Nairobi Attack: Ọ̀pọ̀ àwọn tó há síbi ìkọlú náà ló se ó dígbà lórí Twitter, Whatsapp

Awọn obinrin kan ti wọn doola ẹmi wọn kuro nibi iṣẹlẹ naa n yọ rin nibi ti awọn ọmọ ogun ti gbe ibọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Ikọlu Kenya
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O to ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rin èèyàn ti ori ko yọ ninu ikọlu awọn alakatakiti agbebọn ti wọn ṣigun lọ awọn ile iṣẹ ati ile itura lolu ilu Kenya, Nairobi

Wakati mọkandilogun ni ikọlu naa fi waye, eyi to bẹrẹ laago mẹta ọsan lọjọ iṣẹgun fi waye.

Iriri diẹ ninu awọn eeyan to ru iṣẹlẹ naa la, ti wọn mori bọ lọwọ ikọlu ikọ Al Shabab re e:

'Ile igbọnṣẹ ni a ha ara wa mọ'

Awọn akọroyin meji kan ti wọn ba ile iṣe iroyin orileede Kenya NTV ṣiṣẹ, wa lara awọn ti wọn ha sinu ikọlu naa to waye fun nnkan bi wakati mejila.

"inu ile igbọnṣẹ ni awa ati awọn akẹẹgbẹ wa kan ha si, "ni iṣẹ ti akoroyin Silas Apollo fi ranṣe si ori opo Whatsapp .

O kọ ọ sibe pe e "Ẹru n ba mi gaan."

Aworan awọn ọmọ ogun nibi ti wọn daya de ilẹ si

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Wakati mọkandinlogun lawọn agbofinro fi koju awọn agbebọn naa

O fi kun sinu Whatsapp pe "Niṣe ni wọn n lọ, ti wọn n bọ, ti wọn si n yinbọn laibikita. Ọrọ naa ko rẹrin rara,"

Awọn akọroyin naa sọ fun ile iwe iroyin Daily Nation pe, awọn ati awọn akọroyin mii ti wọn to mẹrinla ṣaa n rakoro lati inu ile igbọnṣẹ lọ si iyara kan si imiran titi ti wọn fi de gbagede nla .

Nigba ti yoo fi to aago mẹta kọja iṣẹju mẹẹdodun ni awọn agbofinro doola ẹmi wọn lọjọru.

'Mo fi ọrọ ranṣẹ loju opo Twitter'

Inu ọfisi rẹ nibi ti o ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bi alukoro fun ajọ to n ri si eto pipin owo to n wọle si asunwọn orileede Kenya, ni Ronald Ng'eno wa, to ti gbọ iro ''ibugbamu nla kan ti ariwo ibọn yinyin si tẹle''

Ronald Ng'eno
Àkọlé àwòrán, Ronald Ng'eno ti kowe ranse dagbere odigab si awọn mọlẹbi rẹlori Twitter

Oun ati awọn akẹgbẹ rẹ gbinyanju lati sa jade ṣugbọn awọn agbebọn naa ti wọle kan wọn lara.

O sọ fun ileesẹ iroyin AFP PE, "Bi wọn ṣe bẹrẹ si ni yinbọn lu wa, la sa gba ibo miran, ti a si sa pamọ si ile igbọnṣẹ to wa ni akasọ kinni. Mo ri alafo kan nibẹ ti mo sapamọ si''

Ronald salaye fun BBC pe ''A ha ara wa mọ ile igbọnṣẹ naa, ti a si dakẹ rọrọ.''

Ni igba ti yoo fi to nnkan bi ago meje ale, ti iro ibọn si n ro, ọgbẹni Ng'eno fi ọrọ ranṣe si ori Twitter pe oun ṣi wa ni ile igbọnṣẹ:

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Presentational white space

Lẹyin ti ikọlu naa ti to wakati maarun, ni o kọ ọrọ pe ẹrọ ibanisọrọ ohun ti fẹku.

Pupọ lo fẹsi si ọ́rọ to fi ranṣẹ sita, ti wọn si fi nọmba rẹ ranṣẹ si ọga awọn to n dari idoola ẹmi awọn eeyan.

Kia lọrọ to fi sita fọnka nitori pe o ti dagbere o digba fun awọn mọlẹbi rẹ ninu rẹ:

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Presentational white space

Awọn aworan miran nipa awọn tori koyọ ninu iṣẹlẹ naa re e:

Aworan ọkunrin kan ti awọn agbofinro n gbe jade kuro ninu ile ti ikọlu naa ti waye

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn agbofinro lo doola ẹmi awọn eeyan kuro ninu ile naa
Aworan Obinrin kan ti ori ko yọ ati mọlẹbi rẹ lẹyin ti wọn pade ara wọn

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Orin ọpẹ ati ayo lo kun ẹnu awọn ti ori ko yọ
ọlọpaa kan sare kọja lẹgbẹ ọkọ ti o n jona lọja kẹẹdogun osu kini 2019

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Lẹyin ti wọn yinbọn lu awọn ọlọde ile itura naa,awọn agbebọn naa sọ ina si awọn ọkọ
Awọn obinrin kan ti wọn doola ẹmi wọn kuro nibi iṣẹlẹ naa n yọ rin nibi ti awọn ọmọ ogun ti gbe ibọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ẹni ori yọ, ipade di ile lọrọ naa