Nigeria civil servant December salary: Irọ́ ni ìròyìn tó sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ kò níì tètè rí owó oṣù Kejìlá gbà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olori awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ Naijiria ti fesi si iroyin kan to n lọ pe o ṣeesẹ ki awọn oṣiṣẹ ma tete ri owo oṣu Kejila gba.
Ọjọbọ ni iroyin jade pe ileeṣẹ to n mojuto ọrọ awsn oṣiṣẹ fi ikilọ sita pe ki awọn oṣiṣẹ ma na owo oṣu wọn Kọkanla ni inakuna, nitori pe o ṣeeṣe ki owo oṣu Kejila pẹ.
Oludari ẹka ibanisọrọ nibẹ, AbdulGaniyu Aminu sọ ninu atẹjade kan pe ayederu iroyin ni ikede naa.
O ṣalaye pe ẹni to fi ọwọ si atẹjade to n lọ lori ayelujara, Dokita S.A Adegoke, kii ṣe oṣiṣẹ ọfiisi Olori oṣiṣẹ, bẹẹ ni ko si akọsilẹ kankan nipa rẹ pe o ṣiṣẹ nibẹ ri.
Aminu sọ pe ọfiisi to n mojuto ọrọ awọn oṣisẹ yoo tẹsiwaju lati ma a mojuto irọrun awọn oṣiṣẹ.
"Rọra ná wó oṣù kọkanlá rẹ pẹ̀lú ọgbọ́n nitorí pé ó ṣeẹṣe kò má sí owó oṣù títí di oṣù kíní ọdún tó ń bọ̀ "
Ó jọ pé nǹkan le má sẹ́nu Ire fún àwọn ọlọ́pàá àwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ ijoba àpapọ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kọ̀ọ̀kan lásìkò keresimesi tó ń bọ yìí.
Eyi ko ṣẹyin bi ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe gba wọn nimọran lati na owo oṣù tí wọ́n gba nínú oṣu kọkànlá pẹlu ọgbọn nitori pe owo oṣù Kejìlá wọn le ma wọle titi di oṣù kini ọdún 2022.
Nínú àtẹ̀jáde ijabọ kan lo tí jẹyọ pe ayẹyẹ Kérésìmesì awọn oṣiṣẹ kan ni Nàìjíríà kò ní sẹ́nu re bí owo oṣù kọkanlá gan kò ṣe wọlé lásìkò tó yẹ.
- Àwọn akọrin ìjọ tó fẹ́ lọ ṣe ìgbéyàwó kàgbákò òjò àrọ̀rọ̀dá, ẹ̀mí 23 sọnù...
- Ẹ̀ wo bàbá àgbàlagbà tó lo ayédèrú apá nitorí kò fẹ́ gba abẹrẹ́ àjẹsára Covid-19
- Wó ìgbésẹ̀ táwọn ọlọ́pàá gbé níwájú iléẹ̀kọ́ Dowen College tí Sylvester Oromoni tó kú lọ
- "Àwọn agbésùmọ́mí ló ń ṣe ìjọba lé wa lórí, kìí ṣe ìjọba Nàìjíríà tí Buhari ń darí"
- Ilé ẹjọ́ ti pàṣẹ tuntun fún ọ̀ga ọlọ́pàá Nàìjíríà lórí Rahmon Adedoyin tí Timothy Adegoke kú sí ilé ìtura rẹ̀
"Èyí wáyé nítorí bí wọ́n ètò ìsúná ìjọba ṣe ń yingin lojoojumọ ni ó fi dá bí ẹni pé awọ kò ka ojú ìlù mọ́ èyí sì lo n ṣàkóbá fún àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀ka ìjọba tí wọ́n kò tètè rí owó oṣù gbà.
Àwọn aláṣẹ ni ilé iṣẹ́ ìjọba ni ni ìbànújẹ́ ọkàn ló jẹ́ ṣùgbọ́n àwọn n woye pé owó oṣù Kejìlá lè má tètè wọlé títí di oṣù kini ọdún.
Eyí wá nínú àtẹ̀jáde tí ilé olórí eto owó nílé ìwòsàn FMC Keffi Samson Adegoke fọwọ́ sí ní ọjọ́ karundunlọgbọ̀n oṣù kọkanlá, ọdún yii

Oríṣun àwòrán, others
Ọgbẹni Adegoke, lásìkò to n sọ̀rọ̀ idaniloju fún awọn oṣiṣẹ ijọba ati awọn olori ẹka ilé iṣẹ́ náà pé awọn ń gbìyànjú láti rí dájú pé FMC kò rí idiwọ yii ni ṣùgbọ́n ó kilọ kí wọn sọ èyí tí wọn gba nínú oṣù kọkanlá ná pàápàá julọ lásìkò ọdún tó wọlé dé yìí.
"Bákan náà , ó gba gbogbo oṣiṣẹ niyanju lati ṣọra bí wọn ṣe lo owo-oṣu Oṣu kọkanla ọdun 2021 ati lati ṣe awọn ipese fun awọn ayẹyẹ Keresimesi lati ibẹ, "àtẹ̀jáde naa gba wọn niyanju.
Bakan naa, ọga àjọ ọlọ́pàá , Alkali Usman, ninu ọ̀rọ̀ tó fi ransẹ́ si gbogbo ẹka ọlọ́pàá, lo ti sọ fun gbogbo awọn ẹka ati awọn kọmisanna ọlọpa kaakiri orilẹ-ede Naijiria pé idaduro díẹ̀ wáyé nínú owó oṣu Kọkànlá wọn.
"Ó ní àlàyé tí oun gba lati ọdọ awọn oṣiṣẹ tó ń ṣètò owó oṣù IPPS tí apakan ọfiisi ọga àgbà iṣiro owó gbogbogbo fún ìjọba àpapọ̀ lo tọkasi idaduro nípa owo osu owo eyiti o tumọ si pe idaduro yoo wa nínú sisanwo ti Oṣu kọkanla, "Ọgbẹni Usman sọ ninu ọrọ tó fi ransẹ́ naa ni nka tí be aago méjì ku díẹ̀ lọ́jọ́ kẹta oṣù Kejìlá.
Síbẹ̀ síbẹ̀, ọ̀gá ọlọ́pàá náà gbóríyìn fún àwọn ìrúbọ àti ìfaraji wọn fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá , ó sì fi dá wọn lójú pé kò ní pẹ́ kí owó wọn tó yọjú
O tun paṣẹ pe ki gbogbo àwọn igbakeji ọga ọlọ́pàá ati awọn kọmiṣanna ọlọ́pàá àti àwọn olùkọ́ oṣiṣẹ ọlọ́pàá láti kéde idaduro owo-osu.
Làsìkò ti ìjọba ààrẹ Buhari, owó yíya lo gbarale láti ṣe àwọn ìṣe àkànṣe àti sísan owó òṣìṣẹ́ idaduro owó oṣù yìí tún lé mu kí àwọn ọlọ́pàá máa lọ ará ìlú lọ́wọ́ gba si ju ti àtẹ̀yìnwá lọ pàápàá julọ lásìkò ọdún yìí.



















