Jiti Ogunye: Ọ̀jẹ̀lú ni àwọn tó ń fi APC sílẹ̀ fún PDP

Ẹgbẹ oselu APC

Oríṣun àwòrán, APC

Àkọlé àwòrán, Ajafẹtọ ọmọniyan, Jiti Ogunye ni ọna abayọ si eto oselu Naijiria ni ki awọn eniyan yan ẹgbẹ oselu tuntun.

Ajafẹtọ ọmọniyan, Jiti Ogunye ti ni awọn oloselu ti wọn n kuro ni ẹgbẹ oselu kan lọ̀ si ẹgbẹ oselu miran ko fẹran awọn ọmọ Naijiria, ati wi pe ikun wọn ni wọn n ja fun.

Jiti Ogunye nigba to n ba BBC sọrọ lori bii awọn asofin se sigun kuro ni ẹgbẹ oselu APC losi PDP saaju idibo gbogboogbo ni ọdun 2019.

O ni Ojẹlu ni gbogbo awọn oloselu ti wọn n fi ẹgbẹ oselu APC silẹ fun ẹgbẹ oselu PDP, ati wipe oju wọ̀n kan wa ni APC ni sugbọn kan wa ni PDP ki wọn to darapọ mọ ẹgbẹ oselu PDP.

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ rántí orin - Má ṣe jẹ́jẹ́ ma wà mi lọ?

Ọna abayọ si ipenija eto oselu ni Naijiria

Jiti Ogunye

Oríṣun àwòrán, Jiti Ogunye

Àkọlé àwòrán, O parọwa si awọn alawọdudu lati fẹran ara wọn nitori awọn ara ilu ni o le yan eniyan ti yoo tukọ wọn lo si ilẹ ileri si ipo.

Ajafẹtọ ọmọniyan naa fi awọn oloselu naa we onisowo ti o seese ki o fi okoowo kan silẹ fun omiran nitori ko pe wọn mọ.

Jiti Ogunye wa kesi "awọn ara ilu lati wa wọrọkọ fi se ada nitori wọn ko le gbẹkẹle awọn oloselu to n kaakiri naa nitori wọn kii se eniyan gidi".

O parọwa si "awọn alawọdudu lati fẹran ara wọn nitori awọn ara ilu ni o le yan eniyan ti yoo tukọ wọn lo si ilẹ ileri si ipo".

Èyí ni orúkọ àwọn sẹnatọ tó fi APC sílẹ̀ lọ sí PDP àti ADC

  • Lanre Tejuosho (Ogun) - ANPP - CPC - APC - PDP - APC
  • Dino Melaye (Kogi)
  • Barnabas Gemade (Benue)
  • Ibrahim Danbaba (Sokoto)
  • Shaaba Lafiaji (Kwara)
  • Ubali Shitu (Jigawa)
  • Rafiu Ibrahim (Kwara)
  • Suleiman Hunkuyi (Kaduna)
  • Isa Misau (Bauchi)
  • Monsurat Sunmonu (Oyo) APC-ADC
  • Soji Akanbi (Oyo) SDP - AD - APC
  • Usman Nafada (Gombe)
  • Musa Kwankwaso (Kano)
  • Suleiman Nazif (Bauchi)
  • Abdulaziz Murtala Nyako (Adamawa) ADC.