Ilé ẹ́jọ́ tó ń gb'ẹ́sùn ìdìbò wọ́gilé ẹjọ́ tí Ajimọbi pè tako Kọla Balogun

Àkọlé fídíò, Iléẹ́jọ́ tó ń gb'ẹ́sùn ìdìbò wọ́gilé ẹjọ́ tí Ajimọbi pè tako Kọla Balogun

Sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun idibo guusu ipinlẹ Oyọ, Kola Balogun ti sọrọ lori ifidirẹmi Sẹnetọ Abiola Ajimobi to pẹjọ tako lori ipo Senetọ.

Balogun ni idajọ naa jẹ aṣeyọri fun iṣejọba awa-ara-wa ni Naijiria ati fawọn eeyan ẹkun idibo guusu ipinlẹ Oyo.

O wa sọ pe ti Sẹnẹtọ Ajimobi ba fẹ maa ba Ọlọrun ja lori idajọ naa ''ki o mura sii, a o wo ẹni ti yoo pegede.''

Sẹnetọ naa sọ ọrọ yi nigba ti o n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin aṣeyọri rẹ nilu Ibadan

Saaju ni Ile ẹjọ to n gb'ẹsun idibo ni agbegbe Iyaganku niluu Ibadan ti wọgile ẹjọ ti gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Ọyọ Ṣẹnetọ Isiaka Abiọla Ajimọbi.

O pe ẹjọ yii tako ẹni ti wọn kede gẹgẹ bi olubori ninu idije si ipọ Sẹnetọ ẹkun idibo guusu ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Kọla Balogun.Adajọ Anthony Apkovi ti o ṣoju igbimọ ẹlẹni mẹta ti o risi igbẹjọ naa lo kede abajade iṣẹ iwadii wọn lọjọ Iṣẹgun.Lara awọn ẹsun ti Abiọla Ajimọbi fi kan Kọla Balogun naa ni aiṣe eto idibo abẹnu ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ki o to dije, ṣiṣẹ amulo awọn janduku lati ji apoti ibo gbe, titọwọ bọ akọsilẹ ẹsi ibo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Aworan inu ile ẹjọ

Sugbọn ile ẹjọ ni gbogbo ẹsun naa ni ko ri ẹsẹ walẹ nitori aisi ẹri aridaju.Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn akọrọyin, ọkan lara awọn agbẹjọro fun Sẹnetọ Kọla Balogun, Amofin Isiaka Abiọla Ọlagunju ṣe alaye wi pe ohun ti ko kan Ajimọbi lo n dasi.

O ni ki lo kan Ajimọbi nipasẹ ẹsun ti o fi kan pe Sẹnetọ Balogun ko kopa ninu eto idibo abẹnu ki o to dije ninu ẹgbẹ oṣẹlu PDP.

Ọlagunju tẹsiwaju wi pe ifẹ ọkan awọn ara ilu lo gbe onibara oun de ipo ti ko si ni ohunkohun ṣe pẹlu ẹsun mago-mago ti ẹgbẹ oṣelu APC fi kan an.O ni ohun idunnu nla lo jẹ wi pe idajọ naa so eso rere fun Sẹnetọ Kọla Balọgun lẹyin ọpọlọpọ atotonu.

A gbiyanju lati ba awọn agbẹjọrọ ati alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC sọrọ lẹyin idajọ naa, ṣugbọn pabo lo jasi.Ariwo ọkan-o-jọkan orin lo gba ẹnu gbogbo awọn alatilẹyin Sẹnetọ Kọla Balogun kan lẹyin idajọ naa.

Kọla Balogun ti o ti fi igba kan ri jẹ kọmiṣọna fun karakata ati amojuto awọn ẹgbẹ alajẹṣẹku ni ipinlẹ Ọyọ ni wọn kede gẹgẹ bi ẹni ti o jawe olubori ninu eto idibo si ipo Ṣẹnetọ ẹkun idibo guusu ipinlẹ Ọyọ naa.

Àkọlé fídíò, APC: òfin NYSC ti APC fi mú mi ni wọ́n kò lò fi mú Ajimọbi tí a kò jọ sìnrú ìlú

Eto idibo naa o waye lọjọ kẹtaleogun, oṣu keji ọdun 2019.

O ni akojọpọ ibo 105,720, ti gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ Abiọla Ajimobi si ṣẹ ipo keji pẹlu onka ibo 92,218.

Aworan inu ile ẹjọ

Bi ọrọ ti ṣe lọ

Senetọ Ajimọbi ni oun ni oun jawe olubori ninu eto idibo to kọja nipinlẹ Oyo.

Idibo yii ni oun ati Kola Balogun ti PDP ti dijọ dupo lori ṣiṣoju guusu ipinlẹ Oyo ni Abuja.

Loni ni igbẹjo naa waye nile ẹjọ ọhun.

Aworan inu ile ẹjọ

Ẹjọ ti Ajimọbi fi sun ni wi pe Kọla Balogun kọ ni awọn eeyan dibo fun ninu eto idibo to waye loṣu keji ọdun yii.

Aworan inu ile ẹjọ

Gbogbo awọn alatilẹyin igun mejeeji ti ji de ile ẹjọ ni kutukutu owurọ oni ti wọn si n reti ohun ti yoo gbẹyin ẹjọ naa.

Aworan inu ile ẹjọ

Laipe yii ni akọwe ile ẹjọ naa ranṣẹ wi pe o di aago meji ọsan oni ki idajọ to waye.