PDP: Àrà tó bá wu Gomina Ajimobi kó dá lọ́sẹ̀ kan tó kù yìí

Oríṣun àwòrán, Google
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ oselu PDP ti ni igbesẹ Gomina Ajimobi lori bi o se yan olori osisẹ tuntun ko di awọn lọwọ ninu eto ti awọn ni silẹ.
Akeem Olatunji to jẹ agbẹnusọ fun ẹgbẹ oselu PDP ni gomina Ajimobi lo si wa lori oye, bẹẹ lo si ni anfaani lati se ohun to wu u.
Olatunji ni awọn ko le e sọ pe awọn fọwọ si igbesẹ naa tabi awọn ko fọwọ si i, ṣugbọn awọn yoo wo igbesẹ naa finifini ti awọn ba de ipo, lati wo boya ọna to gba de ipo ba ofin mu gẹgẹ bi akowe agba tabi bẹẹ kọ.
O fikun un pe ohun to wu gomina naa lo n se nipinlẹ naa, amọ ko da eto ẹgbẹ oṣelu PDP to jawe olubori ninu idibo to kọja ru nitori ẹka osisẹ yato si eto oselu lorilẹ-ede Naijiria.
Ti a ko ba gbagbe, ni Ọjọru, ọsẹ yii ni gomina Abiola Ajimobi yan abileko Ololade Agboola gẹgẹ bi adari awọn osisẹ tuntun, lẹyin ti abileko Hannah Ogunnesan ko iwe fi ipo silẹ.











