Nigeria Electoral Bill: Ṣé Buhari yóò buwọ́lu àbádòfin ètò ìdìbò 2022 tuntun báyìí?

Oríṣun àwòrán, Presidency nigeria
Nigba ti Aarẹ Muhammadu Buhari wọle sipo, lara awọn ileri to ṣe ni lati mu ayipada tootọ ba eto idibo ni Naijiria, amọṣa, eyi n dabi ẹni pe o n falẹ.
Awọn ẹgbẹ ajafẹtọ kan 'se iwọde nilu Abuja nibi ti wọn ti n tẹ ẹ mọ aarẹ leti pe, ko tete buwọlu abadofin tuntun fun ilana idibo ni Naijiria eleyi to ti fi n falẹ lati igba diẹ bayii.
Awọn ẹgbẹ ajafẹtọ naa n fẹ ki aarẹ ṣe ohun to tọ lori bibuwọlu abadofin ọhun lẹyin ti awọn aṣofin ti ṣe gbogbo ohun to fẹ lori rẹ ki wọn to tun taari rẹ pada sii.
- UK fófin de bánkì márùn ún pẹ̀lu olówó Russia mẹ́ta torí làásìgbò Ukraine
- Sotitobire: Ẹ wá wo ohun t'Ọ́lọ́run ń ṣe ní ìjọ mi lẹ́yìn tí mo bọ́ ní ẹ̀wọ̀n gbére tẹ́ẹ tì mí lọ
- Adájọ́ fi ọ̀sẹ̀ méjì kún àkòkò tí Abba Kyari yóò lò ní àhámọ́ NDLEA
- Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ TUC ń palẹ̀ ìyanṣẹ́lódì mọ́ torí ọ̀wọ́ngógó bẹntíróòlù
- Aáwọ̀ APC fẹ́jú, igun kan ń gbé pósí kiri Eko lórúkọ Aregbesola
- Naijiria nílò àwọn ‘Ọlọ̀tẹ̀’ tí yóò máa gbéna wojú ìjọba kó lè tẹ̀síwájú - Obasanjo
Bakan naa lawọn ẹgbẹ alatako kan n pariwo pe boya ki wọn sun idibo naa siwaju di igba miran.
Ohun ti wọn si ni pe ofin naa faaye silẹ fun ajọ eleto idibo lati kede awọn ọjọ kan fun idibo yoowu ti yoo ba waye to ba ti n di nnkan bii ọdun kan si asiko ibo.
Sugbọn eyi le maa ri bẹ bi aarẹ ko ba tete buwọlu abadofin naa ki olukuluku lee mọ ibi to n lọ.
Agbẹnusọ fun aarẹ, Fẹmi Adeṣina pẹlu ti n fi gbogbo igba fọnrere rẹ pe diẹ bayii naa lo ku fun aarẹ lati buwọlu abadofin ọhun; nitori naa ki gbogbo eniyan lọ fi kan wọn balẹ.
Kikuna lati buwọlu abadofin yii ati lati mojuto ifidimulẹ rẹ yoo bu omi tutu sọkan awọn araalu lori ọrọ ibo.
"Odabi ẹni pe aarẹ ko wulẹ fẹ buwọlu abadofin naa ni."
Awọn eekan lamẹtọ lori ọrọ oṣelu bii Ọmọwe Abubakar Kari ṣalaye fun BBC pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, ni iwoye oun o, awọn iṣẹlẹ to n ṣẹlẹ pẹlu ọrọ ofin idibo naa kọja agbara aarẹ.
Ọmọwe Kari ni, "o dabi ẹni pe aarẹ ko wulẹ fẹ buwọlu abadofin naa ni."
"Igba kẹfa niyi lasiko iṣejọba aarẹ Buhari ti wọn ti n gbe ofin yii de ọdọ rẹ, ṣugbọn to ti n wa awawi kan tabi omiran lati kuna bibuwọ lu u ."
Eekan onimọ nipa oṣelu naa, wa tun fi kun un pe pupọ ọmọ Naijiria ni inu wọn ko dun si bi aarẹ ṣe n fi ẹsẹ falẹ lori ọrọ bibuwọ lu abadofin ilana eto idibo ọhun.
O tun tẹsiwaju pe, pẹlu bi o ṣe jẹ pe aarẹ Buhari lo janfani ilana eto idibo ti ko ni kọnunkọhọ ninu lorilẹede Naijiria, sibẹ oun gan an lo wa n ṣe adinagbooku fun awọn ilepa ọpọ ọdun lati ṣe afọmọ ofin idibo ni Naijiria.
Ki lawọn onwoye n sọ?
Awọn onimọ nipa ọrọ oṣelu pẹlu awọn ajafẹtọ ni Naijiria ti fi oju laifi wo igbesẹ aarẹ Buhari.
Wọn sọ ọ kalẹ bi ogulutu pe abawọn nla ni ohun to n rawọle lọwọ nipa abadofin ilana idibo Naijiria naa yoo jẹ, ti wọn ba n kọ itan ilana oṣelu rẹ ati eto ijọba alagbada lorilẹede Naijiria.
Ọpọ lo n woye pe bi aarẹ ba fi le kuna lati buwọlu abadofin ilana eto idibo naa, yoo wulẹ di dandan lati ṣe amulo ofin eto idibo Naijiria tọdun 2010 ni eleyi ti yoo jẹ ifasẹyin nla gbaa fun eto oṣelu Naijiria.














