Timothy Adegoke death case: Àwọn ẹbí Rahmon Adedoyin àti Timothy Adegoke ju òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn nílé ẹjọ́

Ebi Timothy Adegoke ati Adedoyin

Oríṣun àwòrán, Others

Ìgbẹ́jọ́ lórí ohun tó sọkùnfà ikú Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ oyè ìmọ̀ kejì ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo, Ile Ife, ìpínlẹ̀ Osun tó kú sí ilé ìtura Hilton ti bẹ̀rẹ̀ .

Ẹ ó rántí pé àjọ ọlọ́pàá ti wọ́ ẹni tó ni ilé ìtura Hilton náà, Dókítà Ramon Adedoyin àti àwọn mẹ́fà mìíràn lọ sí ilé ẹjọ́ gíga kan nílùú Abuja lórí ikú Timothy Adegoke tó kú sí ilé ìtura náà lọ́jọ́ kẹfà, oṣù kọkànlá, ọdún 2021.

Lára ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn Adedoyin ni sínsin òkú Adegoke lọ́nà àìtọ́, pípa ẹ̀rí ìwé owó tí Timothy Adegoke fi san owó rẹ́ àti yíyọ ẹ̀rọ ayàwòrán (CCTV) ilé ìtura náà rẹ́ lójúnà àti pa àwọn ohun tí kò bá jẹ́ ohun ẹ̀rí rẹ́.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke

Ẹ̀sùn ìpànìyàn, ìlẹ̀dí-àpòpọ̀, àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn ni wọ́n fi kan àwọn mẹ́fà tó kù.

Ki lo ṣẹlẹ lọjọ Ru?

Lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ ilé ẹjọ́ ní ọjọ́'Rú, Fọ́nrán kan ṣe àfihàn ibi tí àwọn mọ̀lẹ́bí méjéèjì tí ń sọ òkò ọ̀rs lu ara wọn.

Àkọlé fídíò, 'Ìgbà mẹẹ̀dógún ni mo ti ṣẹ́ oyún'

Àwọn ẹbí méjéèjì ń bú ara wọn pé wọ́n yóò kú.

Bẹẹ naa ni wọn n leri pẹlu itara si ara wọn

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ