Àyájọ́ èdè abínibí: Ọjọ́ ìsinmi ni àyájọ́ èdè abínibí jẹ́ ní Bangladesh

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Njẹ ẹyin mọ adape fèrèsé lede Gẹẹsi?
Agadagodo nkọ tabi ikeemu?
Orukọ awọn nnkan eelo ile wọnyi ti a darukọ, fun awọn ti ko ba munadoko ninu ede Yoruba, yoo dabi nnkan to le.
Amọ awọn itumọ wọn ko le rara.
Ohun to jẹ ki a lo awọn ọrọ wọnyi ninu iroyin wa lonii, to wa fun ayajọ ọjọ agbelaruge ede abinibi lagbaye, ni ki a ba le tọka pataki ede abinibi ati bi pupọ ninu ede abinibi lagbaye ṣe n lọ si oko iparun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọrọ pupọ ni ẹ le ti ka nipa ayajọ ọjọ yii, ṣugbọn fun anfaani wa, a fẹ ki a la ara wa loye nipa nnkan maarun ti a ko mọ nipa ayajọ ọjọ yii.
Ki gan an ni orisun ọjọ yii?
Ọdun 1999 ni ajọ UNESCO ya ọjọ kọkanlelogun, Osu Keji sọtọ lati fi gbe ede abinibi larugẹ.
Ohun to ṣe atọna igbesẹ yii ni akitiyan awọn oluwọde lorile-ede Bangladesh, nigba ti wọn ko ti ya kuro lara Pakistan.
Ijọba igba naa ni ki wọn maa lo ede Urdu ni dandan dipo ede abinibi wọn, tii ṣe Bangla.
Ọrọ yi ko dun mọ ara ilu ninu rara.

Oríṣun àwòrán, Rehman Asad/Barcroft Media/Getty
Eeyan marun un lo padanu ẹmi wọn nigba ti ọlọpaa yinbọn lu awọn oluwọde lọdun 1952.
Ifẹhonu han ti wọn ṣe nitori lilo ede abinibi wọn, lo faa ti ijọba fi pada wa gbe ofin sita pe ki wọn pada maa lo ede ti wọn fẹ.
Titi di oni, ayajọ ede abinibi jẹ ọjọ isinmi lorileede Bangladesh, ti wọn si fi n ranti awọn akọni ti wọn padanu ẹmi wọn ninu iwọde to sokunfa lilo ede abinibi wọn.
Awọn ede to ti parun ni Naijiria:
Lara idi pataki ti wọn fi ya ọjọ yi sọtọ ni ki awọn ede abinibi ma ba parun.
Bi o tilẹ jẹ pe a n sami ayajọ yii, sibẹ ọpọ ede lo ti parun kaakiri agbaye.
Ohun ti eyi tumọ si ni pe, ko si awọn eeyan to n sọ awọn ede to ti ku wọnyi, ti ko si si awọn arọmọdọmọ wọn to n sọ ede naa.
Awọn ede Naijiria to parun ni iwọnyi:
- Ajawa
- Auyokawa
- Basa-Gumna
- Gamo-Ningi
- Kpati
- Kubi
- Mawa
- Teshenawa
Awọn ede to wa ninu ewu iparun ni Naijiria:
Mẹtadinlọgbọn ni awọn ede abinibi ti o wa ninu ewu iparun ni Naijiria, gẹgẹ bi nnkan ti a ri ka lori Wikipedia.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko si ede kankan nilẹ kaarọ ojiire ti ọrọ yi kan, ṣugbọn pupọ awọn ede ti ọrọ yi kan ni awọn to wa ni agbegbe iwọ oorun ati awọn apa kan lariwa Naijiria.
Lara wọn la ti ri
- Akum
- Bade
- Bakpinka
- Defaka
- Duguza
Awọn ami ẹyẹ fun igbelarugẹ ede
Inu didun lo n mu ori yiya wa. Fun awọn to n ṣapa lati gbe ede abinibi larugẹ, awọn ami ẹyẹ kan wa ti wọn la kalẹ lati fi ṣe iwuri fun wọn.
Mẹta ninu awọn ami ẹyẹ to lamilaaka niwọn yi:
- Ami ẹyẹ Linguapax Prize -
- Ami ẹyẹEkushey Heritage Award
- Ami ẹyẹ Ekushey Youth Award
Ki la le ṣe ki ede fi ma parun?
- Kikọ awọn ọmọ wa lede wa lati kekere.
- Ṣiṣe agbekalẹ ofin lati sọ kikọ ede di dandan, iru eyi ti ipinlẹ Eko ṣe
- Iṣe nla wa niwaju awọn obi. Ohun ti a ba kọ ọmọ ni wọn yoo tele. Ẹ ma sọ ede yin si awọn ọmọ yin
- Gẹgẹ bi ohun ti awọn onimọ sọ, ede jẹ ọna kan gboogi ti a fi n ṣe igbelaruge ohun ajogunba wa, eyi ti o n mi ati eyi ti ko mi
- Wọn tẹsiwaju pe gbogbo ọna lati ṣe itankalẹ ede a ma mu ki awọn eeyan ni ifarada fun ẹya miran ati.





















