Nigeria 2019: Ìròyìn ìdìbò 2019 ti gbérasọ lórí BBC pẹ̀lú #BBCNigeria 2019

Bẹrẹ lati ọjọ kẹtadinlogun oṣu kini ọdun 2019, ile iṣẹ iroyin BBC World Service yoo ma kajọ de iberẹ idibo 2019 lorileede Naijiria.
Oun ti eleyi tunmọ si ni wi pe gbogbo ohun to yẹ ki ẹ mọ nipa idibo naa ni ẹka BBC Yoruba, BBC Hausa, BBC Igbo ati BBC Pidgin yoo ma mu wa si eti igbọ yin gẹgẹ bi alakalẹ eto wa lasiko idibo yii.
Bi ẹ ba n wa awọn iroyin to munadoko, paapa julọ lori ẹrọ ayelujara, hashtag#BBCNigeria2019 ni ki ẹ maa lo lasiko idibo yii.
Bi awọn iroyin naa ba ṣe n wa leṣẹẹṣe ni ẹ o maa gbọ wọn lori ikanni wa.
Ẹ ma gbagbe wi pe awọn ipade itagbangba wa naa ti n lọ lọwọlọwọ ti a si rọ yin lati maa ba wa kalọ loju opo Facebook ati itakun ayelujara pẹlu hashtag#BBCNigeria2019











