Ọbásanjọ́: Ojú bọ̀rọ̀ kọ́ lẹgbẹ́ alájùmọ̀se yóò fi gba ìjọba

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ààrẹ Naijiria nígbà kan rí Olusegun Obasanjo ti ní kí àwọn ẹgbẹ́ atúnlùúṣe gbára dì nítorí àtakọ ń bọ̀ láti ọ́wọ́ ìjọba to wà lóde yìí.
Obasanjo sọ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà ní Ibadan pé iṣẹ́ ńlá ń bẹ níwájúu wọn o, nítorí ojúbọ̀rọ̀ kò ṣeé gbọmọ lọ́wọ́ èkùrọ́.
O ni, "Àwọn kan ní bí wọ́n ṣe daadaa, bi wọn kò ṣe dáadáa, àwọn yoo máa ṣèjọba lọ, wọ́n yóó sì tún lo gbogbo agbára tí wọn ní lati dúró sórí àlèéfà."
"Ẹ má tan ara yín jẹ, kò lè dẹrùn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tó ṣe tàná ni yóò tún ṣe tòní. Ẹ̀rù kò bà wá rárá nítorí Ọlọ́run n bẹ lẹ́hin wa."
Gómínà Ìpínlẹ̀ Osun nígbà kan rí, Olagunsoye Oyinlola àti igbákejì gómínà Ìpínlẹ̀ Oyo nígbà kan rí, Taofeek Arapaja wà nínú ìpàdé náà.
É ó rantí pé Obasanjo ti kó àwọn ẹgbẹ atúnlùúṣe kan sọ̀dí pẹ̀lú èròǹgbà láti ríi pé ìjọba míràn wọlé ní 2019.








