Wife set husband's mistress ablaze: Ìyàwó tó dáná sun àlè ọkọ rẹ̀ kó sí gbaga Ọlapàá nípinlẹ̀ Ogun

Iyawo ile ẹni ọdun mejilelọgbọn kan to tun jẹ iya ọlọmọ mẹta, Kehinde Abdulwasiu ti bọ si ọwọ Ọlọpaa ipinlẹ Ogun tori ẹsun pe o da epo bẹntiroo si ale ọkọ, Tosin Olugbade jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun lara to si da ina sun un.
Iroyin ni ọwọ tẹ afurasi ọhun nigba ti awọn ọlọpaa tẹ́wọ́ gba ifẹsun kan ni agọ ọlọpaa Onipanu latọdọ ọkọ oloogbe naa to fẹjọ sun ni ọjọ kejilelogun oṣu kọkanla pe ni inu oṣu kẹjọ, oun fi ẹsun kan iyawo oun pe o n ni ibaṣepọ pẹlu ẹlomiran, Ismail Wasiu nita.
O ni si iyalẹnu oun, ṣe ni iyawo rẹ ko ẹru rẹ jade nile to si ko lọ si ile Ismail Wasiu, ale rẹ.
O fi kun un wipe lọjọ Kẹrinla oṣu kọkanla ọdun 2021, oun gbọ pe iyawo Ismail Wasiu ni ija pẹlu iyawo rẹ ti iyawo si da epo bẹntiro si iyawo toun to jẹ ale ọkọ tirẹ lara to si kan ina sii lara.
Awọn ẹbi arabinrin naa ti gbe e lọ si ile iwosan amọ taa gbọ pe o pada ku lasiko to n gba itọju lọwọ.
Ẹwẹ nigbati ti wọn gbọ iroyin naa, igbakeji Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CSP Bamidele Job ko awọn oṣiṣẹ rẹ jọ wọn si lọ sibi iṣẹlẹ naa nibi ti ọkọ Kehinde to ti ni ki iyawo rẹ sa lọ ti ko sọwọ wọn.
Lẹyin eyi ni wọn gbe ẹjọ naa lọ si ẹka iwadii ipaniyan ni ipinlẹ naa fun iwadii to jinlẹ.
Ọga ọlọpaa to dari igbimọ aṣewadii ọlọgbọn yii, Femi Olabode fi esi jade to si ti mu ki wọn fi ofin afurasi naa, Kehinde Wasiu ni agbegbe Saki, ipinlẹ Oyo.
Nigba ti wọn fi ọrọ wa a lẹnu wo, afurasi ọhun jẹwọ fun ileeṣẹ ọlọpaa pe lootọ loun ṣe bẹẹ amọ o sọ pe oun ko mọ nkan to ba le oun lọjọ naa.
Iwadii abẹlẹ to ti waye fihan pe afurasi naa ati ọkọ rẹ jọ parọ fun mọlẹbi arabinrin naa pe afẹfẹ gaasi ti wn fi n dana lo bugbamu to si jo oloogbe naa. Ṣugbọn nigba ti aṣiri tu ni ọkọ ni ki iyawo rẹ tete sa asala fun ẹmi rẹ.
Kọmisọna ọlpaa, CP Lanre Bankole ti paṣẹ pe ki wọn jara mọ iwadii wọn ki wọn si tete gbe ẹjọ wọn lọ siwaju ile ẹjọ kia kia.















