Timothy Adegoke: Ètò tí n lọ láti mú ọmọ Adedoyin tí ìròyìn sọ pé ó darí bí wọ́n ṣe sin òkú Timothy ní Hilton Hotel

Adedoyin ati Ọga Ọlọpaa ipinlẹ Osun

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ẹ̀ka ileeṣẹ to n mojuto iwadii ẹ̀sùn ọdaran ti bẹ̀rẹ̀ igbesẹ lati fi panpẹ ofin gbe Raheem Adedoyin, ọmọ ẹni to ni ile itura Hilton Hotels and Resort, Ile-Ife, nibi ti Timothy Adegoke, akẹkọọ Fasiti OAU ku si.

Yatọ si eyi, ileeṣẹ ọlọpaa tun ti kọ esi ayẹwo oku naa nitori pe àwọn ẹbi oloogbe ko si nibẹ nigba ti wọn ṣe e.

Iroyin fìdí rẹ mulẹ fun BBC Yoruba pe ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti kọwe si ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ okeere, to fi mọ àjọ to n risi wọle-wọde, ati awọn àjọ miran, lori ọna ti ọwọ yoo gba tẹ Raheem.

Raheem Adedoyin ni alamojuto ile ìtura Hilton, oun si ni iroyin sọ pe o dari bi wọn ṣe sin oloogbe lai sọ fun ọlọpaa.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke: Màmá olóògbé ní ògó ilé àwọn ni wọ́n pa, ikú rẹ̀ kò gbọdọ̀ já sásán

Iwe iroyin Nigerian Tribune jabọ pe iroyin ní Raheem lo le sọ ipa ti baba rẹ ko ninu iku to pa Timothy, ati bi wọn ṣe sin oku rẹ.

Lati igba ti asiri ọrọ naa ti tu si ni Raheem ti salọ.

Iroyin naa tun sọ pe ijẹwọ àwọn afurasi ti ọwọ tẹ fihan pe o ṣe e ṣe ki ọlọpaa tun mu awọn eeyan kan to mọ nipa ìṣẹ̀lẹ̀ ọhun.

Ati pe ileeṣẹ ọlọpaa ti gba àṣẹ lati fi awọn afurasi si ahamọ titi iwadii yoo fi parí.

Lai pẹ si ni wọn o gbe wọn lọ sile ẹjọ́.

Ọjọ́ karun-un, oṣù Kọkanla ni Timothy Adegoke rinrinajo lati ilu Abuja lọ si Ile-Ife, lati ṣe idanwo ni Fasiti OAU. Ṣùgbọ́n o kú lẹyin to gba yara si ile ìtura Hilton.

Àkọlé fídíò, 'Ǹkan tí ẹ̀gbọ́n mi gangan ṣe fún mi ní Libya, mi ò kí ń lè sọ fún ìyá mi àmọ́ pllú omíjé kíkorò ...'

Àwọn kan gbìmọ̀ pọ̀ láti jí mi gbé lórí ọ̀rọ̀ àbúrò mi Timothy Adegoke tó kú sí ilé ìtura Hilton- Ẹ̀gbọ́n Timothy

Iku Timothy Adegoke

Awuyewuye si n lọ lori iku to pa akẹkọọ MBA fasiti OAU, Timothy Adegoke si ile itura Hilton to wa ni Ile Ife.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun tiẹ ti sọ pe ẹjọ naa ti de olu ile iṣẹ ọlọpaa niluu Abuja bayii.

Amọ, ohun ti a gbọ nipa ọrọ naa ni pe ẹgbọn Timothy, Olugbade Adegoke to n sa soke sa sodo lori ọrọ ọhun sọ pe awọn fẹ ji oun gbe salọ.

Àkọlé fídíò, 'Ǹkan tí ẹ̀gbọ́n mi gangan ṣe fún mi ní Libya, mi ò kí ń lè sọ fún ìyá mi àmọ́ pllú omíjé kíkorò ...'

Olugbade ni lootọọ ni wọn gbiyanju lati ji oun gbe lọ ṣugbọn awọn ẹṣọ Amotekun ati ọlọpaa daabo bo oun.

Olugbade ti kọkọ sọ tẹlẹ pe niṣe loun sa pamọ kaakiri ni Osogbo ati Ife nigbati iṣẹlẹ yii kọkọ ṣẹlẹ.

O fikun ọrọ rẹ pe Ọmọba Ramon Adedoyin to ni ile itura Hilton ran agbẹjọro rẹ si oun pe elo ni oun fẹ gba lati pa ẹnu mọ lori ọrọ naa.

Ṣugbọn oun sọ fun un idajọ ododo gbọdọ waye lori ọrọ naa.

Adedoyin n jẹjọ lọwọ lori iṣẹlẹ yii atawọn oṣiṣẹ ile itura rẹ nibi ti Timothy ku si.

Ẹgbọn Timothy Adegoke sọ tẹlẹ fun BBC Yoruba pe ni gbogbo igba ti awọn fi n wa aburo oun to wọ ọkọ baalu lọ si Akure lati Ife ni awọn to lọwọ ninu iku rẹ ko kọkọ fẹ jẹwọ afigba ti awọn tọpinpin.

O ṣalaye bi wọn ṣe kan si banki Timothy ti wọn si sọ fun wọn pe lootọ lo fi owo ranṣẹ si eeyan meji to si jẹ oṣiṣẹ hotẹẹli naa.

O ni oun mọ eeyan kan lara wọn, oun si ni wọn fun ogun mọ.

"O kọkọ ni lootọ ni ẹni yẹn wa, to si fi owo ranṣẹ amọ awọn ko tii rii ko wa si ile itura".

Igba ti wọn ko ṣẹkẹṣẹkẹ sii lọwọ lo to jẹwọ to tun darukọ gbogbo awọn to pa Adegoke ti wọn si lọ sin in.

Olugbade ṣalaye pe obinrin oṣoṣẹ kan to maa n fi ẹda fọto akọsilẹ to ba ṣe sori foonu ara rẹ ki wọn ma baa parọ mọ lo tu aṣiri to jẹwọ gbogbo ohun to ṣẹlẹ pe lootọ ni o Timothy wa sile itura awọn ti wọn si paa.