Male contraception: Wo ọ̀ná tí àwọn ọkùnrin lè gbà ṣe ìfètòsọ́mọbíbí láì lo kọ́ndọ́ọ̀mù

Oríṣun àwòrán, SIMON MAINA
Ṣe o mọ pe bi ọkunrin ko ba fẹ ki ololufẹ rẹ loyun, awọn naa n gba ọna ifetosọmọbibi?
Oniruuru ọna lo wa fu awọn okunrin lati ṣe ifetosọmọbibi lai lo rọba idaabobo.
Pupọ lọkọ-laya tabi ololufẹ ni wọn n ba ere ifẹ lọ ṣugbọn ti wọn ko tii ṣetan lati bi ọmọ, fun irufẹ awọn ololufẹ tabi tọkọ-taya bẹẹ, oniruru ọna ni wọn le gba lati dena ọmọ bibi.
Lara awọn ọna to gbajumọ julọ ni kọndọọmu lilo wa.
Ohun to yẹ ki o mọ nipa kọndọọmu okunrin
Kọndọọmu jẹ ọna kan gboogi ti awọn okunrin fi dena oyun nini nilẹ Afrika.
Ti okunrin ba lo kọndọọmu naa daadaa, o lle dena oyun ni nnkan bi ida mejidinlọgọrun, bakan naa ni o le dena awọn arun ibalopọ.
Ti o ba fẹ lo kọndọọmu lati dena oyun, o gbọdọ lo rọba naa daadaa. Ohun akọkọ ni ki o yẹ ọjọ ori rẹ wo lati ri daju pe ko tii pari iṣẹ, ati pe ko ni iho kankan lara.
Okunrin tun gbọdọ lo kọndọọmu "latex," to jẹ eyii ti ajọ eto ilera agbaye, WHO ati ajọ UNFPA buwọlu.
Bi kọndọọmu ṣe wa fun awọn okunrin naa lo wa fun awọn obinrin.
Yiyọ nnkan ọmọkunrin ki atọ to jade
Ẹyii tun jẹ ọna kan pataki ti okunrin ti ko ba fẹran kọndọọmu lilo lati dena oyun, amọ kii ṣe ọna to muna doko daadaa.
Gẹgẹ bii ohun ti WHO sọ, ọna yii le kuna pẹlu ida mẹtadinlọgbọn.
Ọna yii ti awọn ọni Gẹẹsi n pe ni "Withdral method" tumọ si pe okunrin naa yoo yọ nnkan ọmọkunrin lasiko ibalopọ ki atọ rẹ to jade.
Ṣugbọn WHO ni eredi ti ọna naa ko ṣe munadoko ni pe o ṣeeṣe ki atọ ọmọkunrin jade ko to da, eyii to le yọri si oyun airotẹlẹ.
Vasectomy
Ọna mii ti awọn okunrin fi le dena oyun ni eyii ti wọn n pe ni "Vasectomy."
Awọn onimọ nipa ifetosọmọbibi maa n ṣe Vasectomy nipa lila abẹ koropọn okunrin, ti wọn a si di ọna ti atọ maa n gba lọ sinu nnkan ọmọkunrin lati inu koropọn.

Oríṣun àwòrán, Jonathan Torgovnik
Ṣiṣe eyii ko sọ pe irufẹ okunrin bẹẹ ko ni le ṣe bii okunrin lọdọ aya tabi ololufẹ rẹ mọ, ṣugbọn irufẹ okunrin bẹẹ ko ni le fun obinrin loyun.
Ki wọn to ṣe Vasectomy fun okunrin, wọn maa n kokọ fun okunrin bẹẹ ni abẹrẹ ti ko ni jẹ ki iṣẹ abẹ naa dun rara bo tilẹ jẹ pe ko ni sun, iṣẹ abẹ ọhun kii ṣi ju iṣeju marundinlogun pere lọ.
Pipa atọ ọmọkunrin pẹlu ooru
Awọn onimọ ijinlẹ tun ti ṣawari ọna mii lati dena bi okunrin ṣe le fun obinrin loyun.
Ọna yii jẹ eyii ti awọn onimọ iṣegun fi maa n pa atọ ọmọkunri pẹlu ooru fun nnkan bii oṣu mẹta.
Bi wọn ṣe maa n ṣe ni pe okunrin naa yoo maa wọ awọtẹlẹ ti yoo mu ki oorun maa mu nnkan ọmọkunrin rẹ fun wakati marundinlogun loojọ fun oṣu mẹta gbako.
Awọn onimọ sọ pe ọna yii ṣiṣẹ daadaa bi wọn ṣe lero pe yoo ṣiṣẹ ṣugbọn iwadii naa ṣi n lọ lọwọ.
Pipa atọ pẹlu afẹfẹ lati inu imu
Awọn onimọ sayẹnsi kan lati ilẹ Gẹẹṣi bẹrẹ iwadii kan lọdun 2016 nipa afẹfẹ ti eeyan le fi sinu iho imu, eyii ti yoo pa ẹyin inu atọ ku patapata.
Awọn onimọ naa ni Ọjọgbọn John Howl ati Ọmọwe Sarah Jones lati fasiti Wolverhampton.
Ẹwẹ, iwadii naa ṣi n lọ lọwọ.
Ki ni awọn ẹlẹsin sọ?
Awọn adari ẹlẹsin kan ti sọ pe awọn ọna naa yii ko buru ṣugbọn wọn lodi si agbekalẹ Ọlọrun ẹlẹdaa.
Alufaa Alfred Saee ni Senegel sọ pe awọn ko faramọ awọn ọna kan ti awọn onimọ sayẹnsi n gba lati maa dena oyun, paapaa fun awọn okunrin.
Alfred ni ibukun Ọlọrun ni ọmọ bibi jẹ, ko si yẹ ki awọn okunrin maa lo oogun kankan tabi ṣiṣẹ abẹ lati dena ibukunn Ọlọrun ninu aye wọn.
















