Oyo TUC: A ṣì fa ìjọ̀ba léti ni pẹ̀lú ìyanṣẹ́lódì

Emmanuel Diran

Oríṣun àwòrán, Emmanuel Diran/Facebook

Àkọlé àwòrán, Emmanuel Diran

Ẹgbẹ awọn lọgalga lẹnu iṣẹ Ọba ni ipinlẹ ọyọ, TUC ti pa ẹnu p sọ pe awọn ko ni jami lori ọrọ ifẹhonu han bi ijọba ba kọ lati ṣe ohun ti wọn n beere fun.

Alaga ẹgbẹ awọn lọgalọga lẹnu iṣẹ ọba ẹka ti ipinlẹ Ọyọ, Comrade Emmanuel Ogundiran lo tẹpẹlẹ mọ ọrọ yii nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ.

Comrade Emmanuel sọ pe lori ọr igbega lẹnu iṣẹ lawọn n ja fun eyi ti ijọba ipinlẹ Ọyọ si n fi ẹtọ awọn dun wọn.

O ni o ti pẹ ti ijọba ti ṣeleri igbega lẹnu iṣẹ fun awọn lati nkan bi oṣu keje ọdun 2018 to si jẹ wi pe awọn kan ti n jẹ mudun-mudun rẹ lẹka eto ilera.

sugbọn ni awọn to ku, ko sohun to jọ bẹẹ. O ni dipo ki awọn maa gbadun, ẹbu ni lẹta ti ijọba gbe le wọn lọwọ nitori awn kan gba igbega lasan ninu iwe ni, awọn ko gba owo oṣu to yẹ ko ba a rin.

Àkọlé fídíò, Woli Kasali: Angẹli mi ni orékelẹ́wà Dọlapo Awoṣika

Ẹwẹ, ọj meje ni ẹgbẹ TUC ipinlẹ kọkọ fun ijọba gẹgẹ bii gbedeke ki wọn to yi ọkan pada nigba ti wọn ri i pe ọrọ ori ahọn lasan ni gbogbo ileri ti ijọba n ṣe fun awọn.

Ni wọn ba yii si iyanṣẹlodi ọlọjọ mẹta lẹyin eyi ti Emmanuel sọ pe awn yoo pada sẹnu iṣẹ ṣugbọn bi ijọba ba kọ ti wọn o si ṣe nkankan, iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọin ni yoo ku.