2022 World Indigenous Language Day: Ìjọba Osun bẹ̀rẹ̀ fífi èdè Yorùbá kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní kíláàsì
Ayajọ ọjọ ede abinibi lagbaye, eyi to maa n waye ni ọjọ Kọkanlelogun osu keji ọdọọdun tun ti ko lonii.
Akoko ayajọ naa ni awọn ẹya ati ede maa n se agbelarugẹ ede wọn tayọtayọ, ti wọn yoo si se afihan rẹ fun araye lati mọ si nipa rẹ.
Ọdun 2022 yii si lo pe ọdun mẹwa gbako ti ajọ to n se agbelarugẹ asa ati ede ni agbaye, UNESCO se agbekalẹ rẹ, eyi to mu ki ayẹyẹ naa buyaari si.
- Ohùn márùn ún tó yẹ kí o mọ́ nípa àyájọ́ èdè abínibí
- Bawo ni o ṣe mọ ede rẹ si?
- Àwọn olùkọ́ èdé Yorùbá l‘Eko dábírà ní àyájọ́ èdè abíníbí
- BBC Yorùbá gba àmì ẹ̀yẹ akọni nídìí àgbéga àṣà àti èdè abínibí
- Ọ̀pọ̀ òṣèré tíátà tó ń sàìsàn ni kò ṣe dáadáa f'ẹ́gbẹ́ - Jide Kosọkọ
- Ọ̀pọ̀ nǹkan tí kò yé èmi àti Bàbá Wande, ló fa ìjà lórí sinimá Tolúwa Nilẹ̀ - Tunde Kelani
Akori ayajọ ede abinibi lagbaye fun ti ọdun yii ni 'Lilo agbara imọ ẹrọ fun ikẹkọ awọn ọpọ ede abinibi: ipenija ati anfaani to wa nidi rẹ.'
Ẹ maa sọ ede abinibi si awọn ọmọ yin - Ijọba Osun
Ọna lati se agbelarugẹ ayajọ ede abinibi to ko loni naa ni ijọba ipinlẹ Osun se gbe akanse eto kalẹ lati sami ọjọ naa.
Kọmisana fun ọrọ asa ati irinjo afẹ nipinlẹ Osun, Obawale Adebisi ati asoju ẹka to wa fun agbelarugẹ asa Yoruba, Ọmọọba Popo Toluwase, Oba Olusina Oyekole se fi ọwọ wẹ ọwọ.
Awọn mejeeji wa gba awon obi ati alagbatọ ni iyanju lati ri pe wọn daabo bo asa ati ise ilẹ Yoruba nipa sisọ ede abinibi si awọn ọmọ wọn.
Ninu ọrọ wọn, wọn gba pe sisọ ede abinibi sawọn ọmọde ko lee se akoba fun sisọ ede gẹẹsi to dangajia.
- Ẹ̀mí bọ́ nígbà tí ọ̀rẹ́ méjì bẹ́nú fúnra wọn nídìí tẹ́tẹ́, ọ̀kan fi ayùn gé ẹsẹ̀ èkejì
- "Agbódegbà ní báǹkì àtàwọn míì ló wà nídìí ìdigunjalè ọkọ̀ agbówórìn n‘Ibadan"
- Aláboyún àti èèyàn mẹ́jọ míì jóná kọjá mímọ̀ nínú ìjàmbá ọkọ̀ n'Ilorin
- Ẹ wo Bàbá tó pòórá lẹ́ni ọdún 26, àmọ́ tó dédé yọ sí ìlú lẹ́ni ọdún 63
- Naijiria nílò àwọn ‘Ọlọ̀tẹ̀’ tí yóò máa gbéna wojú ìjọba kó lè tẹ̀síwájú - Obasanjo
- Ó ṣeéṣe ká ti ẹsẹ̀ òfin bọ èsì ìbò abẹ́nú gómìnà APC l‘Osun - Aregbesola
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni olubi ọmọ níí ṣe pẹ̀lú àyànmọ́ ọmọ láyé?
- Mo nífẹ̀ẹ́ ìyàwó mi jú ìyá àtàwọn ọmọ mi lọ - Kolawole Ajeyemi
Oyekola sọ siwaju pe Yoruba awọn ọmọ wa gbọdọ gbe pẹẹli ju bo se wa yii lọ ati pe o gbọdọ jẹ lilo fawọn akẹkọọ to ba ba fẹ wọ ile ẹkọ.
Obawale Adebisi ninu ọrọ rẹ sọ pe ipinlẹ Osun wa ninu awọn ipinlẹ to gbe asa abinibi larugẹ nipa riri daju pe wọn n fi ede Yoruba kọ awọn akẹkọọ ni kilaasi ikẹkọ.
O tẹsiwaju pe ipinlẹ Osun ti setan lati gbe ede Yoruba larugẹ nipa riri daju pe ede Yoruba di ohun elo fun awujọ agbaye.




















