Sylvester Oromoni Death: Ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró rèé lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College tí wọ́n fẹ̀sùn kan akẹgbẹ́ rẹ̀ pé wọ́n lù ú pa.

Dowen College student death: Sylvester Oromoni death video

Oríṣun àwòrán, Perrie/Twitter

Ileese olopaa nipinlẹ Eko ti ṣalaye ibi ti ọrọ de duro lori iṣẹlẹ iku akẹkọkunrin, Sylvester Oromoni ti ileẹkọ Dowen College ni ipinlẹ Eko.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC ni kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ti sọ igbeṣẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa n gbe lori iṣẹlẹ naa

Ninu ọrọ rẹ, ọga ọlọpaa Odumosu ni awọn ti bẹrẹ iwadii pẹrẹwu lori iṣẹlẹ naa ti awọn ko si ni fi akoko ṣofo.

Odumosu ni awọn ti n gbe igbeṣẹ lori gbogbo awọn to ni ọwọ lori iṣẹlẹ iku ọmọ ọdun mejila naa to waye ni ileẹkọ Dowen College, Lekki.

Eleyii ko ṣẹyin bi ijọba ipinlẹ Eko ṣe ti ileẹkọ naa pa nitori iṣẹlẹ iku ọmọ naa.

Baba Sylvester ni ọmọ oun sọ fun oun ko to ku pe awọn akẹgbẹ ohun lu oun nitori oun kọ lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun.

Sylvester Oromoni

Oríṣun àwòrán, Perreri/Twitter

Lẹyin ti ileewe sọ wi pe bọọlu ni ọmọ naa n gba to fi farapa.

Baba ọmọ naa sọ pe ọmọ rẹ ni awọn ọmọkunrin marun un kan lo wọ inu iyara rẹ, ti wọn si bẹ́rẹ si ni lu nitori pe ko bawọn ṣe ẹgbẹ okunkun.

Arakunrin Sylvester Onoromi Snr ni eleyi kii ṣe igba akọkọ ti wọn yoo dẹyẹ si ọmọ oun ati pe awọn ti fẹjọ sun alaṣẹ ile ẹkọ naa lọpọ igba.

Amọ, Ileeṣẹ ọlọpaa ni wẹrẹ ti awọn ba ti pari iwadii iṣẹlẹ naa, ni awọn yoo fi panpẹ ọba mu gbogbo awọn ti ade ọrọ naa ṣi mọ lori.

Ọga ọlọpaa Odumosu ni to fi mọ gbogbo awọn ti ọmọ naa fi ẹsun kan pe wọn na oun ni awọn yoo fi panpẹ ọba mu.