Truth Social: Donald Trump dá ojú òpó tirẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn tí Twitter àti Facebook fòfin dèé

Truth Social will be run by the former US president's newly created Trump Media & Technology Group
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Aarẹ ilẹ Amẹrika ana, Donald Trump, ti ṣe ifilọlẹ oju opo ikansiraẹni kan to pe orukẹ rẹ ni "Truth Social."

Awọn onimọ to sọrọ nipa aapu ọhun sọ pe o farajọ oju opo ikanni Twitter.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọdun to kọja ni wọn yọ Trump kuro lori ikanni Twitter, Facebook ati YouTube.

Ẹni to n lewaju ifilọlẹ aapu naa, Devin Nunse sọ pe aapu naa yo bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹwu titi ipari oṣu Kẹta ọdun 2022 yii.

Amọ awọn eeyan kan ti wọn fẹ kọkọ darapọ mọ oju opo naa ni o ṣoro lati ṣe bẹẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Lọsẹ to kọja ni ọmọ Aarẹ Trump, Donald Trump Jr kede nipa ikanni naa loju opo Twitter rẹ.

Twitter fofin de Trump loju opo rẹ lọdun to kọja lẹyin ọrọ to sọ lori ifẹhonuhan to waye lọjọ kẹfa, oṣu Kinni, ọdun 2021 ni gbagede Capitol.

Awọn kan ti sọ pe oju opo naa farajọ oju opo Twitter.

Ọgbẹni Nunes sọ pe oju opo Truth Social ko ni ṣe idẹyẹ si ẹnikẹni, bẹẹ si ni ko ni fofin de ẹnikẹnni.

Bo tilẹ jẹ pe App Store ati Google Play ko faye gba ki aapu kankan ṣe ohun ti yoo lodi si ofin.

Àkọlé fídíò, Oja Odan nibi ti wọn ti dáná sún afurasi meji ti wọn ba ori eeyan lọwọ wọn