Security: Àwọn ọmọ ogun gba awọn ọlọ́pàá 20 ti awọn agbésùmọ̀mi jí gbé

Oríṣun àwòrán, Hq nigerian army/ facebook
Awọn ologun sọ pe awọn ọmọ ogun "Operati Hadin Kai" ti gba awọn oṣiṣẹ ọlọ́pàá Nàìjíríà ogún ti awọn afurasi on agbesùmọ̀mí jí gbé. Ileeṣẹ ologun náà fikùn pé wọn ji awọn ọlọ́pàá náà nígbà tí àwọn agbesùmọ̀mí kọlu agọ ọlọ́pàá kan ni Buni Yadi ìpínlẹ̀ Yobe.Adelé Olùdarí ilé iṣẹ́ ọmọ ogun,lórí igbohun safẹfẹ, ọgagun Bernard Onyeuko, ṣe afihan eyi ni Ọjọbọ lásìkò tó ń ṣàlàyé lórí ibi tí wọ́n bá ń iṣẹ́ lori awọn iṣẹ ti awọn ọmọ ogun láàrin ọjọ́ karùn-ún lélógún Oṣù
kọkanla àti ọjọ́ kẹsàn-án Oṣù Kejìlá.
- Ilé ẹjọ́ ti pàṣẹ tuntun fún ọ̀ga ọlọ́pàá Nàìjíríà lórí Rahmon Adedoyin tí Timothy Adegoke kú sí ilé ìtura rẹ̀
- Sunday Ìgbòho Yóò Padà Sílé Láyọ̀ àti Àlááfíà- Akeredolu
- Wo ìdí tí Sanwo-Olu ṣe wọ́gilé ìrìn àláàfíà 'Walk for Peace' tó fẹ́ẹ̀ rìn pẹ̀lú àwọn ará Eko
- Fadeyi Oloro wà ní ìdúbúlẹ̀ àìsàn, ẹ jọ́wọ́ ẹ rànwá lọ́wọ́ - Foluke Daramola
- 2022 Hajj: Saudi fòfin de ìrìn-àjò bàálù láti Nàìjíríà torí ẹ̀dà covid-19 Omicron
Ó tún sọ pé àpapọ̀ àwọn ágbesùnmọ̀mí mejilelọ̀gọta ni awony ti pa, tí wọ́n sì ti mú mejidinlọ́gbọ̀n bákan náà ní wọn gba àwọn ohun ìjà mẹ́rinlelaadọọta ati àwọn èròjà olóró 144 tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn
agbésùmọ̀mi naa.O sọ pe, "Ni apapọ, àwọn agbésùmọ̀mi mejilelọ́gọ́ta ni a gba agbára lọ́wọ́ wọn didoju ati pe mejidinlọ́gbọ̀n ninu wọn ni a mu, Àpapọ̀ awọn ẹran-ọsin tó le ni ọgọ́rùn-ún ni a gba à sì tún gba àwọn ọlọ́pàá ogún
ti wọ́n ji gbe, lásìkò tí àwọn agbésùmọ̀mi ji gbe nígbà tí wọ́n ṣe ìkọlù sí àgọ́ ọlọ́pàá kan nìjọba ìbílẹ̀ Buni Yadi."
Onyeuko tún ṣalaye pé ó kéré tán àwọn ajinigbe pawó ni awọn ọmọ ogun " Operation Thunder Strike" pa.Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ , ogbọ̀n nínú wọn ni wọ́n pa nítòsí ibudó agùnbánirọ̀ ni ìpínlẹ̀ Kaduna.O sọ pe, "Ni ọjọ kẹta Oṣu Kejìlá ọdun 2021, lẹ́yìn ìfìmúfilẹ̀ ati ìwádìí kíkún ní a rídi ìgbòkègbodò àwọn ajínigbé pawó ni ìhà ni ìlà-oòrùn Rijana ni òpópónà márosẹ̀ Abuja si Kaduna.









