Lizzy Anjọrin: Inú mi dùn láti di Bọ̀rọ̀kínnì Àdínnì

Yoruba ni oniruuru ọbẹ laa ri lọjọ iku erin, bẹẹ ni ọrọ ri lasiko ti ilumọọka elere tiata lobinrin kan, Alhaja Aisha Lizzy Anjọrin se iwuye oye ẹsin Bọrọkinni Adinni ti wọn fi jẹ.

Se ni agbegbe yaba nilu eko n ro gbarọ gbudu lasiko ayẹyẹ iwuye naa eyi ti ẹbi, ọrẹ, ololuf ati awọn alajọsepọ rẹ peju si.

Koda awọn isẹ ikinni ku oriire gan ko gbẹyin loju awn opo ikan sira ẹni Facebook ati Instagram, ti wn n ki Lizzy ku oriire oye tuntun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Woli Kasali: Angẹli mi ni orékelẹ́wà Dọlapo Awoṣika

Mama Oloye tuntun naa, Lizzy Anjọrin, si fi awọn aworan ayẹyẹ iwuye rẹ lu oju opo Twitter rẹ kan, diẹ lara rẹ ni iwọnyi.

Lara awọn eeyan to ba Lizzy se jaginni yodo oye tuntun naa ni Alaafin tilu Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta ati awọn olori rẹ meji.

Lizzy Anjọrin, Alaafin tilu Ọyọ ati awọn olori rẹ

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin

Kade pẹ lori laa ki ọba, ikunlẹ ati idọbalẹ si ni a ma n ki oriade nilẹ Yoruba, tori awọn arọbafin nikan lo n se lodi si eyi.

Lizzy Anjọrin ree to ba buruburu niwaju Alaaafin lati fi ẹmi imoore rẹ han si bi ori ade naa se wa yẹ si ni ọjọ iwuye rẹ.

Alaafin wa lori ijoko, ti Lizzy si kunlẹ lati yẹ si

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin

A kii ri ẹfọn ta lẹẹmeji lawọn eeyan fi fọto yiya se pẹlu Alaafin. Pinra-pinra si ni wọn nya fọto pẹ́lu baba.

Awọn obinrin to wọ asọ ẹgbẹjọda n ya fọto pẹlu Alaafin

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin

Mama oloye tuntun ree lagbo, Bọrọkinni Adinni tuntun, to wọ asọ olowo iyebiye, ti oju rẹ si dun wo

Lizzy Anjọrin

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin

Lara awọn eekan ilu lagbo orin kikọ to yẹ Bọrọkinni Adinni tuntun si ni Alhaja Salawa Abẹni ati Wasiu Alabi pasuma.

Salawa Abẹni ati Lizzy Anjọrin

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin

Lizzy Anjọrin ree pẹlu awọn afẹnifẹre miran lasiko ayẹyẹ iwuye ọhun.

Lizzy Anjọrin ati awọn ololufẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin

Awọn eyin funjowo ati ẹlẹyinju ẹgẹ ree nibi ayẹyẹ Lizzy Anjọrin

Awọn ẹlẹyinju ẹgẹ

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin

Iyabọ Ojo ree, ọkan lara awọn gbajugbaja elere ori itage lobinrin, ti wọn wa yẹ Lizzy Anjọrin si lọjọ iwuye rẹ.

Iyabọ Ojo

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin