Osun APC Crisis: Igun ẹgbẹ APC kan ṣe ìwọ́de tako Aregbesola nítorí Tinubu

Posi ti wọn n gbe kiri lorukọ Aregbesola

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Yoruba ni ti ọrọ ba n pẹ nilẹ, gbigbọn ni yoo maa gbọn si.

Bẹẹ lo se ri lori aawọ oselu to n waye laarin Minisita fun ọrọ abẹle, Rauf Aregbesola, Gomina ipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola ati asaaju ẹgbẹ APC kan to fẹ dije fun ipo aarẹ, Bola Ahmed Tinubu.

Bi o tilẹ jẹ pe ipinlẹ Osun ni Aregbesola ati Oyetola ti n wọja ija lori ọrọ ti wọn lo nii se pẹlu erongba Tinubu lati di aarẹ amọ ọrọ naa ti tan de ipinlẹ Eko ti Tinubu wa bayii.

Alaye ree lori bi aawọ APC se tan de ilu Eko:

Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kan ṣe ifẹhonuhan niluu Eko lọjọ Aiku tako Aregbesola lori ẹsun pe o n gbena woju Asiwaju Bola Tinubu.

Agbegbe Alomosho ni ifẹhonuhan naa ti waye niluu Eko.

Orisiirisii iwe ilewọ l'awọn oluwọde naa mu dani eleyii ti wọn kọ oniruuru ọrọ kobakungbe sí nipa Aregbesola.

Bakan naa ni wọn gbe posi kan lọwọ eyi ti wọn ni awọn fi n se ọfọ Aregbesola to di ẹni igbagbe nidi oselu.

Bi wọn si ṣe n gbe posi naa kiri awọn oju popo kan ni agbegbe Alimosho, naa ni won n jo pẹlu posi ọhun, ti wn si n kọ orin ọfọ pẹlu.

Posi ti wọn n gbe kiri lorukọ Aregbesola

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ki lo de ti igun APC kan n se ọfọ Aregbesola lai tii ku?

Nigba ti wọn n se iwọde naa kiri, awọn asaaju igun to n wọde naa bawọn akọroyin sọrọ lati salaye ohun to mu ki wọn gbe igbesẹ naa.

"A fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe agbegbe Tinubu ni Alomosho jẹ," "Asiwaju ni a ba lọ, a kii ṣe abara m'oore jẹ,"

"Ko si ohun to n jẹ BATCO," diẹ lara awọn ọrọ to wa ninu iwe ilewọ ti wọn mu dani niyẹn.

Awọn kan lara awọn oluwọde naa tiẹ tun gbe posi eleyii ti wọn fi ṣe àpèjúwe wi pe irin-ajo oṣelu Aregbesola ti dopin nipinlẹ Eko.

Ki ni ero igun Aregbesola lori isẹlẹ yii:

Amugbalẹgbẹ Aregbesola, Bola Ilori, nigba ti awọn akọroyin Punch kan si lati sọ ero rẹ si isẹlẹ naa salaye pe oun ko le sọrọ lori iwọde naa tori pe olori ninu ẹgbẹ ni Tinubu ati Arẹgbẹ jẹ.

Igbiyanju lati gbọrọ lẹnu oludamọran Aregbesola lori ọrọ iroyin, Sola Fasure, naa si lo ja si pabo.

Awọn to wọ asọ ti wn fi n se ọfọ ni orukọ Aregbesola

Oríṣun àwòrán, Sreen shot

Kini lo fa aawọ laarin Tinubu ati Aregbesola?

Ọrọ lori idibo abẹnu fún ipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Osun lo fa ede-aiyede laarin Aregbesola ati Tinubu.

Tinubu n ṣe atilẹyin fun Gomina Gboyega Oyetola lati lọ fun saa keji gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Osun.

Amọ, akọwe ijọba ipinlẹ Osun tẹlẹ, Alhaji Moshood Adeoti ni Aregbesola fẹ ko ṣoju APC ninu idibo gomina ipinlẹ Osun to n bọ.

Eyi gan lo fa gbọmi sii omi o to ninu ẹgbẹ APC ni ipinlẹ Osun.

Itahunsiraẹni ti waye ṣaaju idibo abẹnu ọhún to waye lọjọ Abamẹta to lọ laarin awọn ọmọlẹyìn Aregbesola ati gomina Oyetola.

Esi idibo abẹnu naa fihan pe Gomina Oyetola lo jawe Olubori pẹlu ẹgbẹẹrun ibo.

Posi ti wọn n gbe kiri lorukọ Aregbesola

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Aregbesola sọrọ lori aawọ to n lọ lọwọ ninu ẹgbẹ APC l'Osun:

Aregbesola ṣalaye pe adari awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Osun ni Oyetola nigba ti oun fi jẹ gomina ipinlẹ Osun.

''Mo fi gbogbo agbara mi ṣiṣẹ lati ri pe Oyetola di gomina ipinlẹ Osun.

Ṣugbọn o jẹ iyalẹnu fun mi pe lati igba ti Oyetola ti di gomina ni o ti wa n ṣọ mi lọwọ ṣọ mi lẹsẹ.

Ọdun meji ni mo fi bẹ Oyetola lati dẹkun aawọ to n ṣẹlẹ lọwọ yii ninu ẹgbẹ APC, amọ ko gbọ si mi lẹnu,'' Aregbesola lo sọ bẹẹ.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun pese eto abo to muna doko fun eto idibo abẹnu to waye lọjọ Abamẹta.