Fuel scarcity: SERAP kọ̀wé sí Buhari pé kó tan iná wádìí gbogbo owó tí wọ́n ti ná lórí ibùdó ìfọpo ní Nàìjíríà

Awọn eeyan n to nileepo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọ n jagun ni ki wọn to ri epo ra.

Ajọ ajafẹtọ kan lorilẹede Naijiria, SERAP ti kọwe si aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari pe ko pa a laṣẹ fun agbẹjọro agba ni Naijiria, to tun jẹ minisita feto idajọ, Abubakar Malami SAN atawọn ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria lati tan ina wadi gbogbo owo ti wọn ti naa lori awọn ibudo ifọpo mẹrẹẹrin to wa lorilẹede Naijiria.

SERAP ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aiku pe bi aarẹ ba kuna lati gbe igbesẹ yii, oun yoo fa a lọ siwaju ile ẹjọ ni.

Ajọ naa ni yoo dara ki aarẹ Buhari wadi bi wọn ti ṣe na owo si lori awọn ibudo ifọpo naa lati ọdun 1999 lọna ati lee fi oju awọn oniwa kotọ lẹka naa han ki wọn si ṣe eto gba ma binu fun awọn to ti fara kaaṣa iwa ijẹkujẹ to waye nibẹ.

Ọwọngogo epo ni Naijiria, iṣoro atigbadegba

Lati bii ọsẹ diẹ sẹyin bayii lawọn ọmọ Naijiria ti n foju wina wahala ọwọngogo epo bẹntiro.

Ọpọlọpọ lo si n lo aimọye wakati lori ila nileepo ki wọn to ri epo bẹntiro ra.

Awọn eeyan n to nileepo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọlọpọ lo si n lo aimọye wakati lori ila nileepo ki wọn to ri epo bẹntiro ra.

Pupọ awọn to ba si jagun ri ra naa n kọminu pe owo gegele lawọn ontaja epo n taa ni owo to pọ ju iye ti ijọba n taa lọ.

Titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ijọba ko tii lee sọ fun araalu igba tabi asiko ti ipenija yii yoo dẹkun tabi ọna abayọ ti wọn n ṣe sii.

Ki lo wa ninu lẹta ti SERAP kọ si Aarẹ Buhari?

Ninu lẹta ti ajọ ajafẹtọ naa kọ si Aarẹ Buhari, o ni ko yẹ ki ijọba o fi ewe rabata bo imi iwa ibajẹ kiko ayederu epo wọ Naijiria, ọwọngogo epo bẹntiro, bi ko ṣe ko fa a tu ti gbongbon ti gbongbo.

"Kiko ayederu epo wọ ilu, ati ọwọngogo epo to n waye kaakiri orilẹede yii fihan bi o ṣe ṣe pataki fun eto lati ṣi oju awọn oniṣẹ ibi fayeri, fa wọn tu ki a si fi iya to tọ jẹ awọn to n jẹ ijẹkujẹ lẹka epo rọbi, ati lati fun awọn eeyan to fara kaaṣa idibajẹ wọn ni idajọ ododo."