹ.
Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ EkoAbiọdun Alabi ti paṣẹ kawọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti o bẹrẹ iwadii lori rẹ.
O ni lọwọ yii, ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ awọn afurasi meji lori iṣẹlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ayé lee! Báwo ni obìnrin ẹni ọdún 22 yìí ṣe dédé dàwátì nínú ọkọ̀ BRT l'Eko?
Titi di asiko yii, ibi ti odidi adelebọ ẹni ọdun mejilelogun arabbinrin kan, Oluwabamise Ayanwola wa ko han si ẹnikẹni bayii lẹyin to di awati ni agbegbe ibudokọ Chevron ninu ọkọ akero BRT to n wọ lọ si Oshodi ni nkan bii ago meje alẹ.
Gẹgẹ bi ohun ti awọn iwe iroyin kan kọ jade, Bamise ni abigbẹyin idile rẹ to si n ṣiṣẹ aranṣọ ni agbegbe Chevron Estate ni Ajah, Eko.
Ninu ọrọ ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko fi sita, wọn ni "a ti kan lu agbami iṣẹ, a o si ni kaarẹ iṣẹ takuntakun lati ṣawari arabinrin naa atawọn to ji i gbe".
Ninu atẹjade wọn ọhun eyi ti agẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Eko, CPS Adekunle Ajisebutu fọwọ si, wọn ni awọn n fi to gbogbo araalu leti pe Omidan Ayanwole Oluwabamise ko tii di riri di akoko ti wọn fi atẹjade wọn sita ni ọjọ Aiku ọsẹ yii.
- Wo ohun táwọn èèyàn ń sọ sí Mercy Aigbe torí àṣírí tí ìyàwó àkọ́fẹ́ Adekaz tú síta
- Ìdí rèé tí a fi kéde lílo Hijab àti àwọn ìmúra míràn fún ọlọ́pàá obìnrin Nàìjíríà- Ilééeé ọlọ́pàá
- Sé lóòtọ́ ní ẹni ọdún 14 yìí fi májèlé sí oúnjẹ mọ̀lẹ́bí tó ń bá gbé ní Obada Oko? ohun tí a mọ̀ rèé..
- Obìnrin tó wà nídí ayẹyẹ 'ówàńbẹ̀' táwọn kan ti pín bẹntiró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn àmúrelé l'Eko ti yọjú síta
- Bí àwọn ọmọ Nàìjíríà tó fẹ́ lọ ran Ukraine lọ́wọ́ lójú ogun ṣe tàdí mẹ́yìn rèé nígbá tí wọ́n gbọ́ "wàa san $1,000"
- Ó yá, àsìkò tó kí o tan iná wádìí gbogbo owó tí wọ́n ti ná lórí ibùdó ìfọpo ní Nàìjíríà - SERAP kọ̀wé sí Buhari
Wọn ni kete ti iroyin naa de eti igbọ ọlọpaa ni ifimufinlẹ ti bẹrẹ nipa iṣẹlẹ to yi ipoora rẹ ka ti bẹrẹ ni kiakia.
Ọlọpaa ni ninu iwadii ti awọn ti bẹrẹ yii, ọwọ awọn ti sare tẹ afurasi meji kan ti wọn si ti n ran iwadi awọn lọwọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa wa n rọ awọn araalu ati ẹnikẹni to ba ni iroyin kankan to lu mọ iṣẹlẹ yii lati fun awọn ni awọn iroyin naa ti yoo ran iṣẹ awọn lọwọ.
A gbọ pe ijọba ibilẹ Moba ni ipinlẹ Ekiti ni arabinrin naa ti wa, o dudu o si lee sọ ede Yoruba ati Gẹẹsi daadaa.

















