Ogun State: Èmi ò ní bojúwẹ̀yìn lórí ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ nípìnlẹ́ Ogùn- Abiọdun

Oríṣun àwòrán, @dabiodunMFR
Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun, ti sọ pe ijọba oun ko ni boju wẹyin lori eto ẹkọ ọfẹ ni gbogbo ileewe alakọbẹrẹ ati girama nipinlẹ ọhun.
Gomina Abiọdun lo sọ ọrọ yii ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ijọba, Kunle Somorin, buwọlu nilu Abẹokuta tó jẹ olu ilu ipinlẹ Ogun.
O sọ ninu atẹjade naa pe "Ipinlẹ yii ko fun alaṣẹ ileewe girama ati ileewe ikọṣẹ ọwọ kankan laṣẹ lati gba owo ileewe lọwọ ẹnikẹni, gẹgẹ bi ahesọ ti awọn kan n sọ kiri."
Dapo Abiọdun tun rọ awọn eeyan ipinlẹ Ogun pe, ki wọn maṣe kọ ibi ara si awọn ahesọ ti awọn kan n sọ kiri.
O ni oun naa ti ka iroyin ofege kan to ni pe awọn ọmọ ileewe ni lati san owo ileewe nigba ti wón ba bẹrẹ saa tuntun losẹ to n bọ.
Lẹyin naa lo wa fi kun un pe, ki awọn eeyan ipinlẹ Ogun ni igbagbọ ninu iṣejọba oun ki oun lee dari ọkọ ipinlẹ na si ebute ayo.
Gomina na sọrọ yii leyin atẹjade kan ti ileeṣẹ to n mojuto eto ẹkọ nipinle ọhun fi kede pe, ki awọn ọmọ ileewe mura lati san ẹgbẹrun mẹrin din lọọdunrun naira fun saa kan.








