Tinubu Presidential Ambition: Aisha Yusuff fèsì padà bí Tinubu ṣe ní káwọn ọ̀dọ́ sẹ́ńpẹ́ fún ipò ààrẹ

Bola Tinubu ati Aisha Yesufu

Yoruba ni gbogbo sọrọ-sọrọ, ki wọn maa ranti awọn to mọ ọrọ gbọ nitori isọrọ ni igbesi, isunkunsi ni igbete gan-n-gan.

Ọpọ eeyan lo ti n fesi si ọrọ ti Aṣiwaju Bola Tinubu sọ nigba to ṣabẹwo si Alaafin Oyo, nibi to ti ba awọn ọdọ se awada pe ki wọn lọ sẹnpẹ fun oun na.

Tinubu, lasiko to n ba Alaafin tilu Oyo, Ọ́ba Lamidi Olayiwola Adeyemi sọrọ lo se ẹfẹ bẹẹ, to si ni awọn ọdọ naa yoo dagba, wọn yoo si aarẹ orilẹede Naijiria lọjọ kan.

Amọ, Tinubu sọ fun wọn pe ki wọn kọkọ fun oun laaye lati jẹ aarẹ Naijiria na, ki wọn wa pada du ipo naa lẹyin saa isejọba oun.

Àkọlé fídíò, Ìjẹ̀bú: Àgbàlàgbà ni mo máa ń ṣe nínú eré tẹ́lẹ̀

Awa ọdọ yoo ya ọpọ eeyan lẹnu ni 2023 - Aisha Yesufu

Nigba ti o ba BBC Yoruba sọrọ, ajafẹtọ ọmọniyan, Aisha Yesufu ní àwon ọdọ ṣetan lati padi ọrẹ da ninu eto idibo ọdun 2023.

Yesufu ni asiko t'awọn ọdọ maa n dẹyẹ si eto oṣelu ti kọja sẹyin.

Yesufu ni awọn ọdọ ti ṣetan lati ya gbogbo eeyan lẹnu ninu idibo ọdun to n bọ.

"Awọn ọdọ Naijiria ni oriṣiiriṣii amuyẹ lati dije fun oniruuru ipo oṣelu lọdun 2023.

Awọn ọdọ koju osunwọn, ọlọpọlọ pipe ni wọn, wọn le lo imọ ẹrọ ati ayelujara lati dé ipo."

Ọrọ ipo oṣelu ko nii ṣe pẹlu ọjọ ori, o nii ṣe pẹlu ẹni to koju osunwọn:

Aisha Yesufu tẹsiwaju peọrọ ipo oselu ni Naijiria ko ni ohunkohun se pẹlu ọjọ ori bi ko se bi oloselu naa kunju iwọn si.

"Ọpọ awọn agba oloṣelu Naijiria lo ti fihan pe wọn ko koju osunwọn lati wa ni ipo olori ti wọn wa.

Ohun to yẹ k'awọn eeyan se lati se ipinnu to yẹ nitori adura kọ ni yoo mu iyipada ti a n fẹ ba Naijiria.

A ni lati ṣiṣẹ papọ fun igbega orilẹ ede Naijiria.

Ọlọrun kọ ni yoo mu iyipada ba Naijiria nitori o tí fun wa lagbara lati le mu iyipada rere ba Naijiria."

Àkọlé fídíò, OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...

Awọn agba oloṣelu gan an mọ agbara ti awọn ọdọ Naijiria ni:

Bakan naa ni Yesufu salaye pea"awọn agba oloṣelu gan an mọ agbara ti awọn ọdọ Naijiria ni.

Eyi ni ko jẹ ki awọn oloṣelu gan an kọ iyan awọn ọdọ kere lagbo oṣelu ni Naijiria.

Awọn ọdọ ode oni yatọ s'awọn ọdọ ti tẹlẹ nitori awọn ọdọ ode oni le ṣe ipade pọ lori ayelujara lati ṣe ohun ti wọn ba fẹ.

Eleyii ko ri bẹẹ tẹlẹ, awọn ọdọ ode oni lo le ṣe ohun tàwọn araalu n fẹ bi eto ẹkọ tó ye koori, eto ilera to peye ati eto abo to múná dóko.

Awọn ọdọ Naijiria ni lati ṣe ara wọn ni ọkan gẹgẹ bi wọn ti ṣe l'asiko iwọde EndSARS," Yesufu ṣalaye.

Àkọlé fídíò, Abeokuta murder

Aisha Yesufu sọrọ lori bi awọn agba oloṣelu ṣe n lo owo lati wọle ipo oṣelu:

Yesufu ni asiko ti to fáwọn araalu lati dibo fawọn ti yoo tun Naijiria ṣe kí wọn si gbagbe nipa awọn to n fowo ra ibo wọle.

Awọn eeyan ni lati ṣe iranwọ owo fawọn ọdọ tó bá fẹ dupo oṣelu.

Ko si iye to kere lati ṣe iranwọ fun oludije ipo oṣelu.

Ti a ba sọ pe a ko ni lo owo wa lati seranwọ fawọn ọdọ tó fẹ dupo oṣelu, awọn agbalagba to ti n ṣe ijọba lori wa tipẹ tipẹ naa ni a o maa yan si ipo lọ.

Owo nikan kọ ni a le fi ṣe iranwọ fáwọn ọdọ to ba fẹ gbegba ibo.

O le fi akoko rẹ silẹ lati ṣe iranlọwọ fun ẹni to ba fẹ dupo oṣelu.

Ẹni to ba ni ile le fi ilẹ rẹ silẹ fun ipade oloṣelu.

Ati pe ko digba ti eeyan ba to dupo aarẹ tabi ipo gomina, awọn ọdọ lè dije fun ile igbimọ aṣofin.

Ile aṣòfin gan an ni o jẹ opakuntelẹ ijọba awaarawa.

Ti awọn ọdọ ba wa nile aṣofin, níbẹ ni wọn yoo ti ni ipa gidi ninu eto oṣelu.

Amin iyasọtọ kan

Mo ṣetán láti bá ẹnikẹ́ni ja ìjà rọ̀fọ̀rọ́fọ̀ nítorí ipò ààrẹ - Tinubu

Tinubu ati Alaafin Ọyọ

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III/ facebook

Nibayii ti saa eto idibo sipo aarẹ lorilẹede Naijiria lọdun 2023 ti n ṣa ara jọ, olukuluku awọn oloṣelu to fẹ dije lo si ti n na wọ soke.

Lara awọn to ti na ọwọ soke ni Aṣiwaju Ahmed Bọla Tinubu wa.

Lọjọ Aiku ni Bọla Tinubu, gẹgẹ bi ara ilana apero to n ṣe kaakiri tibutoro Naijiria lori ọrọ ati dupo aarẹ rẹ, gba ipinlẹ Ọyọ lọ.

Nibẹ si lo ti jiroro pẹlu Olubadan ti wọn ṣẹṣẹ yan, Agba Oye, Lekan Balogun ati Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi III.

Ki ni Tinubu sọ lọdọ Olubadan?

Nigba to de ọdọ Olubadan ti wọn ṣẹṣẹ fẹ yan sori oye, Agba Oye Lekan Balogun, Sẹnetọ Bọla Tinubu ko fi meni pe meji lori ipinnu rẹ, to si sọ ọ yanya pe ohun gbogbo to ba gba ni oun ṣetan lati fun un, lọna ati le e du ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Aṣiwaju Tinubu ṣalaye pe ohun ṣetan lati ja ija rọfọrọfọ pẹlu ẹnikẹni lọna ati du ipo naa.

O ṣalaye fun Kabiyesi tuntun to fẹ jẹ nilu Ibadan pe ṣiṣe aarẹ lẹyin Aarẹ Muhammadu Buhari jẹ ala kan to ti wa lọkan oun lati ọjọ pipẹ wa, ko si si ẹnikẹni to le e da oun duro mọ.

Tinubu ni: "Ko si idumọhurumọhuru mọni kankan to le di mi lọna. Mo ti ṣetan lati ja ija rọfọrọfọ. Mo ti gbaradi tan bayii lati di aarẹ Naijiria. Ikorita koyemi la wa bayii."

Olubadan yonbo Tinubu to n du ipo aarẹ:

Olubadan tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan, Oloye Lekan Balogun, nigba to n fesi si ọrọ Tinubu ni odu ni Tinubu, kii sii ṣe aimọ oloko lagbo oṣelu.

"Iwọ lo ṣe ifilọlẹ ipilẹ idagbasoke ipinlẹ Eko ti gbogbo aye mọ loni. O si ko ipa nla lati gbe Naijiria de ibi to wa loni.

Laisi Yoruba, Naijiria ko le e si ni ibi to wa loni. Naijiria ti pin yẹlẹyẹlẹ. Aarẹ lati ilẹ Yoruba ti yoo mu iṣọkan wọ orilẹede yii bayii ni a nilo."

Tinubu ati Oloye Lekan Balogun ti wọn ṣẹṣẹ yan gẹgẹ bii Olubadan tuntun

Oríṣun àwòrán, Newscoven.ng

Emi o ni kẹyin ọd maa jẹ aarẹ Naijiria o, ṣugbọn ẹ jẹ ki n jẹ temi naa- Tinubu

Ki Tinubu to de ọdọ Olubadan tuntun, lo ti kọkọ gba ọdọ Alaafin Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta lọ laafin rẹ nilu Ọyọ.

Nibẹ si lo ti fi to Kabiyesi naa leti pe ko si bi oun ṣe lee fẹ rawọ le nnkan bantabanta bii didu ipo aarẹ, lai kọkọ fi to awọn ọbalaye leti fun adura ati ifọwọsowọpọ wọn.

"Mo wa fi to awọn baba mi leti ni pe mo ti pinnu lati du ipo aarẹ orilẹede yii ldun 2023. Ohun ti mo nilo ldọ awọn eekan ọbalaye gbogbo bayii ni adura ati ifọwọsowọpọ wọn."

Lasiko to n sọrọ lori bi awọn kan ṣe n ṣe waduwadu si agba lai tii de ipo, aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC naa gbadura pe ọdọ yoo de ibi giga ni Naijiria lai yọ ipo aarẹ silẹ.

Amọṣa o ni oun yoo kọkọ jẹ aarẹ naa, lẹyin oun, awọn ọdọ lee wa maa jẹ tiwọn.

"Ẹ ko fẹ ki agba kọja, ẹ dẹ fẹ di aarẹ. Bi ẹ ba wa di aarẹ nkọ, ṣe ẹ maa le wa kuro nilu ni?"

"Ẹ maa dagba, ẹ dẹ maa di aarẹ. Ṣugbọn ẹ jẹ ki emi kọkọ jẹ temi na."

Alaafin, pẹlu awọn ọba mẹwaa lati ijọba ibilẹ mẹwẹẹwaa to wa lagbegbe Oke-Ogun, kan sara si Tinubu pẹlu adura pe awọn alalẹ ilẹ Yoruba ko ni fi silẹ ninu ilepa rẹ. to gbalejo Tinubu.

Àkọlé fídíò, Segun iberu

Ìtan Tinubu ree, 'afọbajẹ' to ni oun fẹ di aarẹ:

Ni oṣu kinni ọdun 2022 ni Aṣiwaju Bla Tinubu kọkọ kede pe oun fẹ du ipo aarẹ lẹyin to ṣepade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari tan nilu Abuja.

Aṣiwaju ẹgbẹ Oṣelu APC naa ṣalaye fawọn oniroyin lẹyin ipade naa pe oun wa fi to aarẹ leti ni nipa ipinnu oun lati gbe apoti ibo fun ipo aarẹ lọdun 2023.

Tinubu sọ fun awn oniroyin nigba naa pe afọbajẹ loun tẹlẹ oun si ti ṣetan bayii lati di ọba bẹẹni ko si si ofin kankan to sọ pe afọbajẹ ko le e di ọba.

Bakan naa lo si ti n lọ kaakiri tibu toro orilẹede Naijiria lati igba naa lati fikuluku pẹlu awọn alẹnulọrọ gbogbo.