Timothy Adegoke: Àkójọpọ̀ bí ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ lónìí rèé lórí bóyá Adedoyin ní ẹjọ́ láti jẹ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́

Timothy Adegoke ati Rahmon Adedoyin

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun ti wọgile ibeere ikọ olujẹjọ to kede fun ile ẹjọ naa pe oun ko ni ẹjọ jẹ lori iku Timothy Adegoke lọjọ Ẹti to kọja.

Igbesẹ naa waye lọjọru oni lasiko ti igbẹjọ pada bẹrẹ lori iku to pa Timothy Adegoke eyi to n waye nile ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Osun to kalẹ silu Osogbo.

Bẹẹ ba gbagbe, awọn agbejoro fawọn afurasi naa, eyiun Rahmon Adedoyin ati awon afurasi mẹfa yoku lo bẹ ilẹjọ naa pe ko da ẹjọ nu lórí ikú to pa Timothy Adegoke ni ilu Ile Ife.

Awọn afurasi naa lo salaye pe gbogbo ẹri tawọn ọlọpaa atawọn igun olupẹjọ ko wa siwaju ile ẹjọ ko kunju osuwọn lati bawọn se ẹjọ.

Àkọlé fídíò, Àwọn òṣìṣẹ́ Adedoyin jẹ́wọ́ fún wa pé àwọn pa àbúrò mi, ọ̀gá Adedoyin sì mọ̀ síi - Ẹ̀gbọ́n Timothy Adegoke

Nitori naa, wọn ni awọn ko ni jọ kankan lati ro lori iku oloogbe naa.

Amọ lẹyin igbẹjọ to waye ni ọjọ Ẹti to kọja, ni igun agbẹjọro olujẹjọ ati olupẹjọ kọ iwe sile ẹjọ lati salaye idi tawọn afurasi naa fi ni ẹjọ jẹ tabi bẹẹkọ.

Rahmon Adedoyin atawọn afurasi yoku gbọdọ rojọ nipa ẹri 32 ti igun olupẹjọ ko silẹ - Adajọ

Nigba to n gbe idajọ naa kalẹ lonii, Adajo Adepele Ojo ni oun ti se agbeyẹwo awọn awijare igun olupẹjọ ati olupẹjọ nipa boya awọn afurasi naa ni ẹjọ jẹ tabi bẹẹ kọ.

O ni pẹlu awọn ẹri ti àwọn olupẹjọ mú wá sí ilé ẹjọ, o ti fihan pé Timothy Adegoke pàdánù ẹ̀mi rẹ nínú ilé itura Hilton hotel ni ilu ile ìfẹ́, eyi to jẹ ti Adedoyin.

Adajọ Adepele Ojo sọ sìwaju pé ẹri mejilelọgbọn ni àwọn olupẹjọ mú wá sí ilé ẹjọ, eyi to fi idi rẹ mulẹ pe awon afurasi naa ni ẹjọ lati ro lori iku Adegoke.

O wa kede pe oun ko tii dajọ lori boya wọn jẹbi tabi wọn ko jẹbi amọ o di dandan fun wọn lati rojọ, ki wọn si salaye bi isẹlẹ naa se waye.

"A ko ni wọn jebi ẹsun naa sugbon òfin gbọdọ gbọ tí ẹnu àwọn agbẹjọro àwọn afurasi naa lati ri pe idajọ ododo waye.

Mo gbà agbejoro awọn afurasi naa nimọran lati gbaradi láti sọ tí ẹnu wọn lórí bóyá àwọn afurasi ọhun mọ nípa ikú Timothy Adegoke."

Agbejoro fún ìjọba, M.O Omashun nínú ọrọ rẹ sọ pé ìdajo naa lọ je àpẹẹrẹ pé idajo ododo yoo wáyé lórí ikú Timothy Adégòkè torí to ba jẹ pé ilé ẹjọ naa bá dá ẹjọ nù, idajọ ododo kò lè wáyé.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke: Màmá olóògbé ní ògó ilé àwọn ni wọ́n pa, ikú rẹ̀ kò gbọdọ̀ já sásán

Igun Femi Falana salaye idi to se fẹ gba agbara ofin lọwọ ijọba Osun:

Agbejoro to soju fun Agba amofin Femi Falana, eyiun Fatimah Adeshina salaye idi ti igun Falana se kọwe ransẹ sijọba Osun.

O salaye pe ijọba lo maa n lewaju ẹsun iwa ọdaran gbogbo labẹ ofin ilẹ wa, lati ipasẹ ileesẹ ọlọpaa.

Adeshina ni nigba ti awọn afurasi ti kede pe awọn ko ni ẹjọ jẹ, lo j ki Falana pinnu pe oun fẹ lewaju awọn ọlọpaa lati bawọn afurasi naa se ẹjọ.

Amọ o ni labẹ ofin, agbẹjọro kankan ti ko ba si labẹ ijọba ko le bọ sita pe oun yoo lewaju ọlọpaa ninu igbẹjọ iwa ọdaran kankan ayafi ti ijọba ipinlẹ naa ba ro ni agbara ofin lati se bẹẹ.

O salaye pe agbara ofin naa ni Falana n beere fun lọwọ ijọba ipinlẹ Osun ko le lewaju ikọ ọlọpaa to n bawọn afurasi se ẹjọ.

Adeshina sọ pe ijoba ipinle Osun ti gba iwe náà wọlé, tí àwọn sí n dúró de esi rẹ.

Ile ejo ti wa sun igbẹjọ naa sì ọjọ Kẹẹdogun osu kẹrin ọdun 2022.

Amin iyasọtọ kan

Bí ìjọba Osun kò bá gbé agbára òfin wọ̀ mi, yóò nira fún mi láti bá Rahmon Adedoyin ṣẹjọ́ - Falana

Femi Falana, Timothy Adegoke ati Rahmon Adedoyin

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe gbajugbaja Agbejoro nni, Femi Falana, tii se asaaju ikọ awọn agbẹjọro to n soju idile Timothy Adegoke ninu ẹjọ ẹsun ipaniyan to n lọ lọwọ nile ẹjọ giga ilu Osogbo, ti sọrọ lori igbẹjọ to n waye naa.

Bẹẹ ba gbagbe, lọjọ Ẹti ni awọn afurasi to n kawọ pọnyin rojọ, eyiun Ramon Adedoyin atawọn afurasi mẹfa miran, ti kede pe awọn ko ni ẹjọ jẹ lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan wọn.

Idi si ree ti Falana fi yari, to si ni ko si oun to jọ pe awọn afurasi naa ko ni ẹjọ jẹ, to si leri leka pe oun yoo fi agbara ofin pasẹ fun wọn lati jẹjọ ipaniyan naa.

Agba amofin naa ni oun ti fi ìwé iransẹ sì agbẹjọro agba fún eto idajo ni Ipinle Osun, Femi Akande, láti beere fun agbara ofin lati de awọn olujẹjọ naa.

O ni agbara ofin naa ni yoo kan nipa fawọn olujẹjọ naa lati jẹjọ lórí iku to pa Timothy Adegoke nile itura Hilton to jẹ ti Ramon Adedoyin nilu Ile Ifẹ.

Àkọlé fídíò, Omi Adio Robbery: Èèyàn márùn-ún tí kò mọwọ́-mẹsẹ̀ ló kú lásìkò ìdigunjalè PoS l‘Omi Adio

Falana wi awijare pe ayafi ti ìjọba ipinle Osun ba fún òun lagbára láti ba àwọn afurasi mefẹẹfa naa pelu Rahmon Adedoyin se ẹjọ, yoo nira fun oun lati tẹsiwaju lori ẹjọ naa.

O ni idi ni pe ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi naa lo jẹ iwa hihu iwa ọdaran si ijba ipinlẹ Osun.

Amọ lọwọ lọwọ bayii, ijọba ipinlẹ Osun ko tii gbe igbesẹ lori ibeere Femi Falana.

Nigba to n ba iwe iroyin Punch sọrọ, agbẹjọro agba fun ipinlẹ Osun, Akande naa ni oun si n duro de gomina Adegboyega Oyetola lati fun oun lasẹ pe ki oun fesi si ibeere Falana.

O ni gomina Oyetola ni yoo se ipinnu lori igbesẹ ti awọn yoo gbe nipa agbara ofin ti Falana n beere fun.

Bẹẹ ba gbagbe, ni ọjọ Ẹti ti igbẹjọ waye kẹyin ni awọn afurasi lori ẹjọ iku Timothy Adegoke ni awọn ko ni ẹjọ jẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Awọn afurasi naa kede bẹẹ nigba ti agbẹjọro wọn, Amosun pe wọn jade lati wa jẹri nile ẹjọ.

Igbẹjọ naa si n tẹsiwaju lonii Ọjọru lati mọ ibi ti igi ọrọ yoo wo si.

Àkọlé fídíò, Funke-Gbenga Adetuberu: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run rèé tó ní ọmọ líle, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí