Driver hits four siblings in Lagos: Ọkọ̀ tó rìn gba "one way" gbá ọmọ ìyá mẹ́rin lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo l'Eko

Oríṣun àwòrán, Lagos Police
Ọkọ kan to n gba 'one way' ti gba ọmọ iya mẹrin kan ni ibudokọ Amje, to wa ni alagbado niluu Eko.
Iroyin ni meji lara awọn ọmọ iya naa jade laye, nigba ti awọn meji to ku ti n gba itọju nile iwosan.
Amọ ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ẹnikan lo dagbere faye, nigba ti awọn marun un mii farapa yanayana.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, oniruru ijamba lo maa n waye nitosi ibudokọ naa nitori awọn to maa n gba 'one-way' lagbegbe ọhun to wa ni opopona Abeokuta si Eko.
Oṣojumikoro kan sọ fun awọn akọroyin pe iṣẹlẹ naa waye lasiko ti awọn ọmọ iya naa n bọ lati ile ijọsin lọjọ Aiku.
O ni "Awọn ọmọ naa kagbako iṣẹlẹ laabi ọhun nigba ti wọn n bọ lati ṣọọṣi."
"Kii ṣe oni ni a ti n bẹ ijọba ki wọn ṣiju aanu wo lori ọna yii, paapaa awọn ọlọpaa lati maa mu gbogbo awọn to ba n gba one-way naa, amọ niṣe ni wọn kọ eti ikun si wa… o tun ti ṣẹlẹ bayii o."
Ẹlomiran ti ọrọ naa ṣoju rẹ, Akeem Tajudeen, ni oun ni oun gbe awọn ọmọ naa digbadigba lọ sile iwosan Ajike, ti wọn si fi da oun loju pe meji ninu wọn ti dagbere faye.
Dẹrẹba ọkọ naa dero atimọle
Lẹyin iṣẹlẹ naa ni awọn ọdọ adugbo ọhun bẹrẹ ifẹhunuhan, ti wọn si bẹ'gi di ọna naa.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Adekunle Ajisebutu fi lede, o ni awọn ti fi ṣikun ofin mu awakọ naa, iwadii si ti bẹrẹ.
O ni "Ijamba ọkọ buburu kan waye ni ibudokọ Amje, ni Ajegunle, Alagbado, eyii to kan ọkọ Toyota Highlander SUV kan ti orukọ awakọ rẹ n jẹ Akinola Sulaimon."
"Nigba ti ọkọ naa n bọ lati Toll Gate lagbegbe Kola Bus Stop lo rọ lu awọn ṣọọbu kan nibi ti obinrin kan, Simisola Abedoye ti jade laye, nigba ti awọn marun un mii farapa gidi."
"Oku ẹni to jade laye ti wa nile igbokusi nigba ti awọn to farapa ti n gba itọju lọwọ ni General Hospital to wa niluu Ota, ipinlẹ Ogun."















