Fuel Scarcity: Ẹgbẹ́ TUC ní káwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ jóko sílé torí ọ̀wọ́n epo

Awọn eeyan tto duro lati ra epo

Oríṣun àwòrán, IPMAN

Ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC ti n gbero lati gunle iyansẹlodi ti ọwọngogo epo bẹntiroolu ba tẹsiwaju kaakiri orilẹede Naijiria.

Ẹgbẹ TUC ni awọn oṣiṣẹ l'awọn ileeṣẹ kosemani at'awọn ileeṣẹ ijọba ni ọrọ ìyanṣẹ́lódì ọhun yoo kan ti o ba ṣẹlẹ.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC n binu si ileeṣẹ aarẹ papaa julọ aarẹ Muhammadu Buhari .

TUC ni o ti yẹ ki Buhari mọ awọn to wa nidi ọwọngogo epo to gbode ni Naijiria, ki o si fi ijiya to tọ sí wọn jẹ wọn.

Àkọlé fídíò, 'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'

Ọrọ ti TUC sọ lẹyin ipade opin ọsẹ:

Akapo ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC, Mohammad Yunusa lo ṣi aṣọ loju ọrọ yii nibi ipade awọn agba oṣiṣẹ, SSASCGOC niluu Abuja lopin ọsẹ to kọja.

Yunusa to jẹ aarẹ ẹgbẹ SSASCGOC tẹlẹ ṣalaye pe ẹgbẹ naa ti sọ fawọn ọmọ ẹgbẹ lati joko sile titi digba ti ọwọngogo epo yoo fi tan nilẹ.

Yunusa ni "ohun ti a beere fun ni pe ki ijọba wa awọn to wa nidi ọwọngogo epo to gbode kan ki o si fi iya jẹ wọn.

Bakan naa ni ẹgbẹ SSASCGOC to jẹ ọmọ ẹgbẹ TUC ti sọ fun TUC pe, ko paṣẹ fawọn oṣiṣẹ lati dẹkun lilọ si ibi isẹ titi di igba ti epo yoo fi wa daadaa.

Ohun ti a le ṣe niyii, a ṣi n reti esi lati ọdọ TUC.

Àkọlé fídíò, Ìjẹ̀bú: Àgbàlàgbà ni mo máa ń ṣe nínú eré tẹ́lẹ̀

Ẹ pasẹ pe ki awa osisẹ fidi mọle tori ọwọngogo epo

Ṣugbọn igbesẹ ati ero tiwa ni SSASCGOC ni pe ko yẹ ki ẹnikẹni maa lọ sibi iṣẹ mọ níwọ̀n igba ti ọwọngogo si wa nita.

Ẹ duro si ile yin, ti epo ti ijọba n sọ ba dé, onikaluku yoo pada sẹnu iṣẹ."

Ẹwẹ, Yunusa tun bu ẹnu ẹtẹ lu ijọba apapọ lori ọwọ to fi mu ọrọ iyanṣẹlodi ẹgbẹ olukọ fasiti, ASUU.

O ni ọwọ yẹpẹrẹ ni ijọba fi mu eto ẹkọ ni Naijiria.

Yunusa ni oniruuru adehun ni ijọba apapọ ti buwọlu pẹlu ASUU amọ ti ijọba kuna lati muṣẹ.

"Iṣoro kan gboogi ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ n koju ni Naijiria ni pe ijọba kii gbọ ọrọ t'awọn oṣiṣẹ n sọ.

Ko ṣeeṣe lati ni ijiroro ti yoo so eso rere pẹlu ijọba apapọ.

ASUU n sọ nípa adehun ti wọn ti ni pẹlu ijọba apapọ tipẹ tipẹ ti ijọba ko tii sọ ohun kan nipa rẹ.

Igba ti awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ba pe fun ìyanṣẹ́lódì nikan ni ijọba maa n tẹti lati gbọ ohun ti wọn n sọ," Yunusa lo sọ bẹẹ.