Abba Kyari: Adájọ́ ṣe àfikún sáà tí afurasí yóò ló ní àhámọ́, kó le rọrùn fún NDLEA láti ṣe ìwádìí ẹ̀sùn rẹ̀ lókè òkun

Abba Kyari

Gbogbo ẹbẹ ọga agba ọlọpaa tẹlẹ, Abba Kyari ti wọn fi ẹsun gbigbe oogun oloro kan, lati jẹ ki ile ẹjọ gba oniduro rẹ lo ja si pabo lọjọ Isẹgun.

Ile ẹjọ giga tijọba apapọ to wa nilu Abuja ti wa fi ọjọ mẹrinla kun akoko ti wọn yoo fi Kọmisana ọlọpaa tẹlẹ, Abba Kyari si ahamọ ajọ NDLEA.

Ile ẹjọ gba ẹbẹ ajọ NDLEA lati tubọ fi yari si ahamọ siwaju si, ko ba le rọrun fun ajọ naa lati pari awọn iwadii rẹ lori ẹsun gbigbe oogun oloro ti wọn fi kan.

Adajọ Zainab Abubakar gbe asẹ naa kalẹ lasiko to joko lori ibeere asẹ kiamọsa ti agbẹjọro ajọ NDLEA, Mike Kassa gbe siwaju rẹ.

Àkọlé fídíò, Money Ritual: Ǹ kò le bèèrè

Ninu iwe ẹbẹ naa ni ajọ NDLEA ti bbẹ fun akoko diẹ si lati fi Kyari si ahamọ lori awijare pe ẹsun gbigbe ologun oloro ti wọn fi kan afurasi naa lagbara pupọ.

Ki lo de ti ajọ NDLEA fi n bẹbẹ fun afikun akoko ti Kyari yoo lo ni ahamọ?

NDLEA ni iwadii awọn lori ẹsun naa si le gba ajọ naa lati rinrin ajo kuro ni orilẹede yii fun awọn iwadi kan.

Agbẹjọro naa tun bẹ ile ẹjọ lati fontẹ si ibeere rẹ naa lori sise afikun saa ti wọn fi Kyari si ahamọ nitori idajọ ododo.

O ni eyi ni yoo fun ajọ NDLEA laaye lati huwa to tọ si afurasi naa lati ipasẹ isẹ iwadi to munadoko.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Abubakar pasẹ pe ki wọn tun fi Abba Kyari si ahamọ fun ọjọ mẹrinla miran.

Amọ o ni onka iye ọjọ mẹrinla naa bẹrẹ ni oni, ọjọ Kejilelogun osu keji ọdun 2022 to gbe idajọ naa kalẹ.

Amin iyasọtọ kan

Abba Kyari ní àìsàn ìtọ̀ súgà, ó sì nílò ìtọ́jú ìtọ́jú kíákíá, ẹ tu sílẹ̀ - Agbẹjọ́rò

Abba Kyari

Oríṣun àwòrán, Other

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, Adajọ ile ẹjọ giga kan niluu Abuja, Inyang Ekwo ti kọ lati gba beeli ọga ọlọpaa ti wọn fẹsun iwa ọdaran kan, Abba Kyari, kuro ni ahamọ ajọ NDLEA.

Kaka ko gba beeli rẹ, niṣe ni adajọ naa sọ pe ki Kyari sọ fun ile ẹjọ ọhun nipa ẹjọ to pe ijọba.

Ṣaaju ni Kyari ti kọkọ pẹ ijọba apapọ lẹjọ lori atimọle rẹ ni ahamọ ajọ NDLEA.

Ninu iwe ipẹjọ naa to ni nọmba FRHC/ABJ/CS/182/22 ni Kyari ti ke si ile ẹjọ ọhun pe ko kan nipa fun NDLEA lati tu oun silẹ.

NDLEA ti Kyari mọle lori ipa to ko ninu oogun oloro gbigbe pẹlu awọn afurasi mii.

Àkọlé fídíò, Ìjẹ̀bú: Àgbàlàgbà ni mo máa ń ṣe nínú eré tẹ́lẹ̀

Amọ agbẹjọro Kyari sọ pe onibara oun ni aisan itọṣuga, o si nilo itọju ni kankan.

Wayi o, adajọ Ekwo ti sọ pe ẹsun ti Kyari fi kan ijọba apapọ wuwo gidi, nitori naa, o gbọdọ fun ijọba ni anfani lati gbọ ẹjọ naa ko to le gbe igbesẹ lori rẹ.

Lẹyin na ni wọn sun ẹjọ ọhun si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji ti a wa yii.

Ki ni eredi ti NDLEA fi mu Kyari?

Gẹgẹ bii atẹjade NDELA, ileeṣẹ ọlọpaa funra rẹ lo mu afurasi naa lori ẹsun pe o wa lara awọn ẹgbẹ to n gbe oogun oloro.

Lẹyin naa ni wọn fa le NDLEA lọwọ lori ẹsun kan naa pe ẹgbẹ to wa n gbe oogun oloro laarin Brazil ati Ethiopia si Naijiria.

Yatọ si DCP Abba Kyari, wọn tun fẹsun kan awọn ọlọpaa miii pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Kyari, bii ACP Sunday J Ubua, ASP Bawa James, Simon Agirgba ati Inspector John Nuhu.

Ta ni Abba Kyari?

Wọn bi Abba Kyari lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 1975, niluu Maiduguri, ni ipinlẹ Bornu.

O kẹkọọ gboye ni fasiti ijọba apapọ to wa niluu Maiduguri ati ile ẹkọ awọn ọlọpaa to wa ni Wudil, Kano lọdun 2000.

Okiki rẹ bẹrẹ si n kan lẹyin ti ọwọ rẹ tẹ awọn gbajumọ ajinigbe kan bi Evans, Wadume, ati bẹẹ beẹ lọ.

Kyari kawe gboye ni fasiti ijọba apapọ to wa niluu Miduguri.

O jẹ igbakeji kọmiṣọnna ọlọpaa ati ọkan lara awọn ikọ akọṣẹmọṣẹ afimufinlẹ ti ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ko sọdi, IRT, ni olu ileeṣẹ naa to wa niluu Abuja.

Kyari ti fi akoko igba kan ṣiṣẹ gẹgẹ bii alakoso ẹka to n gbogun ti idigunjale, SARS, ni ipinlẹ Eko.

Lara awọn aṣeyọri Kyari ni bi ikọ rẹ ṣe fi ṣikun ofin mu awọn adigunjalẹ to kọlu ile ifowopamọ kan niluu Offa, ni ipinlẹ Kwara, nibi ti ẹmi eeyan mọkanlelọgbọn ti sọnu.