Timothy Adegoke: Òṣìṣẹ́ woléwolé ṣàlàyé ìdí tí wn fi sin òkú olóògbé

Timothy Adegoke ati Rahmon Adedoyin/Facebook

Oríṣun àwòrán, Timothy Adegoke and Rahmon Adedoyin/Facebook

Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló ń tún fojú hàn bí ìgbẹ́jọ́ lórí ikú Timothy Adegoke ṣe tún wáyé nílé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Osun tó wà ní Osogbo lónìí.

Ramon Adedoyin tó ni ilé ìtura Hilton nilu Ile Ife níbi tí Timothy Adegoke kú sí àti àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìtura náà mẹ́fà ló ń kojú ẹ̀sùn ìpànìyàn àti ìlẹ̀dí àpò pọ̀.

Ẹlẹ́rìí àkọ́kọ́ tó wá jẹ́rìí nílé ẹjọ́ lónìí tií ṣe ẹlẹ́rìí kẹfà lórí ìgbẹ́jọ́ náà, ni Fatai Adebowale tó jẹ́ òṣìṣẹ́ woléwolé tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ Osun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oku Timothy Adegoke ti n jẹra, la ṣe sín - Wolewole

Adebowale ní lọ́jọ́ kẹjọ oṣù kọkànlá, ọdún 2021 ní òun gba ìpè látọ̀dọ̀ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá pe òkú ènìyàn kan tí wọ́n bá ní ẹ̀gbẹ́ títì lòpópónà Ede.

Ó ṣàlàyé pé nígbà tí àwọn fi ma dé ibí tí òkú náà wà lọ́jọ́ kẹsàn án, oṣù kọkànlá, òkú náà ti ń jẹrà, àwọn yá àwòrán òkú náà.

Ó fi kun pé nítorí tí òkú náà ti ń jẹrà, àwọn kò lè gbe e kúrò níbẹ̀ nítorí náà ni àwọn ṣe gbẹ́ ilẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀, tí àwọn sì sin òkú náà síbẹ̀.

Bákan náà ló ṣàlàyé pé lẹ́yìn èyí ni àwọn fín ibi tí àwọn sí òkú náà sí ní nǹkan bí ago méjì ọ̀sán.

Ó ní lẹ́yìn èyí ni àwọn ya àwòrán ibi tí àwọn sin òkú náà sí, tí àwọn sì ko lọ fún alága ìjọba ìbílẹ̀ náà.

Adebowale tẹ̀síwájú pé lọ́jọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù kọkànlá bákan náà, ni òun tún gba ìpè láti ọdọ̀ DPO àgọ́ ọlọ́pàá pé kí òun kó àwọn ẹ̀rí ìsìnkú náà wá sí àgọ́ wọn.

Ó ní òun sì ko fún wọn lọ́hùn.

Bákan náà ló ní kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn náà, ni àwọn ọlọ́pàá mìíràn tún wá láti Abuja lórí ìsìnkú náà.

O ni wọ́n sì ní kí òun kó gbogbo àwọn ìwé ẹ̀rí lórí ìsìnkú náà wá sí àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní Oke Fia, Osogbo.

Àkọlé fídíò, Plastic Recycler: Asade Abdulsalam ni kìí ṣe gbogbo ìdọ̀tí ni ẹ̀gbin, owó ni