Sylvester Oromoni - Ọlọ́paàá jẹ́rí níwájú ìgbìmọ̀ olùwàdìí pé lóòtọ́ọ́ ní àwọn afurasí akẹ́kọ̀ọ́ fìyà jẹ olóògbé náà

Oríṣun àwòrán, Oromoni
Osisẹ ọlọpaa to n se iwadi awuyewuye to rọ mọ iku Sylvester Oromoni, tii se akẹkọọ ile ẹkọ Dowen College nilu Eko ti kawọ pọnyin ro ẹjọ niwaju igbimọ oluwadi to n tọpinpin isẹlẹ naa.
Bẹẹ ba gbagbe, osu Kejila ọdun 2021 ni Sylvester jade laye nile iwosan kan, ti wọn si fura pe ejo lọwọ ninu nipa iku rẹ.
Awọn akẹkọ marun to wa nile ẹkọ Dowen College si ni wọn fura si pe wọn n fi iya jẹ oloogbe naa, ti wọn si fun ni ohun mimu oloro, ko to jade laye.
- Onímọ̀ ẹ̀yà ara míì kéde okùnfa ikú míràn tó pa Sylvester Oromoni
- Wó ìgbésẹ̀ táwọn ọlọ́pàá gbé níwájú iléẹ̀kọ́ Dowen College tí Sylvester Oromoni tó kú lọ
- Ilé ẹjọ́ gba béèlì akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College márùn ún tó ń jẹ́jọ́ lórí ikú Sylvester Oromoni
- Mẹ́ta lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College tí Sylvester dárúkọ ti wà ní àkàtà ọlọ́pàá - Kọmisanna ọlọpaa Eko
- Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tí ọmọ mi, Sylvester Oromoni sọ fún wa nìyí nínú ìrọra kí ó tó kú, òní ni ọjọ́ ìbí rẹ̀!
- Àwọn ọlọ́pàá gbé òkú Sylvester Oromoni, akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College to ku l'Eko fún àwọn òbí rẹ̀ lẹ́yìn àyẹ̀wò 'Autopsy'
- Ikú Sylvester Oromoni: Wo kókó òfin ìpínlẹ̀ Eko mẹ́wàá tó tako ẹgbẹ́ òkùnkùn
- Mi ò ní sin òkú ọmọ mi títí màá fi rí ìdájọ́ òdodo gbà, kò báà jẹ́ ọgbọ̀n ọdún - Baba Sylvester Oromono
- "Kí ló dé tó jẹ́ orúkọ ẹbí Kashamu nìkan lẹ mú bọnu nínú àwon ọmọ Marun ti Oromoni Jnr dárúkọ?"
- Gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú Sylvester Oromoni kò ní lọ láì jìyà lábẹ́ òfin - Buhari
Osisẹ ọlọpaa Bamidele Olusegun, ti ẹka isẹ ọlọpaa iwadii ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Panti nilu Eko si ni ọlọpaa to n se iwadi isẹlẹ naa, ẹni to rojọ niwaju igbimọ naa.
Amọ nigba to yọju siwaju igbimọ naa, o dahun ọpọ ibeere ti agba amofin Femi Falana n ju si lori isẹlẹ ọhun.
Bamidele salaye pe awọn ko pari iwadii awọn akẹkọọ afurasi ti wọn fi ẹsun kan, ki wọn to tu wọn silẹ kuro ni ahamọ lati tẹle asẹ ile ẹjọ to sọ bẹẹ.
Awa ọlọpaa kọ iwe ẹhonu lati tako bi wn se tu awọn akẹkọọ afurasi marun silẹ:
O ni ileesẹ ọlọpaa kọ iwe ẹhonu si adajọ agba nipinlẹ Eko, eyi to fi n beere pe ko gbe ẹsẹ kuro lori asẹ gbigba oniduro awọn akẹkọọ maraarun naa, ko to di pe ọjọ lọ lori asẹ fifi wọn si ahamọ fun ọgbọnjọ.
Iwe ẹhonu naa si wa lara awọn ẹri to wa niwaju igbimọ oluwadi naa, ti deeti rẹ jẹ ọjọ kejilelogun osu Kejila ọdun 2021.
Iwe naa si lo n ta ko bi wọn se gba beeli awọn akẹkọọ maraarun naa, ti ikọọkan wọn ko tii pe ẹni ọdun mejidinlogun.
Osisẹ ọlọpaa Fayoade Adegoke, tii se ọga agba fun ileesẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Panti nilu Eko, si lo fọwọ si iwe ẹhonu naa.
Iwadii wa fihan pe lootọ ni wọn fiya jẹ oloogbe Oromoni, to si mu nnkan olomi:
Bakan naa, ni iwe abọ iwadii ọlọpaa, ti deeti ori rẹ jẹ ọjọ kẹtalelogun osu Kejila ọdun 2021, lo tun gbe kalẹ bii iwe ẹri miran niwaju igbimọ oluwadi ọhun.
Ẹlẹri naa ni lootọ ni wọn fiya jẹ Oromoni, ti wọn si kan nipa fun lati mu ohun mimu kan, ti oun ko le sọ iru nnkan to wa ninu rẹ.
Amọ o fikun pe ọkan lara awọn akẹkọọ afurasi naa, ni wọn ni ko lọ rọọkun nile fun igba diẹ naa lọdun 2019 nitori iwa aidaa kan to hu, to n sintọ si olukọ rẹ lara nile ẹkọ.
Ẹlẹri naa fikun pe ile ẹkọ Dowen ko fi iya jẹ afurasi akẹkọọ miran to na oloogbe Oromoni losu Kẹwaa ọdun 2021 nitori o n bi pe ko se apejuwe bi abẹ ẹgbọn rẹ obinrin to wa nile ẹkọ naa se ri.
Isọri awọn akẹkọọ kan nile ẹkọ Dowen ko ara wọn jọ lati maa dunkooko mọ awọn akẹẹgbẹ wọn:
Bamidele tun sọ fun Mikhail Kadiri, tii se asaaju igbimọ oluwadi ọhun pe abọ iwadi ọlọpaa fihan pe, isọri awọn akẹkọọ kan ko ara wọn jọ nile ẹkọ Dowen lati maa dun mahuru mahuru mọ awọn akẹkọọ ẹlẹgbẹ wọn.
Bakan naa ni ẹlẹri naa ni awọn olukọ mẹtẹẹta to n se amojuto ilegbe awọn akẹkọọ ninu ọgba ile ẹkọ Dowen ni wọn ko mu isẹ wọn lọkunkundun rara.
Awọn olukọ naa ni Valentine Igbokwueze, Ahmed Ayomo ati Adesanya Alusesan, to si ni wọn n foju fo awọn asise akẹẹ rẹ.
Bakan naa lo ni wọn tun kuna lati gbe igbesẹ to yẹ, nigba ti wọn fi ẹsun ifiyajẹni ati idunkookomọni lati ọdọ awọn akẹkọọ kan, to wọn leti.
Amọ osisẹ ọlọpaa naa ni awọn ko le foju wọn ba ile ẹjọ lati jẹjọ awọn ẹsun naa nitori awọn ko ni ẹri to muna doko lati se bẹẹ.
Igbimọ oluwadii naa ti wa sun ijoko rẹ siwaju di ọjọ Isegun oni, ti agbẹjọro ile ẹkọ Dowen College, Anthony Kpokpo, atawọn agbẹjọro miran yoo si maa fi ọrọ wa osisẹ ọlọpa ọtẹlẹmuyẹ naa lẹnu wo.
Ki lo ti sẹlẹ sẹyin lori iku Slyvester Oromoni:
Iroyin iku Sylvester di ilumọọka nigba ti ibatan rẹ kan fi si ori ayelujara pe àwọn akẹkọọ kan ni ile ẹ̀kọ́ Dowen College, ti ọmọ naa n lọ, lo lu u, nitori pe o kọ̀ lati darapọ mọ ẹgbẹ́ okunkun.
Àmọ́, awọn alasẹ ile ẹ̀kọ́ naa sọ pe irọ ni. Wọn ni ẹsẹ ni ọmọ naa sọ pe o n dun oun, lẹyin to farapa nibi ere bọọlu.
Ijọba ipinlẹ Eko ti ile ẹkọ naa pa, ti ọpọ obi si n tara poro lori iku akẹkọọ naa.
Ijọba gbe igbimọ oluwadii kalẹ lati se ayẹwo iku to pa ọmọ ọdun mejila naa, ti onimọ iwadi akọkọ si ni awọn kẹmika kan ti wọn ri ni inu rẹ lo gba ẹmi rẹ.






















