Gobirawa: Àwọn èèyàn kan ní Sokoto àti Zamfara ní àwọn agbésùmọ́mí ti gbàjọba lágbègbè wọn

Oríṣun àwòrán, HQ Nigerian Army
Awọn eeyan agbegbe Gobir ni ipinlẹ Sokoto ati Zamfara ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari lati fopin si ipaniyan lemọlemọ to n waye lagbegbe wọn.
Ninu lẹtya kan ti wọn kọ ranṣẹ si Aarẹ ni wọn ti sọ bẹẹ.
Awọn eeyan naa, labẹ asia ẹgbẹ Gobirawa Community Development Organization, sọpe ipaniyan ojojumọ ti sun awọn, awọn si n fẹ ki ijọba apapọ wa ojutu si ọrọ naa.
- 2022 Hajj: Saudi fòfin de ìrìn-àjò bàálù láti Nàìjíríà torí ẹ̀dà covid-19 Omicron
- Fadeyi Oloro wà ní ìdúbúlẹ̀ àìsàn, ẹ jọ́wọ́ ẹ rànwá lọ́wọ́ - Foluke Daramola
- Ìlú Eko yóò gbàlejò Àarẹ Muhammadu Buhari lónìí
- Gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú Sylvester Oromoni kò ní lọ láì jìyà lábẹ́ òfin - Buhari
- Ẹ̀jọ́ àtí ìwádìí ikú Timothy Adegoke ti kúró lọ́dọ̀ọ wa nípinlẹ̀ Osun- Agbẹnusọ Ọlọ́pàá Oṣun
- Mọ̀ síi nípa abẹ́rẹ́ àjẹsara tó jẹ́ dandan: Wo ìdí mẹ́ta tí àwọn kan ṣe nífẹ̀ síi àti ìdí mẹ́ta tí àwọn ẹlòmíì kò ṣe gbà á
Wọn ni asiko to wu awọn janduku naa ni wọn n ṣakọlu si agbegbe awọn lati pa eeyan bii ẹni pa ẹran, ti wọn si n fi ipa mu awọn san owo ori.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ ninu lẹta naa, awọn janduku ọhun n ṣe bii ijọba le awọn lori nitori bi wọn ṣe n yọ awọn olori ti awọn yan bi ẹni yọ jiga lati fi ẹni to ba wu won sori irufẹ aga bẹẹ.
Wọn fi kun pe iwọnba ẹṣọ alaabo perete lo wa lagbebe wọn eyii to jẹ ki aye ga awọn agbebọn lati ṣe bo ṣe wu wọn.
Olori awọn eeyan ọhun, Alhaji Ibrahim Alhasan sọ fun BBC pe ọrọ naa ti kọja oju ẹ.
O ni "Kii ṣe ijọba lo n ṣakoso agbegbe wa mọ, awọn agbesumọmi lo n ṣakoso rẹ."
"Awọn agbesumọmi lo n yan awọn adari fun wa, a ko le ṣe ohunkohun lai ṣe pe wọn mọ si ṣaaju."
Alhasan ṣalaye siwaju si pe olori awọn agbesumọmi naa ni Bello Turji, okunrin ọhun a si maa ya gbogbo agbegbe wọn lẹyọ kọọkan.
"O maa n gba owo ori, a si maa pa eeyan bo ba ṣe wu ti nnkankan ko si ni ti ẹyin rẹ jade."
O pari ọrọ rẹ pe kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn yoo kọ lẹta si Aarẹ lori eto abo to mẹhẹ lagbegbe awọn.
- Ìgbésẹ̀ láti dínà arìnrìnàjò ọmọ Nàìjíríà sí UK yóò da ètò rú fáwọn tó fẹ́ bá ẹbí wọn ṣe Kérésìmesì ní UK
- Ṣé lóòtọ́ ni ajínigbé sọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjí di iṣu ní Ibadan?
- Báwo ni àwọn ọmọ méje ṣe di òkú sínú ọ̀kọ̀ àyọkẹ́lẹ̀ kan ní Badagry
- Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tí ọmọ mi, Sylvester Oromoni sọ fún wa nìyí nínú ìrọra kí ó tó kú, òní ni ọjọ́ ìbí rẹ̀!
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn òbí ọmọ ọdún 15 tó yìnbọn pa èèyàn mẹ́rin nílé ẹ̀kọ́
















