2023 Presidential Election: Mí o búwọlu ìdupo ààrẹ ọdún 2023 fún Tinubu-Foluke Daramola

Mí ò polongo ìdupo ààrẹ ọdún 2023 fún Tinubu-Foluke Daramola

Oríṣun àwòrán, Foluke daramola/instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajúgbajà òṣèré Nollywood Foluke Daramola Salako ni òun kò buwọ́lu ìyànsípò ààrẹ ẹnikẹni ní ìgbà kan kan sùgbọ́n oo

Ó ni nǹkan tí àwọn ènìyàn rí lórí ayé líujara kò ni nńkan ṣe pẹ̀lú bí àwọn ènìyàn ṣe ń bu ẹnu àtẹ́ lu òu ti ọ̀ps sì ń naka àlébù.

Ó ní nǹkan ti àwọn ti àwọn ń ṣe kò nííse pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Nollywood, bí kò ṣe ẹgbẹ́ àwọn tó n pè fún àláfía àti ìrẹ́pọ̀ Nàìjíríà ni, kò ní ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òṣèlú

Foluke ni àwọn kò lọ síbẹ̀ láti lọ buwọ́lu lílọ fún ìpò ààrẹ Asiwaju Ahmed Bola Tinubu ni ọdún 2023.

Gbájúgbàjà òṣèré náà ni kò sí ẹni tí ó san owó fún òhun fún òhún kóhùn, ìpídé bi àláfíà àti ìrẹ́pọ̀ yóò ṣe wà ni Nàìjíríà ni àwọn ń se

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Kí ni ó fa ìdfí abájọ?

Foluke Daramola, àti oṣèré Nollywood miiran ti wọ́n ń pè ni Mr Ibu ni ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíría ti bu ẹnu àtẹ́ lù pé wọ́n ń lu ilù máa jó lọ mo n wo ẹ̀yin rẹ fun Asiwaju ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Bola Ahmed Tinubu nípa ìpinu rẹ̀ láti du ipò ààrẹ Nàìjíríà lọ́dún 2023.

Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé Tinubu kò ti kéde fún ra rẹ̀ pé òun yóò du ipò ààrẹ lọ́dún 2023, sìbẹ́ ọ̀pọ̀ àwọn alátẹ̀lé rẹ̀ ló ti n ṣe ìpolongo fun.

Nínú fọ́ràn náà tó jẹyọ lórí ayélujára ni à ti ri àwọn ènìyàn kan nínú gbọ̀gán kan ti tábìlì yípo, ti ẹnikan náro tó si n fi orúkọ Tinubu kọrin báyi pé Tinubu ooo...

Èyí lo fa ìrunú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ti wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ni bú Folukẹ Daramola àti Mr Ibu pé wọ́n ti dalẹ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ati pé wọ́n fẹ́ràn láti máá du àpò wọn ju rírò nípa àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ àti ọjọ́ iwájú wọn.