Ogun Ritual Killing: Ọ̀kan lára àwọn afurasí mẹ́rin tó gé Sofiat Okeowo lọ́nà àti fi ṣẹ́ṣó gba ìtúsílẹ̀

Sofiat ati awọn afurasi to pa a

Oríṣun àwòrán, others

Ile ẹjọ majisteeti kan niluu Abeokuta ti tu ọkan lara awọn ọdọkunrin mẹrin ti wọn fẹsun kan pe wọn sun ori ọdọbinrin kan, Sodiat Okeowo, ninu ikoko lọna ati fi ṣẹṣo silẹ.

Awọn ọdọkunrin mẹrin naa ni Balogun Mustakeem, Majekodunmi Soliudeen, Abdulgafar Lukman ati Wariz Oladeinde.

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ wa lọgba ẹwọn Oba, eyii to wa ni ijọba ibilẹ Obafemi-owode ni ipinlẹ ọhun lori iku Sofiat ti wọn ge lọna ati fi ṣẹṣo.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2022 yii ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa lagbegbe Kugba, niluu Abeoukuta lẹyin ti wọn fẹsun kan wọn pe wọn ge ori Sofiat, to jẹ ọrẹbinrin Majekodunmi, ti wọn tun jo ori oloogbe naa ninu ikoko.

Àkọlé fídíò, Oníṣòwò ọ̀ọ̀nì àti ejò ní ẹran náà ń fún ara lóore láì wo èèwọ̀ àṣà àti ẹ̀sìn tó rọ̀ mọ

Alaye ree lori idi ti adajọ se fi Oladehinde silẹ:

Adajọ ile ẹjọ majistreeti ọhun, I.O. Abudu sọ pe wọn ti tu Wariz Oladehinde, to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun silẹ lẹyin ti awọn agbẹjọro ijọba ni ki wọn fi silẹ.

Adajọ Abudu ni wọn ko ri ẹsun kankan ka si Oladehinde lẹsẹ gẹgẹ bii iwe ti awọn agbẹjọro ijọba kọ.

O ni eyii ko ṣẹyin ọrọ ti ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe afurasi naa ko mọwọ-mẹsẹ ninu bi awọn afurasi to ku ṣe ge ẹmi Sofiat kuru.

Wayi o, wọn ti wa sun igbẹjọ naa si ọjọ kejilelogun, ọsu Kẹrin, ọdun 2022 yii.

Ẹwẹ, adajọ ọhun ti ni ki wọn dawọn afurasi mẹta to ku pada si ọgba ẹwọn titi di ọjọ ti igbẹjọ ọhun yoo tẹsiwaju.

Àkọlé fídíò, Anifat Bello: Mọ́tò gbá mi lẹ́nu iṣẹ́, eyin méjì fòyọ àmọ́ mo fi eyín oníke rọ́pò rẹ̀

Ṣe lootọ ni oogun owo wa?

Babalawo kan ti BBC Yoruba ba sọrọ, Olukunle Idowu, sọ pe ko si nkan to n jẹ etutu ọla tabi oogun owo ninu Ifa.

O ni to ba jẹ pe o wa ni, oun paapaa yoo ti ni owo tabua lọwọ.

Eyi tako igbagbọ ọpọ eeyan pe awọn babalawo lo n ṣe oogun ọrọ fawọn ọdọmọde ti wọn n wa owo ojiji lasiko yii.

Lẹnu ọjọ mẹta yii, iroyin fifi awọn eeyan ṣe oogun ti wa wọ pọ lawujọ.

Babalawo Idowu sọ pe ikanju lo bi gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii lati inu ile bọ si ode to fi de ọdọ ijọba.

Àkọlé fídíò, Áńkọ́fù ológun kéré fún ọwọ́ mi àmọ́ wọ́n fi okùn dì mí kúrò nílé lọ sí bárékè Odogbo