Michigan school shooting: Ọlọ́pàá fi ṣìkún òfin mú àwọn òbí ọmọ tó yìnbọn pa èèyàn mẹ́rin nílé ẹ̀kọ́

James and Jennifer Crumbley

Oríṣun àwòrán, USmarshalsHQ

Awọn obi ọmọ to yinbọn pa eeyan mẹrin nile ẹkọ kan nilẹ Amẹrika, Ethan Crumbley, ti wa ni gbaga ọlọpaa bayii niluu Detroit, lẹyin ti wọn ti kọkọ gbiyanju lati fẹsẹ fẹ.

James ati Jennifer Crunbley kọ lati yọju sile ẹjọ lọjọ Ẹti lẹyin ti wọn fẹsun ipaniyan aimọ kan wọn.

Wọn fẹsun kan awọn tọkọ-taya naa pe wọn ko kọbi ara si awọn iwa ti ọmọ wọn n wu ṣaaju iṣẹlẹ ọhun, eyii to lew tọka si iwa ipa to lwe wu.

Awọn ọlọpaa fi ṣikun ofin mu awọn obi ọmọ naa lẹyin ti awọn agbofinro ri ọkọ wọn laarin ilu.

Awọn agbofinro lati ilu Detroit atawọn agbofinro ijọba apapọ ri awọn obi afurasi naa lẹyin ti wọn wa agbegbe kan finifini niluu Detroit lẹyin ti wọn ti kọkọ kede $10,000 ẹbun owo fun ẹnikẹni to ba le ṣamọna bi ọwọ yoo ṣe tẹ wọn ṣaaju.

Ẹwẹ, agbẹjọro afurasi naa sọ fun BBC pe kii ṣe pe awọn obi rẹ mọọmọ fẹsẹ fẹ, ṣugbọn wọn fi ilu silẹ fun abo ara wọn lẹyin ti ọmọ wọn ṣe aṣemaṣe tan.

Afurasi naa, to jẹ ọmọ ọdun marundinlogun yinbọn lu awọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ ni ipinlẹ Michigan.

Àkọlé fídíò, Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí

Iroyin ni o dana ibọn ya awọn akẹgbẹ rẹ, to fi mọ awọn olukọ rẹ lọjọ Iṣẹgun, ṣugbọn o ti sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Awọn mẹrin to ba iṣleẹ naa lọ ni Tate Myre, Madisyn Baldwin, Hana St Juliana, ati Justin Shilling ti ọjọ ori gbogbo wọn wa laarin ọdun mẹrinla si mẹtadinlogun, nigba ti awọn meje mii farapa nibi iṣẹlẹ ọhun.

Ijọba ilẹ Amẹrika n ṣe ẹjọ ọdọkunrin naa gẹgẹ bii ẹjọ agbalagba, wọn si fi ẹsun mẹrinlelogun kan an, eyii to rọ mọ lilo ibọn lai gba aṣẹ, ẹsun igbesunmọmi, ẹsun ipaniyan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò, Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀