Hijab Ban in India: Ilé ẹjọ́ Karnakata ní kò sí ibi kankan nínú Kùránì tó ti pọ́n ní dandan fún obìnrin láti lo Hijab

Àwọn obìnrin tó lo hìjáàbù
Àkọlé àwòrán, Àwọn obìnrin tó lo hìjáàbù

Ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ Karnataka, orílẹ̀ èdè India ti gbé ìdájọ́ kan kalẹ̀ wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò ní ẹ̀tọ́ láti máa lo hìjáàbù ní àwọn ìyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́.

Ilé ẹjọ́ náà ní hìjáàbù lílò kò pọn dandan nínú ẹ̀sìn Islam àti pé kò ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀.

Àwọn adájọ́ mẹ́ta tó gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ ní gbígba àwọn obìnrin mùsùlumí láàyè láti máa wọ hìjáàbù nínú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ yóò jẹ́ ìtàpá sí òfin orílẹ̀ èdè náà.

Nínú àgbékalẹ̀ ìwé alábala mọ́kàndínláàdóje tó kún fún àwọn ọ̀rọ̀ láti inú Kùránì, àwọn adájọ́ náà ní kò sí ibi tí ẹ̀sìn Islam ti pá ní dandan fún àwọn obìnrin, láti máa wọ hìjáàbù àti pé tí òfin kò bá pa á ni dandan kò yẹ kí orílẹ̀ èdè náà mu ni tipátipá.

Ìdájọ́ yìí ló ń ṣe àtìlẹyìn fún àṣẹ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Karnataka ti pa ṣaájú wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò ní ẹ̀tọ́ láti máa wọ hìjáàbù nínú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́.

Àkọlé fídíò, Kwara Hijab Crisi: Èdè àwọn Krìsítẹ́nì àti Mùsùlùmí kò yé ara wọn lórí lílo Hijab

Ilé ẹjọ́ ní ìjọba ní àṣẹ láti sọ irúfẹ́ aṣọ tó bá fẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa wọ̀.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ní oṣù kìíní ọdún yìí ni ilé ẹ̀kọ́ kan ní ìpínlẹ̀ Karnataka fòfin de gbígba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ obìnrin láti máa wọ hìjáàbù ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́.

Ìpinu yìí ló fà á tí àwọn mùsùlùmí ní ìpínlẹ̀ náà ṣe ìwọ́de tó sì fi di ọ̀rọ̀ ńlá.

Ní ọ̀pọ̀ ọjọ́ ní ìjọba fi ti àwọn ilé ẹ̀kọ́ kan lórí pa nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Lẹ́yìn èyí ni àwọn obìnrin náà gba ilé ẹjọ́ láti pe ìjọba lẹ́jọ́ pé ìwé òfin orílẹ̀ èdè India fi àyè gba àwọn láti lo hìjáàbù níbiníbi àti ní ìgbàkúgbà.

A ó pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn:

Ọ̀jọ̀gbọ́n Ravi Varma Kumar tó jẹ́ agbẹjọ́rò àgbà fún àwọn olùpejọ́ ní àwọn yóò ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ.

Bákan náà ní àwọn olùpẹjọ́ ní ilé ẹjọ́ já àwọn kulẹ̀ fún ìdí àwọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú ilé ẹjọ́ náà mọ́.

Wọ́n ní àwọn yóò ja ìjà náà títí dé òpin.

Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ náà ń lọ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mùsùlùmí kò lọ sí ilé ẹ̀kọ́, kódà ọ̀pọ̀ wọn ni kò ṣe ìdánwò nítorí hìjáàbù.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin náà fi àyè sílẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti wọ hìjáàbù nígbà tí wọ́n bá wà ní ọgbà ilé ẹ̀kọ́, wọ́n ní kò tẹ́ àwọn lọ́rùn láti máa gèlè àwọn bá fẹ́ wọ kílàsì.

Ẹ̀wẹ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ náà ní ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà tẹ́ àwọn lọ́rùn.

Àkọlé fídíò, Áńkọ́fù ológun kéré fún ọwọ́ mi àmọ́ wọ́n fi okùn dì mí kúrò nílé lọ sí bárékè Odogbo