RCCG Dating Site: Wo àwọn òfin tí ìjọ Redeem gbé kalẹ̀ kàwọn ọ̀dọ́ tó wọ ojú òpó olólùfẹ́

Oríṣun àwòrán, Others
Ile ijọsin Redeem Christian Church of God (RCCG), ẹka City of David to wa ni agbegbe Victoria Island ni ipinlẹ Eko, ti gbe oju opo ololufẹ kan kalẹ̀ si ori ayelujara.
Ninu akọle ti ile ijọsin naa fi si oju opo Facebook rẹ lo ti kede pe "ko si igbeyawo ni ọrun'' lẹyin ọjọ diẹ ti oju opo naa bọ si ori ayelujara.
Bakan naa ni wọn kọ si oju opo naa pe awọn woye pe awọn eniyan yoo pade egungun iha wọn ni oju opo naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo àwọn ìdí tí Adájọ́ fi dá Wòlìí Sotitobire láre, tó sì da ẹ̀wọ̀n gbére nù
- Àwọn ọ̀dọ́ Eruwa ṣe ìwọ́de lórí ikú Timothy Adegoke tó kú sílé ìtura ní Ife
- Wo orílẹ̀èdè tí ẹ̀dà Covid-19 tuntun Omicron rápálá wọ̀ l‘Áfíríkà
- Èsì iléẹ̀kọ́ Dowen rèé sí ìkú akẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn òbí rẹ̀ ní àwọn ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn pa nítorí kò darapọ̀ mọ́ wọn!
- N kò fara mọ́ ẹ̀rí Princess, ẹ yọ́ dànú torí kò bá òfin mu - Baba Ijesha yarí nílé ẹjọ́
- Òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ ló sin Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ OAU tó kú sílé ìtura - Agbẹjọ́rò
- “Màá ṣúgbàá gbígba ₦25m ẹ̀tọ́ Baba Suwe lọ́dọ̀ NDLEA lẹ́yìn ikú rẹ̀”
- Abubakar Malami kéde àwọn agbébọn bíi agbésùnmọ̀mí lẹ́yìn ò rẹyìn
Abẹwo si oju opo naa fihan pe o wa fun awọn ọdọlangba to n wa afẹsọna, ti wọn si n fi oju sọna fun igbeyawo.
Awọn ti o ba si fẹ darapọ mọ oju opo naa gbọdọ fi orukọ wọn silẹ, ti wọn yoo si ṣayẹwo wọn ki wọn to gba wọn wọle.
Amọ wọn fi ikilọ si oju opo naa pe ẹnikẹni ko ni san owo kankan lati darapọ mọ oju opo ọhun.
Ninu atẹjade to wa ni oju ọpọ naa ni wọn ti parọwa si awọn ti wọn fẹ darapọ mọ oju opo naa lati farabalẹ ṣe iwadii ẹnikẹni to ba kọ ẹnu ifẹ si wọn.
''Ijọ Christian Church of God (RCCG), the City of David ko fi ẹnikẹni ṣe oniduro ẹnikẹni to ba sọ ọrọ ifẹ si ọ, ti wọn ba si lu ọ ni jibiti ko si ọwọ ijọ naa nibẹ nitori o darapọ mọ oju opo naa.''
Bakan naa ninu fidio ti pasitọ ijọ naa, Idowu Iluyomade fi sita, ni o ti sọrọ nipa oju opo naa ati iru awọn eniyan to wa nibẹ.
''Oriṣirisi eniyan lo wa ni oju opo naa, lati ẹni ogun ọdun, de ọ̀dun marundinlọgbọn to fi de ẹni ọdun marundinlaadọrin.''

Oríṣun àwòrán, Others
Bakan naa ni wọn fikun un pe oju opo naa ti n gbe igbesẹ lati bẹrẹ eto idanilẹkọ fun awọn to ba darapọ mọ oju opo naa, lọna ati kọ wọn nipa awọn ohun ti eniyan le ṣe lati ni igbeyawo to wuyi ni awujọ.



















