Ogun Election: Ilé ẹjọ gbé àga lọ rèé jókòó jẹ sílé fún Ọsunsanya.

inec

Oríṣun àwòrán, Inec

Àkọlé àwòrán, Ogun Election: Ilé ẹjọ gbé àga lọ rèé jókòó jẹ sílé fún Ọsunsanya.

Ile ẹjọ ti n ri si igbẹjọ eto idibo ni ipinlẹ Ogun ti pe fun atundi ido to gbe Aṣojuṣofin Kọlapọ Osunsanya wọle.

Ọjọ Aje ni Abeokuta ni Adajọ Wakkil Alkali Gana ti dajọ wi pe ibo ti o gbe Kọlapọ wọle ko dan mọnran.

Ọsunsanya to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti o si n ṣoju aarin gbungbun ipinlẹ Ogun ti ile Igbimọ Aṣofin kekere.

Àkọlé fídíò, 'Gbogbo olùdíje Ogun fi dá àwọn ènìyàn lójú pé...'

Ile ẹjọ to n gbọ igbẹjọ lẹyin eto idibo fagile ibo ijọba ibilẹ mẹta ti o gbe Ọsunsanya wọle lataari magomago ti oludije ninu ẹgbẹ oṣelu PDP fi kan an.

Oludije ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ti o jẹ olupejọ, Ọgbẹni Taiwo Shotẹ, ni ibo ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun yii ni awuruju ninu.

O ni ki ile ẹjọ fagile ibo naa, ni eyi ti ajọ eleto idibo nilẹ yii INEC ti kede ọmọ ẹgbẹ oselu APC gẹgẹ bi olubori.

Lẹyin iwadii, Ile ẹjọ ti wa paṣẹ bayii lati da ibo naa sọnu ki wọn si ṣe atundi ibo laarin aadọrun un ọjọ.