Covid-19 Omicron variant: Saudi Arabia fòfin dè ìrìn-àjò láti Nàìjíríà torí ẹ̀dà tuntun coronavirus

Saudi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹ ede Saudi Arabia naa ti fofin de irin-ajo baalu lati orilẹ-ede Naijiria lẹyin ti ẹda coronavirus Omicron ṣẹyọ ni orilẹ-ede naa.

Ajọ to n ri Irinajo ọkọ ofurufu lorilẹ ede Saudi Arabia, GACA lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita ni Ọjọru.

Orilẹ ede Saudi kede igbesẹ yii lẹyin ọsẹ kan ti wọn ri arinrinajo kan lati apa ariwa ilẹ Afirika to ni ẹda Omicron arun coronavirus nilẹ naa.

Ajọ GACA ṣalaye ninu atẹjade naa pe awọn ọmọ Naijiria ti wọn ba ti lo ọjọ mẹrinla ni orilẹ ede mii lo le ni anfani lati wọlé sí Saudi.

Awọn ọmọ Saudi to ba n bọ lati Naijiria gbọdọ lo ọjọ marun un lai jade, wọn si gbọdọ fi iwe ẹri to ṣafihan pe ko si covid-19 lara wọn lẹyin ti ọjọ marun un ba ti pe tan.

Àkọlé fídíò, KieKie

Ijọba Saudi ni ẹnikẹni to ba tapa si alakalẹ yii yoo foju wina ofin.

Ẹwẹ, ajọ NAHCON to n ri si ọrọ irinajo Hajj si Saudi ti sọ oun ko tii gba iwe kankan lati naa lori ikede ti ajọ GACA ṣe nipa irinajo si Saudi.

Àkọlé fídíò, FUTA First Class Twins

Laisi àní ani, igbesẹ Saudi Arabia to fofin de irin-ajo baalu lati Naijiria si ilẹ naa yoo ṣakoba fun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ Naijiria ti wọn ti gbaradi lati lọ fun Umrah (lesser Hajj) papaa julọ awọn to ti sanwo.

Laipẹ yii orile-ede UK fofin de irin-ajo baalu lati Naijiria tori ẹda Coronavirus Omicron to ṣẹṣẹ bẹ silẹ kaakiri agbaye.

Àkọlé fídíò, Mama Deeper Life Ondo

Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ eleto ilera lagbaaye, WHO, Omicron ti de orilẹ ede mẹtadinlọgọta bayii.

Ajọ WHO iye awọn eeyan ti yoo dero ile iwosan yoo tun pọ si laipẹ nitori Omicron.