Modele Sarafa Yusuf vs Dapo Abiodun: Ọ̀rọ̀ àárín èmi, Dapo Abiodun àti Ọlọ́hun ni èyí àmọ́...
Modele Sarafa jẹ obinrin to ti foju han gẹgẹ bii ọkan lara awọn ti yoo du ipo gomina ipinlẹ Ogun.
Titi di asiko yii, o ṣi wa ninu iṣejọba Gomina Dapo Abiodun to jẹ gomina ipinlẹ naa lọwọlọwọ gẹgẹ bi ọkan lara awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ papọ.
Iyalẹnu lo jẹ fun awọn eeyan nigba to kede erongba rẹ lati gbe apoti idibo eyi to si n mu awọn eeyan sọrọ pe kilode to fẹ koju ọga rẹ ti wọn yoo jọ maa figagbaga.
Ẹwẹ, ọtọ lọrọ rin nigba ti BBC Yoruba de ọdọ Arabinrin Modele Sarafa-Yusuf fun ifọrọwanilẹnuwo lori "ki lo ri lọbẹ to fi garu ọwọ" to jẹ ibeere awọn eeyan.
Oluwo gbóríyìn fún Awujale, Akarigbo fún àyípadà òfin lórí àṣà àtijọ́ fún yíyàn Ọba, ṣíṣe ìsìnkú Ọba
Gẹgẹ bi alakalẹ ofin Naijiria, ko sohun to buru ki ẹnikẹni gbe apoti idibo niwọn igba to ba ti ni amuyẹ rẹ. Amọ ero awọn eeyan lo saba maa n mu iriwisi ọtọọtọ wa lori bi oṣelu ṣe n lọ ni Naijiria.
Modele Sarafa ṣalaye ohun gbogbo fun BBC Yoruba latori bo ṣe ni oun lọ bere lọwọ ọga oun, Dapo Abiodu pe ṣe o fẹ gbe apoti idibo ati esi ti o fun un.
O ni Ọlọrun ti fi awọn nkan si oun lọkan ti awọn le ṣe lati mu iyipada ba ipinlẹ Ogun.
"Kii ṣe pe ko dara bayii o amọ o ṣi lee dara ju bayii lọ".
"Teeyan ba fi owo pilẹsẹ idibo, to ba debẹ a jale tori ẹni to ba ṣowo gbudọ jere".
Modele n sọ eyi tori o ni ara ibeere tawọn eeyan maa n bi oun ni pe nibo loun ti fẹ ri owo na fun igbesẹ ti oun gbe yii o si da wn lohun pe kii ṣe ohun gbogbo ni owo.
Ta ni Modele Sarafa-Yusuf?
Ọmọ Iperu Remo ni Modele ni ipinlẹ Ogun.
Oun ni olubadamọran agba lori eto iroyin fun gomina ipinlẹ Ogun amọ o ni oun ti yọwọ nibẹ nigba ti oun kede gbigbe apoti idibo.
Oniroyin ni Modele Sarafa. Gẹgẹ bo ṣe sọ, oun ni akaroyin obinrin akọkọ ni ilẹ adulawọ to kọkọ royin nipa ere idaraya lori ẹrọ amohunmaworan.

