Kwara Hijab Crisi: Abdulrazaq ní òun tẹ̀lé ìdájọ́ ilé ẹ̀jọ́ lórí lílo Hijab

Gomina Abdulrazaq Abdulrahman ati awọn akẹkọọ to wọ Hijab

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrazaq Abdulrahman ti kede pe gba gba gba ni oun wa lẹyin ofin to fun awọn akẹkọọbinrin musulumi laaye lati lo Hijab.

Atẹjade kan ti akọwe eto iroyin fun gomina ipinlẹ Kwara, Rafiu Ajakaye fisita lo sisọ loju ọrọ yii.

Gomina Abdulrazaq ni atilẹyin oun yii lo wa nibamu pẹlu idajọ ile ẹjọ lori ọrọ naa ati bi ipinlẹ Kwara se jẹ awujọ ti ọpọ ẹsin wa.

O ni ohun to mu ipinlẹ naa wu oju ri ni bi awọn eeyan rẹ se n gbe pọ laarin ọpọ ẹsi gẹgẹ bii ipinlẹ ẹkun guusu Naijiria amọ to wa ni ẹkun ariwa.

O salaye ẹyin ofin ni ijọba oun wa pẹlu ododo ati aisegbe sibi kan ni gbogbo igba.

Àkọlé fídíò, Bukola Odufuwa: Mo ń ta oúnjẹ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, gbálẹ̀, fọ aṣọ, pọnmi láì tọrọ agbe jẹun

Ki lo mu gomina kede igun to fi si lori lilo Hijab?

Ikede gomina ipinlẹ Kwara yii lo tẹle bi awọn Musulumi ati Kristiẹni se n fi ọwọ gun ijọba nimu pe ko le bọ sita sododo lori isẹlẹ to n waye nidii lilo Hijab nile ẹkọ.

Awọn ẹlẹsin mejeeji naa n na ika aleebu si gomina Abdulrazaq pe tori eto iselu ni ko jẹ ko mọ odo ti yoo da ọrunla si nidi ọrọ naa.

Amọ atẹjade ti ijọba fisita lori isẹlẹ yii ni kii se pe ijọba n fi ọwọ ra awọn igun kan lori lati gbe sẹyin igun kan amọ o n se suuru lati sọ ero rẹ lori ọrọ ẹlẹgẹ naa ni.

Gomina wa rawọ ẹbẹ sawọn olugbe ipinlẹ naa lati mase jẹ ki awọn iroyin eke ati si wọn lọna tabi gbe wọn gun ara wọn.

Awọn Musulumi kọ owo gba ma binu ti gomina fun wọn:

Awọn mọlẹbi ati igun Musulumi ti faake kọri lati gba owo gba mabinu ti ijọba fun wọn lori ẹni to ku atawọn to fara pa nidi laasigbo lilo Hijab.

Miliọnu kan naira owo gba ma binu ti ijọba fun mọlẹbi Habeeb Idris to ku lasiko laasigbo lilo Hijab to waye nile ẹkọ Oyun Baptist High School nilu Ijagbo ni wọn ko gba.

Bakan naa ni wọn kọ ẹgbẹrun lọna ọtalerugba o din mẹwa naira (N250,000) ti ijọba fun ikọọkan musulumi mọkanla to fara gbọgbẹ lasiko wahala naa.

Àkọlé fídíò, Kwara Hijab Crisi: Èdè àwọn Krìsítẹ́nì àti Mùsùlùmí kò yé ara wọn lórí lílo Hijab

Ki lo ti sẹlẹ sẹyin:

O ti le ni ọdun kan bayii ti aawọ ẹsin ti n da omi alaafia ru ni awọn ile ẹkọ to jẹ ti Kristiẹni nipinlẹ Kwara.

Koda, aawọn naa ti mu ọgbẹ nla ba awọn eeyan kan lasiko rogbodiyan to waye ni ọdun to kọja.

Bakan naa ni ọpọ ile ẹkọ ni ijọba gbe ti pa nitori rogbodiyan naa, to si se ipalara fun eto ẹkọ lasiko naa.