Kano Emirate: Ṣé àwọn gómìnà ò máa tọwọ́ bọ àṣà lójú báyìi?

Kano emirate

Oríṣun àwòrán, Patrick van Katwijk

Àkọlé àwòrán, Emir Muhammadu Sanusi jẹ gómìnà báǹkì àpapọ̀ Nàìjíríà láàrin 2009-2014kó to dí Emir ìlú Kano
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ìròyìn tó gbòde láìpẹ yìí lóri ìpinu ìjọba láti pin ààfin ọba to tóbi jùlọ ni orílẹ̀-èdè Nàjíríà ìyẹn pínpín ọba jíjẹ si ọ̀nà márùn ni ìpínlẹ̀ Kano ní o ti ń mú onírúurú àwọn awuyewuye jẹyọ láàrín ọmọ Naijíríà, ti ọ̀pọ̀ sì ń sọ pé èté ìjọba lásán ni láti sọ ọbá ìpínlẹ̀ Kano Muhammed Sanusi dí aláìlágbára bí àwọn ènìyàn ṣe ni ìgbàgbọ́ pé kìí fi ọ̀rọ̀ sábẹ ahọn sọ fún ìjọba tó ń bẹ lóde ni ìpínlẹ̀ Kano.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nínu ìtàn to gbé ìjọba Emir kalẹ̀ ní Kano láti ọ̀ọ̀rùndún kẹẹ̀dógún sẹ́yìn ní ó ni ọwọ́ ìja Jìhádìì àti jàgídíjàgan àwọn onirúuru jagunjagun nínú láti ọdun 1903, ìjọba Emir ní Kano ti rídi joko dáada láti ẹyin wá. Ọ̀pọ̀ ìgbá si ni gbígbe ọba fún ẹni to kàn lẹ́yìn kìí níra lẹ̀yín ti Emir to wà lóri oye ba ti gbésẹ̀.

Ọ̀pọ̀ ló wá ń fòyà pé ṣe omi àlàfíà to wa ni Kano kò ni dàru báyìí, ìjọba ibilẹ̀ mẹ́rìnlélógóji pẹ̀lú ènìyàn to le nio mílíọ̀nù mẹ́sàn ni Emir ń dari, tí ó ti wá dínkù si ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́wàá báyìí nígbà ti wón ti pín ipò Emir si mẹ́rin.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Bí wọn ṣe ti wá jan ofin tuntun ọhun lóntẹ ti ìjọba Abdullahi Umar Ganduje si ti fọ́wọ́ si i lójọ́ru to kọjá, ọjọ kẹjọ ọsù karun ọdún 2019, ìjọba Emir to ti wá láti igba ọdún sẹyin ní ìpínlẹ̀ Kano tún ti bẹ̀rẹ̀ ìtàn túntún báyìí.

Òfín tuntun yìí rii dáju pé Emir ìlú Kano Alhaji Muhammed Sanusi Lamido Sanusi keji ti gbogbo ènìyàn mọ bi alágbára to si níkì láàrín àwọn ọba àti ẹlẹ́sìn ní orilẹ̀-èdè Naijirià ní wọn ti ìdá kan nínú ìdá márùn àgbára rẹ̀ sílẹ̀ fún, Wọn ṣe àgbákalẹ̀ àwọn ìjọba mẹ́rin míràn ti àwọn náà yóò si ná ààfin wọn.

"Kódà lásikò àwọn ìjọba òyìnbó amúnisìn, wọn ó fọ́wọ́ kan ìtàn Kano gẹ́gẹ́ bí èyí ti gómìnà wọn ń ṣe yìí" ọjọgban Tijani Naniya ti ẹka ìmọ̀ Itan Fasíti Bayero ni Kano lo sàlàye èyí. O sàpèjúwe ìdásílẹ̀ ìjọba túntún yìí gẹ́gk bi dída ìtàn ẹ̀yà kan rú ti kò si yẹ kí ẹnikẹni gbàá láàyhe láti wá si ìmúṣẹ

Kano emirate

Oríṣun àwòrán, ISSOUF SANOGO

Àkọlé àwòrán, Ado Bayero to waja jẹ ara ilé baba Emir Muhammed Sanui II

"Ǹkan tó ṣẹ̀lẹ̀ ni ìpínlẹ̀ Kano ni ọ̀sẹ̀ to kọja ṣe àfihan gbangba ọ̀nà láti tún ìtàn àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Kano kọ, ìtàn to ti pé ẹgbẹ̀rún kan ọdún, kódà nígbà ti àwọn ìjọba òyìnbó amúnisin wá wọn ó fọ́wọ́ kan ìtàn wa, kílo wá de ní àsìkò yìí? Báwo ni ìtàn ti ó ti pẹ́ to èyí yóò kan ṣe dojú bolẹ̀ láàrín ọjọ́ mẹ́ta péré, èyi ko bójú mu rárá, ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ nínú."

Ẹwẹ́, ọ̀tọ̀ lójú ti ìjọba Kano fi wo ọ̀rọ̀ náà, nínú àtẹjáde kan ti wọn fi síta sọ pé ìdí ti àwọn fi pin ìjọba Emir Kano ni láti mú ki ọba súnmọ àwọn ara ilú ni ìgbèríko

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Ọ̀jọ̀gbọ́n náà fí kun pé òun ni ìgbàgbọ́ pé ìlànà tuntun yìí to ni Emir marún-ùn kàkà ti yóò fi jẹ ẹyọkan ko ni pẹ ti yóò fi doju, nítori pe gómìnà ìpínlẹ̀ Kano nígbà kan rí, Abubakar Rimi ti gbìyànjú rẹ̀ ni ọdún 1982 tí gbogbo rẹ̀ sì dàyàbolẹ̀ láàrín ọdún kan

Ọ̀kan nínú àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Kano Zakari Mohammed sàlàyé pé láì bèrè nípa pe a tún ìtàn kọ, oun ni ìgbàgbọ́ pé ọnà túntun ni láti rii dáju pe àwọn ara ìlú yóò ni ànfani láti súmọ ìjọba àti àwọn aláṣẹ.

Kano emirate

Abdullahi Sani to tun jẹ aráìlú Kano míràn sọ pe ọmọ ogoji ọdun ní oun, Emirati Kano si ni òun mọ ti òun si fẹ́ràn

Ẹlòmiràn to tún ni ìpèníja ojú to si jẹ olùgbé Kano, Saifullah Mukhtar sọ pé oun ri ìgbẹ́sẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bii ǹkan to dára ti yóò si ní ipa lára àwọn ara ìlú ti yóo si mu ki ọbá súnmọ ara ìlú, àti pe àdíkù yóò ba diduro fún ìgbà pípẹ́ láti gbọ abọ láti Emir Kano

Kano emirate

Bótilẹ̀ jẹ́ pe àwọn ìwé ìròyín ìbílẹ̀ sàlàye pe ilé ẹjọ gíga ní ìpínlẹ̀ Kano ni ọjọ jímọ to kọja ti fi iwé síta pé gómìnà ò ní àṣẹ láti fi àwọn Emir túntun náà lọ́lẹ̀, síbẹ̀ ìjọba ti fi ọ̀pá àṣẹ́ le àwọn Emir tuntun náà lọ́wọ́ lọ́jọ́ ajé

Láàrin gbogbo ìṣẹ́lẹ̀ yìí, ó ṣe pàtaki láti mọ̀ pé ìpínlẹ̀ Kano nìkan kọ ni ìrú èyí kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ si ní ǹkan to jọ bi ẹni pe o ní ọ̀rọ̀ òṣèlú nínú ní lọ́lọ́ yìí.

ÌPINLẸ̀ IMO

Ní ọdún 2015 Gómìnà Rochas Okorocha ti ìpínlẹ̀ Imo ti ṣe irú ǹkan to jọ báyìí pẹ̀lú Eze Owerri nígbakan ri, olóògbé Eze Emmanuel Emenyonu Njemanze, OzuruIgbo V ti Oweri nígbaà ti Oba ou fẹsun kan pé Rochas ń pin ilú Owerri àti gbogbo ìpínlẹ̀ Imo lápapọ.

Rochas

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/ROCHAS

Àkọlé àwòrán, Gomínà Okorocha gbe igab ibo latia di sẹnatọ ni ọdun 2019 lẹ̀yìn to ti lo ọdun mẹ́jọ gẹ́gẹ́ bii gomina Imo

Nígba ti gbogbo ẹ gbónà tan láàrin àwọn mejèèji, ní ìjoba Okorocha fún Eze naa ni ìwé lọ gbélé ẹ gẹ́gẹ́ bi ìgbákeji alaga Eze Njemanze fún gbogbo Ndi-Eze to jẹ ẹka to n gbẹ́jọ

The state government in a statement denied the allegation saying, "It has no hand in the suspension of the four traditional rulers and the trial of more than fifty others by the Ezes' Council." It however added "… the government will however not hesitate to act on the recommendations of the Ezes' Council as long as it would be in the interest of the State…"

Lẹ́yìn náà ni ìjjọba gbé atẹjade kan sita pe ọ̀rọ̀ náà ko ri bẹ́ẹ̀ " A ò ní ọ́wọ́ nínú yíyọ àwọn ọba mẹ́rin ti gbigbe àwọn ààdọta lọ siwaju igbimọ àwọn Ezes lati jẹjọ, Ẹ̀wẹ̀ fikun pé ìjọba kò ni kọ ìmọran àwọn ǹkan to tọ láti ṣe fun igbimọ àwọn Eze níwọn ìgbà ti yóò ba ti mú ìlọsíwáju ba ìpínlẹ̀ Imo

Eze Njemanze, Owerri

Oríṣun àwòrán, Alamy

Àkọlé àwòrán, Eze Njemanze lo ọdun mẹ́tàdínlọgbọ̀n titi to fi kún ni ọdun 2016 lẹ́yìn ọdun mẹ́rìnlélọ́gọ́rin

Nítori náà gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sẹlẹ̀ ní Kano, bẹ́ẹ̀ ni ijọba Okorocha se pin awon lọbalọba si àgbégbe márun ti onikaluku si ni ọba ti wọn.

Lóníì ipinlẹ Imo ni ìlú mẹ́tàdinlogojiléẹgbẹ̀ta pẹlu ọba wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ ti o si jẹ gómìnà Okorochanáà lo yan wọn

IPINLẸ OYO

Ní ìhà Gúúsù-Iwọ̀-òòrun Nàìjíríà Ìpinlẹ̀ Oyo, àwọn ti koju ǹkan to farapẹ irú ǹkan bayiìí laipẹ yìí nígbà ti Gomina Ajimobi àti Oba Saliu Adetunji to jẹ Olubadan ti ìlú Ibadan

Oyo governor

Oríṣun àwòrán, @AAAJIMOBI

Àkọlé àwòrán, Governor Ajimobi fìdírẹmi nínú ìpo ṣẹnatọ to dije fún lọdun 2019 lẹ́yìn to ti ṣe Gomina Oyo léèmèjì

Ní inú oṣù kẹ́jọ ọdun 2017 Ajimobi sún àwọn mogaji mọkanlélógun sí ipò ọba èyi to mu wọn duro ni ipò kan náà pẹ̀lú Olubadan.

Olubadan, Oyo

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/SALIU ADETUNJI

Àkọlé àwòrán, Oba Adetunji ní Olubandan kọkanlelógoji , o gori oye ni ọdun 2016 lẹni ọmọ ọdun méji din ni ààdọrun

Pẹlu ìgbésẹ̀ yìí wọn gomina ti ti fowokan ilana asa to ti wa tipẹ, ni ìha keji, gomina ni ko si n kan to yii itan pada, ko si nkan to yi iṣenabye pada, bakan naa ni asa o lọ si ibikan nilu Ibadan, bíkose pe àwọn ń mú ìdàgbàsoke ati igbelarugẹ ba àwọn ọlọye to ti wà nilẹ tẹ́lẹ̀

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Olubadan ti ọrọ náà kan gbe gomina Ajimobi lọ si ile ẹjọ pe ki ó dá aṣẹ náà pada, bakan náà ni Gomina Oyo tẹlẹ ri Alhaji Rasheed Ladoja to jẹ ọkan lára àwọn Mọgaji ti wọn gbe ga kọ ipò náà to si lodi si ìgbésẹ̀ gomina pe oun kò le jẹ ọba lai ni ààfin

Ninu oṣù kini ọdun 2018 ni ile ẹjọ giga ni ìpínlẹ Ọyo dájọ pe ìgbésẹ̀ gomina lòdi si òfin, bákan náà ni Gomina náà ti gbe ẹjọ lọ ile ẹjọ kòtẹmilọrun