Ìkọlù Kenya: èèyàn mẹ́rìnlá pàdánù ẹmi wọ́n ninu Ikọlù náà

Àkọlé fídíò, Ìbúgbàmù ńlá ati iro ibọn gbalẹ ni ile itura Nairobi

Ikọlu iyinbọnpaniyan to waye nile itura DusitD2 lorileede Kenya ti dopin lẹyin ti awọn agbofinro pa awọn agbebọn to wa nidi ikọlu naa.

Eeyan mẹrinla lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ohun .

Aarẹ orileede Kenya Uhuru Kenyatta lo kede ọrọ yi lọjọru.

Ko ti daju iye awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa ṣugbọn ọga ọlọpa lorileede Kenya Joseph Boinnet sọ fun ile iṣẹ iroyin AFP pe awọn maarun lawọn funra si pe o kopa ninu ikọlu naa

Awọn ọmọ ikọ Al-Shabab ti saaju kede pe awọn lawọn wa nidi ikọlu to waye nile itura kan nilu Nairobi.

Lọjọ iṣẹgun lawọn agbebọn sadede yabo ile itura Dusit lolu ilu Kenya ti ṣe Nairobi.

Iroyin ta gbọ ni pe eeyan kan ti ku ninu iṣẹlẹ naa ti awọn agbofinro si ti n gbiyanju lati doola awọn eeyan to ha sinu ile itura naa.

Aworan awọn ti wọn sa asala ẹmi wọn

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ikọlu Kenya

Ẹgbẹ Al Shabab fi ikede sita lati ọwọ agbẹnu sọ wọn kan to ba BBC Somalia to fidi joko silu Nairobi sọrọ.

O kere tan ibugbamu meji lawọn akoroyin sọ wi pe awọn ti gbo ninu ọgba ile itura naa.

Aworan awọn ti wọn sa asala ẹmi wọn

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan ti n sa asala fun ẹmi wọn nibi ikọlu naa

Ọga ọlọpaa nilu Kenya Joseph Boinnet, ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ wi pe awọn agbebọn yabo ile itura Dusit, ti wọn fura si wi pe o jẹ ''ikọlu awọn agbesunmọmi.''

O sọ pe "A mọ wi pe awọn agbebọn kan si yi wa ninu ile itura naa, ti a si gbọ wi pe awọn agbofinro wa ti n gbiyanju lati wọ idi wọn sita.''

O salaye pe awọn ọlọpaa ti doola ẹmi ọpọ eeyan ti o si rọ awọn ara ilu lati ma se kaya soke.

''A n gbiyanju lati dẹkun ikọlu yi ni kiakia''

line