Ẹgbẹ́ IMN:ọmọ ẹgbẹ́ wa mẹ́tàlá ní ọlọ́pàá yìnbọn pa níbi ìwọ́de ìdárò Ashura

Oríṣun àwòrán, Google
Fakinfa laarin ọlọpaa Naijiria ati ẹgbẹ ọmọ Shiite( IMN) tun ti gbọna mi yọ pẹlu bi ẹgbẹ naa ti ṣe ni ọlọpaa yinbọn pa ọmọ ẹgbẹ awọn mẹtala.
Saaju lowurọ ọjọ Iṣẹgun ni ẹgbẹ naa ti ni awọn ọlọpaa yabo awọn ọmọ ẹgbẹ wọn kaakiri ibi ti wn ti ṣe iwọde ni Naijiria.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ wọn Ibrahim Musa ti ṣe ṣalaye fun BBC, o ni awọn ọlọpaa pa eeyan mẹfa ni Bauchi,mẹta ni Kaduna ,meji meji ni Sokoto ati Gombe ati ẹnikan ni Katsina.
Musa ni o ṣeeṣe ki iye eeyan to ku ṣi lekun si nitori bi awọn ọmọ ẹgbẹ wn ti ṣe faragbọta.
Ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ti tako ọrọ yi pe awọn ko yinbọn pa ọmọ ẹgbẹ Shitte kankan bi kii ṣe pe awọn tu awọn to pejo lati ṣe iwọde ka.
Ohun ti a ti jabọ saaju nipa iroyin yi
Loni ni iwọde ni iranti iku Imam Hussein to jẹ ọmọ ọmọ anọbi n waye lọdọ awọn ẹlẹsin Shiite lagbaye
Lẹyin ti iroyin gba oju ayelujara pe awọn agbofinro ti pa mẹta ninu awọn ọmọ ẹyin Shiite ni Kaduna, BBC kan si abẹnugan awọn Shiite.
Ibrahim Musa to jẹ agbẹnusọ fun IMN ṣalaye fun BBC pe ootọ ni pe ọmọ ẹyin awọn mẹta ti ku ni Kaduna bayii.
Lẹyin eyi ni BBC kan si ileeṣẹ ọlọpaa ni Kaduna lati fidi ọrọ yii mulẹ.
Alukoro awọn ọlọpaa ni Kaduna, PPRO wọn ni irọ funfun balau ni awọn ẹlẹsin Shiite n sọ.
Ọga ọlọpaa Yakubu Sabo to jẹ alukoro ọlọpaa ni Kaduna ṣalaye pe ọlọpaa ko pa ẹnikẹni.

Oríṣun àwòrán, @SZakzakyOffice
O fidiẹ mulẹ pe ootọ ni pe awọn ọmọ ẹgbẹ Shiite kora wọn jọ fun iwọde ṣugbọn wọn ti tuka bayii nibi eto Ashura ti wọn n ṣe.
O ni ko si ẹnikọkan ti agbofinro yinbọn fun bi awọn Shiite ṣe n pa irọ kiri lori ayelujara.
Shiite ni ọlọpaa ti pa mẹta ninu àwọn ni Kaduna lasiko iwọde iranti iku ọmọ ọmọ Anọbi.
Eeyan mẹta lo ti jalaisi bayii nibi irin idaro Ashura ti awọn ọmọlẹyin Shite ṣe nilu Kaduna.

Oríṣun àwòrán, @tostvnetwork
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ IMN atawọn ọmọlẹyin Shiite ni Naijiria, Ibrahim Musa ṣalaye fun BBC pe awọn ọlọpaa lo yinbọn pa mẹta ninu awọn ọmọlẹyin Shiite naa nilu Kaduna
Bakan naa lo tun ṣalaye pe awọn ọlọpaa ti tilẹkun mọ ọmọlẹyin Shiite ni olu ileeṣẹ ẹgbẹ IMN ni ilu Ṣokoto lati kawọn lọwọ ko ki mọ maa baa jade lọ ṣe iwọde wọn.
Gẹgẹ bii ileri ti wọn ṣe, awọn ọmọlẹyin Ibrahim Elzakzakky to jẹ aṣiwaju ijọ ẹsin Shiite ni Naijiria fọn si igboro lọjọ Iṣẹgun lati ṣeto irin idaro Ashura eleyi ti gbogbo awọn ẹlẹsin Shia kaakiri agbaye maa n ṣe ni ọjọọjọ kẹwaa, oṣu kẹsan an, ọdun.
Wọn tun fi sita loju opo twitter wọn yatọ si pe wọn sọ fun BBC lori ẹrọ ibanisọrọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Wọn n ṣe eto yii ni iranti Imam Hussein, ọmọ ọmọ Anọbi to ku ninu ogun Karbala.
Amọṣa ni ilu Abuja, awọn ọmọlẹyin Shiite naa ko lo to ọgbọn iṣẹju fun irin wọn naa ti wọn fi ṣẹri pada sile.
Awọn onwoye ni aifẹ idojukọ pẹlu awọn ọlọpaa lo mu ki wọn tete ṣẹwe le irin naa eleyii ti o ti da ọpọ ipaya si ọkan awọn olugbe ilu Abuja lati igba ti wọn ti kede pe awọn yoo ṣee.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti paroko ikilọ ranṣẹ sawọn ọmọlẹyin Shiite naa pe ko si aye fun wọn lati ṣe irin aro naa nitori gẹgẹ bii aṣẹ ile ẹjọ, ẹgbẹ Shiite naa kii ṣe ẹgbẹ to ba ofin mu lorilẹede Naijiria.
Gbogbo igbiyanju BBC lati ba awọn agbofinro ipinlẹ Kaduna sọrọ lori ẹseun yii ko tii bi eso rere bayii.












